New Covid-19 Strain UK : Atiku ní kí ìjọba dì ìrìnnà ọkọ̀ òfurufú láàrin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sí Nàìjíríà kú nítorí Covid-19

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, @Atiku

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ina esisi ko gbọdọ tun jo wa lẹẹkan si, ẹ ti papakọ ofurufu ki Covid-19 ma baa yọ wọle lẹẹkeeji.

Ikilọ ree lati ẹnu Igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ ri Atiku Abubakar lori ọna ati dena itankalẹ arun Covid-19 lẹẹkeeji ni Naijiria.

Atiku to tun dije dupo aarẹ ninu idibo ọdun 2019 sọ pe aitete gbe igbesẹ ijọba nigba ti ajakalẹ akọkọ waye lo jẹ ki ọrọ di bo ti ṣe ri loni.

Loju opo rẹ ni Twitter lo kọ ọrọ yi si pẹlu bi ọwọja itankalẹ arun Covid-19 ṣe n peleke si ni Naijiria.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Atiku mu akawe bi awọn orileede miran nilẹ Yuroopu ti ṣe ti n ti bode wọn pẹlu ilẹ Gẹẹsi lọna ati kọdi itankalẹ ẹda Covid-19 kan to n ja rainrain ni ibẹ.

Ninu awọn orileede taa n sọ yi ni Italy, Belgium ati Netherlands wa.

O ni awọn orileede ti wọn ko jafara ti n gbe igbesẹ to yẹ nitori naa ki Naijiria di lilọ bibọ ọkọ ofurufu lati ilẹ Gẹẹsi si Naijiria ku.

UK

Oríṣun àwòrán, @82ndBigCountry

Atiku pari ọrọ rẹ pe eto ilera Naijiria ko munadoko debi ti yoo le tọju awọn to ba lugbadi arun naa.

Igbọran gẹgẹ bi o ti ṣe wi, san ju ẹbọ ruru lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adari ile aṣofin ipinlẹ Niger

Adári ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Niger àti akọ̀wé náà ti lùgbàdì Covid-19

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni pe adari ile igbim aṣofin ipinlẹ Niger, Abdullahi Bawa ati akọwe ile, Abdullahi Kagara ti ni esi ayẹwo to sọ pe wọn lugbadi arun Covid-19.

Lati igba naa ni ati adari ati akọwe rẹ ti wa ni iyasọtọ.

Kọmisọna eto iroyin nipinlẹ naa, Muhammed Idris lo fidi ọrọ yii mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku.

Eyi ti mu ki gbogbo awọn ọmọ ile atawọn oṣiṣẹ lọ ṣe ayẹwo Covid-19.

Ninu oṣu kọkanla ni gomina ipinlẹ naa, Abubakar Bello naa gba esi to fihan pe o lugbadi arun naa ṣugbọn ti ara rẹ ya lẹyin ọsẹ kan.

Ṣé lóòtọ́ ni Adajọ́ Àgbà Naijiria, Tanko Muhammad náà ti ní Covid-19?

Tamko Muhammad

Oríṣun àwòrán, Twitter/@NGRPRESIDENT

Ibeere ti ọpọ n beere ni pe ṣe lootọ ni Adajọ Agba Naijiria, Tanko Muhammad ti ni aarun Covid-19?

Ọpọ ileeṣẹ iroyin n kede pe ọkan lara awọn adajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria, Onidajọ Ibrahim Saulawa lo fi ikede naa sita, nibi ayẹyẹ ikojade olu ile ẹgbẹ awọn agbẹjọro to jẹ Musulumi, to waye nilu Abuja lọjọ Iṣẹgun.

Onidajọ Saulawa sọ pe ilu Dubai, ni orilẹ-ede United Arab Emirate, ni Tanko Muhammad wa, to ti n gba itọju.

Sugbọn gbogbo igbiyanju BBC lati fidi ọrọ yii mulẹ ni ko yọri nitori ọpọ awọn to le sọrọ nipa rẹ nitootọ ni awọn ko fẹ sọrọ lasiko yii.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa: Mọ̀ síi nípa ìró afárànma àti agbárànmọ́ fáwẹ́ẹ̀lì Yorùbá