Darfur Sudan killings: Ó lé ní ọgọ́rin èèyàn tó kú nínú ìjà ẹlẹ́yàmẹ́yà tó wáyé ní Dafur- Aláṣẹ Sudan

Sudan

Oríṣun àwòrán, AFP

Awọn alasẹ orilẹ-ede Sudan ti sọ pe o le ni ọgọrin eeyan to kú ninu ija ẹlẹyamẹya to waye ni Darfur.Iroyin naa fi kun pe ọpọlọpọ eeyan lo tun farapa lasiko rogbodiyan naa to waye ni agbegbe El Geneina.Rogbodiyan naa ko yọ ibudo ti awọn eeyan ti ogun sọ di alainilelori wà, nitori pe awọn kan kọlu wọn.

Àkọlé fídíò, BBC findings on lekki shooting: Ẹ wa wo àwọn tó ṣì ń wá ẹbí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ End SARS 2020

Gbogbo eyi waye lẹyin ti ijọba ati ikọ ọlọtẹ fi ọwọ si iwe adehun l'oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, lati jẹ ki alaafia waye.Ibẹrẹ oṣu yii si ni awọn ọmọ ogun ajọ isọkan agbaye, United Nations, bẹrẹ si ni kuro ni orilẹ-ede naa. Iroyin sọ pe rogbodiyan tuntun yii bẹrẹ lasiko ti ọkùnrin kan gun ọkùnrin kan to jẹ ẹ̀yà Arab pa.

Eyi si lo fa ìjà laarin ẹ̀yà mejeeji.

Ijọba ti fi awọn ọmọ ogun ránṣẹ, lati daabo bo araalu. Ninu ija yii, ajọ UN sọ pe ọpọlọpọ ile, ọjà, ati sọọbu ni wọn dana sun, ti awọn janduku si ko awọn ẹrù to wa ninu wọn.

Àkọlé fídíò, Ado Ekiti Blind Couple: Tọkọ-taya Oke ní Ọ́ba òkè ló fi àwọn dá àrà tó wù ú

O ni wahala to n waye lai dawọ duro ni awọn agbegbe kan ni Darfur ti mu ki awọn eeyan ti ko ri ile gbe kò pọ si. Bakan naa ni ile ẹjọ ẹsun ọdaran l'agbaye, ICC, n wa aarẹ tẹlẹ, Omar al-Bashir, ti wọn yọ kuro ni ipo lọdun to kọja, fun ẹsun àṣemáṣe lasiko ogun ati pipa awọn ẹ̀yà kan run ni agbegbe naa. Ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin ọhun n jẹ ẹjọ lọwọ ni Khartoum fun ipa to ko ninu iditẹ gba jọba lọdun 1989.