Jubril Martins-Kuye: Mínísítà lẹ́ẹ̀méjí, Jubril Martins-Kuye ti jáde láyé

Jubril Martins-Kuye

Oríṣun àwòrán, Premium times

Eekan oloṣelu kan ni ipinlẹ Ogun to tun ti fi igbakan ri jẹ minisita fun karakata ati idaleeṣẹsilẹ lorilẹede Naijiria, Jubril Martin Kuye ti jade laye.

Nnkan bii agogo mẹwaa owurọ ọjọ Aiku lo jade laye.

Ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹjọ ọdun 1942 ni wọn bi Oloogbe Jubril Martins Kuye ki Aarẹ ana, Goodluck Jonathan to yan an gẹgẹ bii minisita lọjọ kẹfa, oṣu kẹrin, ọdun 2010.

Bakan naa lo tun di ipo minisita abẹle fun eto iṣuna labẹ iṣejọba aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ titi di ọdun 2003.

Ko tii si iroyin kankan to tii jade nipa ohun to ṣokunfa iku rẹ, ṣugbọn iroyin sọ pe ilu rẹ, Agọ Iwoye lo mi eemi ikẹyin sii

Àkọlé fídíò, Ado Ekiti Blind Couple: Tọkọ-taya Oke ní Ọ́ba òkè ló fi àwọn dá àrà tó wù ú