Farmers-Herders clash: Amotekun Ondo mú àwọn afurasí daran-daran tó já wọ oko olóko pẹ̀lú màálù

Oríṣun àwòrán, @news360info
Ọjọ Iṣẹgun ni iroyin jade pe ọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ alabo Amọtẹkun nipinlẹ Ondo tẹ daran-daran Fulani meji ati awọn maalu wọn nijọba ibilẹ Ifedore nipinlẹ Ondo.
Awọn afurasi naa ni iroyin sọ pe wọn fi ẹran ọsin wọn ba irugbin jẹ ni oko awọn agbẹ kan ni agbegbe naa.
Bakan naa ni wọn tun fi ẹsun kan wọn pe wọn kọju ija si awọn oṣiṣẹ Amọtẹkun to fẹ fi ofin mu wọn.
Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ọsẹ bii meji ti gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu kede ofin to de dida ẹran ọsin ni oru, ati laarin ilu ati ojupopo.
- Gbogbo ẹ̀yin Fulani darandaran tó wà ní ìgbó ìjọba ní Ondo, ọjọ méje lẹní láti pòórá - Gomina Akeredolu
- ''Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo kò bẹ̀rù idúnkokò mọ́ni iléeṣẹ́ ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ àwọn Fulani darandaran''
- '' Ìrọ ní ò, N51.8million kọ́ ní àwọn Naijiria dá fún Sunday Igboho, N4milion ní''
- Bukola Saraki sọ̀rọ̀ sókè lórí ìgbésẹ̀ Sunday Igboho
Bakan naa ni gomina tun paṣẹ fun awọn daran-daran lati kuro ni awọn igbo iyasọtọ nipinlẹ naa.
Lasiko to ba BBC Yoruba sọrọ, Oludari ajọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Adeleye Adetunji sọ pe lootọ ni ọwọ awọn tẹ daran-daran meji, ati awọn maalu wọn fun pe wọn ba irugbin jẹ ni oko oloko.
Ṣugbọn ṣa, Alaga ẹgbẹ awọn daran-daran, Miyetti Allah, Alhaji Garuba Bello, sọ pe oun ko tii gbọ nipa iṣẹlẹ naa.
Lati oṣu Kinni, ọdun 2020 ni ọrọ awọn Fulani daran-daran ati awọn agbẹ tun ti n fa wahala ni ilẹ Yoruba.
Paapaa lẹyin ti gbajugbaja ajijagbara, Sunday Adeyemo, ti awọn eeyan mọ si Sunday Igboho, fun awọn Fulani daran-daran ni gbedeke ọjọ meje lati fi ilẹ Yoruba silẹ.
Ọrọ yii fa rogbodiyan lasiko ti Igboho lọ si agbegbe Oke Ogun nipinlẹ Ọyọ, nibi ti awọn janduku kan ti kọlu Seriki Fulani nilu Igangan lẹyin abẹwo Sunday Igboho.













