Herders-Farmers clash: Kí oníkálùkù máa lọ ní ìlọ tiẹ̀, a ò fẹ́ Seriki Fulani ní ìlú mọ́-Akọ̀wé àgbẹ̀ Igangan

IBrahim Sarki

Ipetuṣaawọ ọrọ laarin Fulani ati awọn agbe Yoruba ni Ibarapa paapa ni ilu Igangan ko ṣebi ẹni pe yoo yanju laipẹ yi.

Idi ni pe awọn tọrọ kan, iyen awọn Yoruba ati awọn Fulani ko ṣetan lati joko yanju ọrọ yi ni tubu n nubi.

Ninu ifọrọwerọ to waye lori ikanni BBC akọwe awọn agbẹ ni Igangan alagba Taiwo Adeagbo sọ pe alejo lawọn Fulani ati pe wọn fi oko jijẹ kalẹ ti wọn si bẹrẹ si ni pa awọn eeyan.

O mu ẹri wa nipa awọn iwe ẹhonu toun ti kọ lati fẹsun kan Seriki Fulani lori gbogbo aṣemasẹ to n ṣe lagbegbe Igangan.

Ninu alaye rẹ, alagba Adeagbo sọ pe Seriki Fulani kii ṣe ẹni to faye gba alaafia nilu nipa awọn nkan orisirisi to n kọ sinu iwe iroyin

''Saliu Seriki kọ iwe si ijọba ipinlẹ Oyo lai ṣe pe ẹnikankan n pa maalu rẹ''

Aworan ifọrọwerọ

''Bakan naa nigba ti BBC lọ ba fun ifọrọwerọ o ṣalaye pe maalu oun le si ni ọdọọdun ni.Ṣe ẹyin naa ri gbogbo irọ to n pa? Awọn n ri oko wọn da ṣugbọn awa agbẹ Yoruba ko ri oko tiwa da''

Adeagbo ni gbogbo atotonu yoo wu ki Seriki Fulani ati awọn ọmọ rẹ le wi, ohun to ṣe koko ni pe ara ilu ko fẹ wọn nilu mọ.

Awọn ara ilu ko le ni ka ma gbe ni Igangan mọ

Ninu esi si gbogbo awọn ẹsun ti Adeagbo fi kan baba rẹ, ọmọ Seriki Fulani, Ibrahim Salihu sọ pe ẹtaanu lo n mu ki awọn Yoruba maa tako igbelu Fulani ni Igangan.

O ni ko si ootọ ninu ọrọ ti Adeagbo sọ pe Seriki Fulani n pe awọn Fulani wa lati ilẹ Niger to si n fipa gba maalu wọn.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik
Àkọlé fídíò, Arakunrin Fulani ni aigbede ara eni ni orisun ija pelu agbe

Ibrahim bẹnu atẹ lu gbogbo akawe ti Adeagbo muwa to si ni Adeagbo gaan kii ṣe ọmọ ilu Igangan nitori naa ko le sọ nipa itan Igangan tabi ko ni oun gbẹnu awọn agbẹ sọrọ.

Lori ẹsun pe awọn Fulani n gbe ibọn AK47 kaakiri, Ibrahim fesi pe :

''Bi a ba ni ibọn lọwọ, ṣe awọn to wa ṣigun ba wa nile, a ko ni ti ṣina ibọn lati daabo bo ara wa ni?''

Nipa iku Ọmọwe Abọrọde ti wọn pa ni Igangan Ibrahim ni oun ko jiyan pe kii ṣe Fulani lo pa ṣugbọn iku rẹ jọ bi iṣẹlẹ awọn agbenipa nitori ọrọ oṣelu ni.

O ṣalaye pe Aborọde jẹ ẹni to sunmọ awọn Fulani paapa mọlẹbi Seriki Fulani nitori naa iroyin to gbode pe wọn pa Aborode nigba to wa fẹjọ sun Seriki pe awọn Fulani fẹran jẹ oko rẹ kii ṣe ootọ.

Aworan ifọrọwerọ

A ko fẹ awọn Fulani mọ ni Igangan

Nigbẹyin gbẹyin ifọrọwanilẹnuwo, BBC beere boya wọn le wa na abayọ lati le jijọ maa gbe pọ ni irẹpọ.

Ninu esi tirẹ Alagba Adeagbo sọ pe ko si ṣiṣe ko si aiṣe, gbogbo ara ilu ni ko fẹ ri Seriki Fiulani ati awọnb ọmọ ẹ nilu mọ.

Amọ ṣa Ibrahim ni ara ilu kole sọ pe kawọn ma gbe ilu mọ lopin igba ti ofin Naijiria faaye gba ki ọmọ Naijriia maa gbe ibi to ba wu lopin igba to ba ti jẹ ọmọ ilẹ naa.

Adamu Suleiman
Àkọlé àwòrán, Adamu Suleiman sọ pe lootọ lawọn ati Yoruba jijọ n gbe ibọn kaakiri

'Sunday Igboho dáná sun àwòrán bàbá wà kódà ó tún yìnbọn sókè nígbà tó wà sí ilé wà ní Eggua'

Bi ẹ baa n sọrọ pe awa Fulani n gbebọn kiri, lootọ ni ṣugbọn awọn Yoruba naa n gbe ibon tiwọn naa ka.

Ọrọ yi ni BBC gbọ lati ẹnu ọkan lara awọn darandaran to wa nilẹ Yoruba.

Adamu Suleiman to ba BBC sọrọ fidi ọrọ mulẹ pe lootọ lawọn n gbe ibọn kaakiri ṣugbọn ati awọn ati awọn agbẹ lo n gbe ibọn kiri titi ti ijọba yoo fi yanju wahala to wa nilẹ.

Ọmọ Seriki Fulani ilu Eggua ni ijọba ibilẹ Yewa nipinlẹ Ogun yi sọ pe ile oun wa lara ile tawọn janduku dana sun laipẹ yi ni Eggua.

O ni ijọba kii gbe igbesẹ to yẹ lati dẹkun ikọlu to n waye yi nitori awọn ọlọpaa ko ni irinṣẹ to kaju osunwọn.

Lori ọrọ awọn janduku to wa dana sun ile wọn ni Eggua, Suleiman ni ''Nigba ti Sunday Igboho de ilke wa, o ni ki wọn dana sun, o gbe aworan baba mi wọn sọ ina si, wọn yinbọn. Ohun gaan alara gbe ibọn to si yin soke''

Sueliman tẹsiwaju pe ''ara Seriki ko ya, o wa ni ile iwosan bi mo ṣe n ba yin sọrọ. O n gba itọju nitori ohun to ṣẹlẹ ko iporuru ọkan ba''

Bẹẹ naa ni Suleiman sọ pe oun ti n gbe ni Eggua lati kekere ni.

O ni awọn mọlẹbi Seriki to aadọta to wa nibẹ ati pe lọdun 1985 ni wọn bi oun si Eggua.

O ṣalaye ibasepọ to wa laarin awọn agbẹ ati darandaran latẹyinwa.

''Ti agbe ba ri darandaran wọn maa n sọ fun wọn ki wọn ma da ẹran wọ inu oko, awa naa si maa n gbọ si wọn lẹnu''

Saaju asiko yi lawọn eeyan ti n sọrọ pe awọn darandaran maa n gbe ibọn rin kaakiri nilẹ kaarọ o jiire ṣugbọn ko si Fulani to sọ pe lootọ ni.

Àkọlé fídíò, Bí àlááfíà yóò ṣe wà láàrin Fulani àti Yorùbá ni Ooni bá lọ sọ́dọ̀ Buhari- Ààfin Ile Ife

Bawọn darandaran se kọlu awọn eeyan Asa ti wọn si pa awọn eeyan

Bi a ti ṣe n gbiyanju lati gbọrọ lẹnu awọn ti ọrọ yi kan, nibẹ la ti rin gẹrẹ wọ abule Asa ni ijọba ibilẹ Iselu Yewa ni ariwa ipinlẹ Ogun.

A gbọ pe awọn darandaran ṣe ikọlu sawọn eeyan nibẹ.

Nibẹ la ti pade arabinrin kan to ṣalaye fun wa pe awọn darandaran pa ọmọ kan ṣoṣo ti oun bi.

Arakunrin kan naa sọ fun wa pe wọn ṣa oun lada lori ati ọwọ ti wọn si ge ika oun sọnu.

A tun ri arakunrin kan ti oun naa ṣalaye pe awọn darandaran da ọgbẹ si oun lara pẹlu ada.

Ọja to wa labule yi ko rẹni na nitori ibẹru pe awọn darandaran yi yoo wa ṣe ikọlu si wọn.

Arakunrin Mathew Fakambi sọ fun BBC bi awọn darandaran yi ṣe kọlu ile itaja oun ti wọn si jin ọja gbe nibẹ.

Aworan arabinrin
Àkọlé àwòrán, Arabinrin yi sọ pe awọn darnadaran pa ọmọ kan ṣoṣo toun bi

"Lọjọ taa n wi yi, mo lọ si Oja Odan lati lọ tun ẹrọ amunawa gẹnẹretọ ṣe. Bi mo ṣe n pada bọ ni mo ri tawọn eeyan sa kaakiri''

''Nigba ti mo beere pe ki lo ṣẹlẹ, wọn ni awọn Fulani lo n le awọn''

O ṣalaye pe awọn to kogun wa ba awọn yi gbe awọn agbofinro lọwọ ti wọn si n yinbọn ti wọn si n fọ ṣọọbu awọn.