Coronavirus: Àwọn ọmọ Nàìjíríà n polongo pé ibìkan nàá ni kí olórí àti ọmọ ìlú ní Nàìjíríà ti gba ìtọ́jú

Abba Kyari

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lati igba ti ajọ to n dena ajakalẹ aarun ni Naijiria, NCDC, ti kede pe olori awọn oṣiṣẹ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Abba Kyari naa ti ni aarun coronavirus, ni awọn ọmọ Naijiria kan, paapa lori ayelujara ti n sọ pe asiko yii ni awọn alaṣẹ Naijiria yoo ni imọlara aitun ẹka eto ilera Naijiria ṣe.

Ọrọ ti wọn n sọ tun wa a peleke, lẹyin ti iroyin kan jade pe wọn fẹ ẹ gba Kyari wa sileewosan nilu Eko fun itọju, dipo ilu Abuja to n gbe.

Ọpọ lo n sọ pe ko yẹ ko ribẹ, wọn sọ pe ibikibi ti ẹni to ni aarun naa ba n gbe loyẹ ki wọn o ti tọju rẹ.

Àkọlé fídíò, Coronavirus: Fífi nkan bó ìmu nìkan kò le dènà kíkó coronavirus

Bakan naa ni awọn kan tun n sọ pe ẹsan aitun awọn ileewosan orilẹ-ede yii ṣe lo delẹ yii.

Ati pe ki awọn olori to ba ni i, ko gba ilu oyinbo ti wọn maa n lọ tẹlẹ lọ lati gba itọju.

Ẹ ka eero awọn ọmọ Naijiria ni oju opo isalẹ yii.

Ọpọ lo ti lẹ n sọ pe kini ijọba fi obitibiti biliọnu Naira ti wọn n fi sinu owo iṣuna lati fi gbọ bukaata ileewosan to wa nile ijọba l'Abuja.

Ọpọ lo n sọ pe aitun ilu ṣe, ati ileewosan to wa ni Naijiria ko ṣẹyin wọn. Pe ka ni wọn tun orilẹ-ede Naijiria ṣe boṣeyẹ ni, nkan i ba wa daada lẹka eto ilera.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ayẹwo ti fihan gbangba pe igbakeji aarẹ Naijiria, Yemi Osinbajo ko ni arun coronavirus.

Yemi Osinbajo ati Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Instagram/profosinbajo

Àkọlé àwòrán, Àyẹ̀wò ti fihàn pé igbákejì ààrẹ Yemi Osinbajo ò ní covid-19

Ọjọgbọn Osinbajo ti ya ara rẹ sọtọ fun ayẹwo nitori ajakalẹ arun Coronavirus tẹlẹ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Oludamọran si ararẹ Muhammadu Buhari lori ọrọ oṣelu, Babafemi Ojudu lo fọrọ naa lede loju opo Twitter rẹ.

Ọpọ ọmọ Naijiria ni wọn ki baba ku ajaye, bẹẹ ni wọn ki i ku oriire loju opo Twitter.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Skip X post, 4

End of X post, 4

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ
Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Yemi Osinbajọ ti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún àyẹ̀wò àrùn Coronavirus

Igbesẹ yi lo n waye lẹyin ti amugbalẹgbẹ aarẹ Muhammadu Buhari, Abba Kyari fara kaasa arun naa.

Oluranlọwọ agba fun igbakeji aarẹ lori ọrọ to n lọ, Laolu Akande lo fi ọrọ naa lede loju opo Twitter.

Àkọlé fídíò, Coronavirus: Gbogbo igbá ti ṣófo láwọn ilé ìtajà káàkiri London
Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 6

O ni "Igbakeji aarẹ Osinbajọ ṣe ipade ninu ọfiisi rẹ lana pẹlu fidio lori itakun agbaye. Loni ni yoo bẹrẹ si ni ṣe iṣẹ lati ile rẹ, gẹgẹ bi ilana yiya ara ẹni sọtọ ti ileeṣẹ NCDC gbe kalẹ."

Yatọ si amugbalẹgbẹ aarẹ to ti lugbadi arun ọhun, gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed naa ti fara kaasa arun ọhun.

Yemi Osinbajo ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram/profosinbajo

Lọwọ yii, eeyan mẹrindinlaadọta lo ti ni arun naa lorilẹ-ede Naijiria, leyi to ti mu ki ijọba apapọ ti ilekun gbogbo ileewe, ti awọn ijọba ipinlẹ kan si ti gbe agadagodo sẹnu ọna ileeṣẹ ati ọja wọn.

Coronavirus: Soyinka rọ ìjọba láti pe àwọn ilé ìjọsìn tó tàpá sófin kóníléogbélé lẹ́jọ

Wole Soyinka

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Soyinka rọ ìjọba láti pe àwọn ilé ìjọsìn tó tàpá sófin kóníléogbélé lẹ́jọ

Ìjọba Naijiria kò ṣe dáadáa tó lórí ìtànkálẹ̀ àrùn Coronavirus- Soyinka

Ọjọgbọn Wole Soyinka ti bu ẹnu ẹtẹ lu ijọba apapọ ati awọn olori ẹlẹsin lori iha ti wọn kọ si itankalẹ arun Coronavirus ni Naijiria.

O ni ijọba Naijiira ko kọbi ara si arun naa ko to di pe o di tọrọfankale bayii ti ẹru ti n ba tonile talejo.

Ọjọ kẹrindilogun, Oṣu Kẹta, ọdun 2020 ni ọjọgbọn naa wọ Naijiria lati ilẹ Amerika, to si fi ara rẹ pamọ fun ayẹwo coronavirus lẹyin irinajo ọhun.

Soyinka sọ fun BBC ninu ifọrọwerọ kan pe, to ba jẹ pe ijọba Naijiria ti ṣe ohun to tọ lasikọ to yẹ ni, arun naa kò ba ma ti tan kalẹ to bo ṣe ri yii.

O ni "O yẹ ki Naijiria ni ẹka ile iwosan to le koju iṣẹlẹ pajawiri, ile oogun ati awọn irinṣe to dantọ lati koju ajakalẹ arun bi Coronavirus, ṣugbọn niṣe ni ijọba fi ẹtẹ silẹ, to n mojuto lapalapa."

Ọjọgbọn Ṣoyinka ṣalaye pe owo to yẹ ki ijọba fi koju ajakalẹ arun bi Coronavirus ni awọn kan ti ko sapo, ti wọn si ti fi ṣe awọn iṣe akanṣe ti ko ṣe ara ilku lanfani kankan.

Ogbontarigi onkọwe yii ni oun ti ya ara oun sọtọ gẹgẹ bi o ṣe yẹ ki oun to mọ lẹyin ọjọ mẹrinla boya oun ni tabi bẹẹkọ

Ṣoyinka pari ọrọ rẹ pe o yẹ ki ijọba pe awọn ṣọọṣi ati mọṣalaṣi to tapa si aṣẹ rẹ lẹyin to wọgile ipejọpọ ti eeyan rẹ ju aadọta lọ lẹjọ.

Lasiko ti Soyinka n ba BBC sọrọ lori ẹrọ ibanisọrọ lo ti ni o yẹ ki awọn adari ijọ tabi mọṣalaṣi bẹẹ le kọ ẹkọ to yẹ lai yọ awọn olujọsin ti ko naani ẹmi ara wọn silẹ.

Àkọlé fídíò, Nikesuliat: Ọ̀dọ́mọdébìnrin akéwì tó n fi ẹ̀ṣà kìlọ̀ ìwá lásìkò yìí

O ni "Ohun to yẹ ki ijọba ṣe ni ko fi iya to tọ jẹ gbogbo ile ijọsin to kọti ikun si aṣẹ ọun, nitori ko si iyatọ laarin wọn ati awọn agbesumọmi to n gbẹmi awọn eeyan."

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'