Ondo Fulani ultimatum: Gbogbo ẹ̀yin Fulani darandaran tó wà ní ìgbó ìjọba ní Ondo, ọjọ méje lẹní láti pòórá - Gomina Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Twitter/Akeredolu
Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti fun awọn Fulani darandaran ni ọjọ meje lati kuro ni igbo ijọba to wa ni ipinlẹ naa.
Gomina Akeredolu fi aṣẹ yii lede loju opo ikansiraẹni Twitter rẹ.
O ni ọna lati dẹkun gbogbo iwa ọdaran to fi mọ ijinigbe to peleke ni ipinlẹ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Akeredolu ni awọn Fulani darandaran ti sọ igbo ijọba ni ibujoko awọn ọdaran ati awọn ajinigbe, ti wọn si n lọ awọn agbegbe yii lati sapamọ kuro lọwọ ijọba.
- BBC findings on lekki shooting: Ẹ wa wo àwọn tó ṣì ń wá ẹbí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ End SARS 2020
- Ó lé ní ọgọ́rin èèyàn tó kú nínú ìjà ẹlẹ́yàmẹ́yà tó wáyé ní Dafur- Aláṣẹ Sudan
- Ẹ wo ohun tí Seriki Fulani sọ fún gómìnà Makinde nípa Sunday Igboho
- Ìjọba Eko ṣàlàyé ìdí tó fi ṣí iléèwé padà bí covid-19 ṣe ń pọ̀ síi lójoojúmọ́ níbẹ̀
''Ọpọlọpọ ijinigbe ni a ti tọ ipasẹ rẹ lọ si ọdọ awọn to n kaakiri gẹgẹbi darandaran, ti wọn si lọ igbo ijọba lati ko awọn eniyan pamọ ati lati gba owo lọwọ awọn ẹni ti wọn ba jigbe.''
''Gẹgẹ bi alasẹ lori eto aabo nipinlẹ Ondo, mo ṣetan lati da abo bo awọn eniyan ati ohun inu wọn ni ipinlẹ Ondo.''
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
''Nitori naa mọ paṣẹ pe ki gbogbo awọn darandaran to ba wa ni igbo ijọba kuro nibẹ ni aarin ọjọ meje''
''Mo fopin si dida ẹran kaakiri igboro ni alẹ ni kiakia, nitori ọpọlọpọ oko ni wọn n bajẹ ni alẹ.''
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
''Ko gbọdọ si dida ẹran laarin igboro ati opopona ni ipinlẹ Ondo mọ.''
''Ko gbọdọ si awọn ọmọde ti yoo ma da ẹran kaakiri ipinlẹ Ondo''
- Ọlọ́pàá mẹ́rin kú, ọ̀kan dàwátì níbí ìkọlù tó wáyé ní Birnin-Gwari ní ìpínlẹ̀ Kaduna- Ọga Ọlọ́pàá
- Àlàyé rèé lórí bí ''Ice Cream'' ṣe lùgbàdì àrùn coronavirus bí èèyàn
- N1.4bn ni ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti yòó ná lórí Amotekun lọ́dún 2021
- Wo àwọn oúnjẹ márùn ún tó ń mú kí àtọ̀ ọkùnrin dára síi
- Wo ìpalára ní ọ̀nà mẹ́fà tó lè bá ènìyàn tí kò bá kí ń mu omi mímu tó ìwọn tó yẹ
- Sunday Igboho fún Fulani Oyo ní gbèǹdéke, Seriki fulani yarí, ọlọ́pàá dá síi...
Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu wa fikun wi pe ijọba ipinlẹ naa ninu aanu rẹ wa fun wọn ni gbedeke ọjọ meje fun awọn Fulani darandaran to ba fẹ ma a ṣiṣẹ ni ipinlẹ Ondo lati fi orukọ wọn silẹ pẹlu awọn alaṣẹ.