Farmers vs Herders: Ìjọba tí kò ṣe ojúṣe rẹ̀ ló mú káwọn Fulani máa gbé ìbọn AK47 kiri

Oríṣun àwòrán, Bala Mohammed Facebook
Gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed ti sọ idi ti awọn Fulani ko ni le ṣe lalai maa gbe ibọn AK-47 kaakiri.
O fidi ọrọ yi mulẹ lasiko to n sọrọ nibi apero awọn akọroyin to waye ni olu ilu Bauchi.
Mohammed ni idi t'ọpọ awọn darandaran fi n gbe ibọn ni lati daabo bo ẹmi ara rẹ ninu igbo lọwọ awọn ẹranko ati ajimaalu gbe.
Bala ni ko yẹ ki awọn ọmọ Naijiria maa sọ gbogbo eeyan ẹya kan di alaburu nitori iwa tawọn kan baa n hu ninu wọn.
O ni ijọba to kuna lati daabo bo awọndarandaran lo mu ki wọn maa gbe ibọn fun aabo ẹmi wọn.
Lẹnu lọọlọ ọrọ wahala ija laarin awọn darandaran ati agbẹ jẹ eleyi to mu iriwisi ọtọọtọ wa.
Ninu awọn to sọrọ nipa iṣẹlẹ yi ni Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom to ni aarẹ Buhari n ṣe bi igba pe aarẹ awọn Fulani nikan nii ṣe.
Lasiko apero awọn oniroyin yi, Bala Mohammed bẹnu atẹ lu Ortom pe o wa lara awọn to n fi gbolohun rẹ da ija ẹlẹyamẹya silẹ.
''A ti ri nkan tawọn Gomina akẹgbẹ wa n sọ ni iwọ oorun Guusu Naijira ati awọn to wa ni Guusu Guusu Naijiria. Wọn kuna pẹlu ọrọ wọn''
O ni ''ṣugbọn ẹni to kuna ju ni Gomina Ortom Benue to da gbogbo wahala yi silẹ.Bi ẹ ko ba faye gba awọn eya mi, ṣebi awa naa n faye gba awọn eeyan yin lọdọ wa?''
Ki lawọn eeyan sọ si ọrọ Bala Mohammed nipa AK-47?
Loju opo Twitter niṣe lawọn eeyan n sọrọ labẹ akorio ọrọ AK-47.
Sẹnẹtọ nigba kan ri Shehu Sani ni bi igba pe eeyan n faye gba ki eeyan maa hu iwa aburu ni ọrọ Gomina yi jẹ
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ray Isah no tiẹ sọ pe ko wulẹ yẹ ki a ma jiyan lori ọrọ yi. Ki ẹya kọọkan kuku maa gbe ibọn kiri
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ṣugbọn ninuirori tirẹ Seidu Idris ni ọna gbogi ree fawọn Fulani lati daabo bo ara wọn
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3