Marriage dispute: Ìyàwó mi fi mí sílẹ̀ kó lọ sílé ọkùnrin míì nínú báráàkì kan náà, àmọ́ mò sí tún fẹ́ràn rẹ̀

Igbeyawo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Sọja kan to ti fẹyin ti lẹnu iṣẹ ologun, Richard Imana ti sọ fun ileẹjọ ibilẹ (Customary court) niluu Eko pe ko tu igbeyawo ọdun mẹwaa oun pẹlu aya rẹ ka.

Ọgbẹni Imana fi ẹsun kan iyawo rẹ, Nkem pe o fi oun silẹ, ko si tun foun laye lati ri ọmọ oun.

Imana sọ fun ileẹjọ naa pe Nkem ko kuro nile oun, o si ko lọ si ile ọkunrin mii ninu baraaki kan naa tawọn n gbe.

Ọgbẹni Imana to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogoji ṣalaye pe iyawo oun ko lọ ba ọkunrin mii nigba ti iṣẹ gbe oun lọ si ipinlẹ Borno.

''Mo bẹrẹ si ni tọju awọn ọmọ wa nitori iyawo mi ko tọju wọn mọ,'' Imana lo sọ bẹẹ.

Sọja naa tun fikun ọrọ rẹ pe iyawo oun kọ lati buwọ luwe nigba ti dokita to n tọju oun ni ko ṣe bẹẹ nigba ti ara oun ko ya.

Oruka

Oríṣun àwòrán, others

O ni iyawo oun tun mu abikẹyin awọn lọ si ọdọ mama rẹ lai gbaṣẹ lọwọ oun.

Amọ, sọja ọhun ni oun si fẹran iyawo oun lẹyin ti ọmọ mẹta ti wa laarin wọn.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa: Mọ̀ síi nípa ìró afárànma àti agbárànmọ́ fáwẹ́ẹ̀lì Yorùbá

Ninu ọrọ tiẹ, Nkem sọ fun ileẹjọ pe ọdọ ọrẹ oun obinrin to wa nile ọkọ loun ko lọ lẹyin ti ọkọ oun ko fowo ounjẹ ranṣẹ si oun atawọn ọmọ mọ.

''Irọ ni pe mo ko lọ sile ọkunrin mii, ọdọ ọrẹ mi ni mo lọ nigba ti iṣẹ gbe ọkọ mi lọ si Borno,'' Nkem lo ṣalaye bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni wọ́n ti já àbálé Esra lábẹ́ àwáwí àyẹ̀wò wúndíá

O rọ ileẹjọ lati bawọn yanju aawọ to wa laarin nitori oun si nifẹ ọkọ oun bo tilẹ jẹ pe ko nifẹ oun.

Aarẹ kootu naa, Ọmọba Adewale Adegoke sọ fawọn mejeeji lati jọ sọ asọyepọ laarin ara wọn.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Wo ìtàn ìyá kan ìyá kan àtàwọn olè ajọ́mọgbé tó n ta ọmọ ní Kenya