Chief Lateef Jakande: Ètò ìsìnkú gómìnà alágbádá àkọ́kọ́ ti ìpínlẹ̀ Eko

Eto isinku gomina ijọba alagbada akọkọ ti ipinlẹ Eko ti n waye.
Lara awọ́n eekan ilu to peju sibi eto isinku yii ni gomina ana ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun, igbakeji gomina ipinlẹ Eko, Obafemi Hamzat atawọn eeyan jankan jankan mii nipinlẹ Eko ati lawọn ipinlẹ mii.
Awọn imaamu nla nla ninu ẹ́sin musulumi peju sibẹ lati gba adura ikẹyin fun un.
Imaamu agba Ilupeju ataawọn aafaa ibẹ wa lara awọn to ṣe adura nibi eto isin ikẹhin fun oloogbe.

Akewi kan to mọ gidi nipa oloogbe kẹnu b ewi ti ori awọn si n wu nitori pe o j eeyan to sunmọ Alhaji Jakande gan.

Ninu ewi rẹ lo ti n sọ iru eeyan ti oloogbe jẹ ati awn nkan rere rere to ṣe nigba aye rẹ to bẹẹ tawọn eeyan bẹrẹ si ni na an lowo.
"Ni 1981, mo ṣe awo fun wọn, mo sọ fun wọ́n nipa awọ́n iṣẹ́ Jakande..."
Eto isinku yii n lọ lọ́wọ́ lori ayelujara Zoom fun anfani awọn ti ofin ko gba laye lati lọ si ibi itẹ oloogbe.
Bi o ba fẹ wo eto isinku naa bo ṣe n lọ lọwọ tẹ oju opo isalẹ yii:

Chief Lateef Jakande dágbére fáyé lẹ́ni ọdún 91
Gẹgẹ bo ṣe tẹ wa lọwọ, Alhaji Lateef Jakande jẹ Ọlọrun nipe lowurọ oni Ọjọbọ, ọjọ kọkanla oṣu keji ọdun 2021 lẹni ọdun 91.
Ọkan lara awọn ọmọ oloogbe Deji Jakande lo fi aridaju iroyin yii hande.

Bakan naa, Gomina Babajide Sanwoolu ti ipinlẹ Eko ti fi ọrọ idaro sita nipa baba Jakande. O yin in gẹgẹ bi adari to laami laaka ati oniroyin to ṣee gbagbọ nigba aye rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Nigba ti BBC Yoruba kan si Kọmisana fun eto ipolongo ati ọgbọn inu ni ipinlẹ Eko, o jẹ ko di mimọ pe eekan ti ko ṣee gbagbe ni oloogbe Jakande nipinlẹ Eko, nilẹ Yoruba ati ni Naijiria lapapọ.


Ọgbẹni Gbenga Omotosho fi yeni pe gẹgẹ bii gomina akọkọ ni ijọba alagbada fun ipinlẹ Eko ti o dẹ ṣe e daadaa to bẹẹ to jẹ pe orukọ rẹ ko le parẹ laelae.
"Ẹni to jẹ pe gomina wa lonii, Babajide Sanwoolu n gbedi fun ni oloogbe Jakande. Nipa eto ileewe, ibagbepọ araalu, irina ati gbogbo bo ṣe ṣe ijọba rẹ, ohun to ṣe ko lee parẹ laelae ni".
Omotosho ni ọfọ nla ni nkan to ṣẹlẹ jẹ fun ipinlẹ Eko amọ inu awọn dun pe baba ṣe nkan rere ti wọn lee ranti rẹ fun.
Gẹgẹ bii oloṣelu ati adari ni Naijiria
Oloogbe Jakande lo wa pẹlu baba Awolowo nigba aye wọn ni. Bakan naa gbogbo nkan ti baba Jakande ṣe nigba aye tirẹ naa ni wọn n gbosuba fun.
O fi kun un pe oloogbe Jakande tun gbiyanju lati maa ri i daju pe ẹkọ ti iran Yoruba nilo di nini ki gbogbo Yoruba baa le ṣe ara wọn ni oṣuṣu ọwọ.
- Àìrìjìnà ni àìrábuké ọ̀kẹ́rẹ́, orí ọ̀kadà ni wọ́n ń gbé òku sí lọ mọ́súárì
- Àwọn darandaran tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ wọ ọgbà Soyinka, kí ló tẹ̀yìn rẹ̀ bọ̀?
- Oba Yesufu Asanike I, Olubadan tó fi èèyàn joyè jùlọ̀ láì fi ẹ̀yà ṣe
- Ìròyìn ayọ̀! Tessica tó fi 'glue' lẹ irun pọ̀ tí rí ẹlẹ́yinjú àánú Dókítà tó fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ orí fún un















