Herdsmen invade Soyinka House: Ṣé lóòtọ́ làwọn darandaran tasẹ̀ àgẹrẹ wọ ọgbà Soyinka?

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fesi si iroyin to gbode kan pe awọn daandaran Fulani ṣigun lọ ba ọjọgbọn Wole Soyinka nile rẹ.
Alukoro ọlọpaa Abimbola Oyeyemi ṣalaye pe ko si ootọ ninu fọnran fidio kan ti eeyan kan ti n sọ pe awọn darandaran ti yabo ile Soyinka .
Ninu alaye rẹ o ni niṣe ni Wole Soyinka pade darandarasn kan to ni oun n wa maalu rẹ́ to sọnu ti Soyinka si sọ fun pe kio gbe awọn maluuu rẹ kuro ni agbegbe ile rẹ.
- Oba Yesufu Asanike I, Olubadan tó fi èèyàn joyè jùlọ̀ láì fi ẹ̀yà ṣe
- 'Sunday Igboho dáná sun àwòrán bàbá wà kódà ó tún yìnbọn sókè nígbà tó wà sí ilé wà ní Eggua'
- Ìbẹ̀rù nípa Amotekun ló ń mú káwọn èèyàn kan máa wí ìwíkùwí - Soyinka
- 'Sunday Igboho dáná sun àwòrán bàbá wà kódà ó tún yìnbọn sókè nígbà tó wà sí ilé wà ní Eggua'
- Ìjọba Buhari ń wùwà bíi ìjọba Abacha lórí ọ̀rọ̀ Ṣoworẹ- Ṣoyinka
O ni ọga ọlọpaa agọ ọlọpaa to wa ni agbegbe Kemta Estate gbọ si ọrọ yi to si ni ki ẹni to ni maalu naa yọju si agọ ọlọpaa lati wa ṣalaye bi ọrọ se ri.
Oyeyemi ni o jẹ iyalẹnu pe awọn ri fọnran fidio to gbori ayelujarea kan ti awọn eeyan si n gbe iroyin ẹlẹjẹ pe awọn Fulani ṣigun lọ si ile Soyinka lati lọ doju ija kọ.
Gẹgẹ bo ti ṣe sọ, ko si ohun to jọ wi pe wọn yabo ile Soyinka tabi pe wọn ba dukia rẹ jẹ.
Kọmisana ọlọpaa ninu atẹjade naa tẹsiwaju lati kan si ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Edward Awolowo sọ pe yatọ si pe oun ba ẹni to ni maalu naa Kazeem Soriola sọrọ, oun wadi ọrọ lẹnu Fulani to n ba daa maalu ti awọn si ti fidi ododo mulẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati yago fun iroyin ayederu eyi to le da wahala silẹ lawujọ.












