Manu Dibango: Covid-19 ti pa akọni afúnfèrè Sax ilẹ̀ Africa

Oríṣun àwòrán, AFP
Àgbà ọ̀jẹ afunfere Sax Man Dibango ti ku ni ilú Paris lẹ́yin to he aàrun Coronavirus.
Dibango ti ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ fun orin rẹ to pe ni Soul Makossa lọ̀dun 1972 ti jade laye. Oun ni ẹni akọkọ ninu àwọn gbájugbaja àgbáyé ti Covid 19 yóò pa.
Ẹni ọdún mẹ́rìndínláàdọrún to maa n kọrin jazz àti ti ibilẹ papọ jé ọmọ orilẹ-ede Cameroon.
"Pẹlú ìbànújẹ ọkàn ni a fi kéde ikú Manu Dibango to jẹ baba amayedun" nínú àtẹjáde to jẹyọ lori atẹjisẹ Facebook rẹ.
'A o ni sin òkú rẹ̀ ni ojútaye a si fẹ́ ki àwọn ènìyàn fi ikíní ẹdùn wọ́n ranṣẹ́ si láti ori àtẹ̀jisẹ a o gbé bá wọ́n gbe jáde.
Àwọn olorin ilẹ̀ Afirika to fi mọ Angelique Kidjo àti Youssou N'Dour ti sááju nínú ìkíni.
Lóri àtẹjisẹ́ Twitter, Kidjo pin fọ́nran kan ti wọn gbà kalẹ̀ ni oṣù méji sẹ́yin lásiko ti wọ́n n gbáradi fún orin Makossa pẹlu Dibango.
Bayii ni olorin ọmọ Benin naa ṣe kọọ sibẹ̀ pé "iwọ gan an ni erin olorin ilẹ̀ Afirika àti èniyan to rẹwa"
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post

N'Dour pe ọmọ olorin Cameroon naa ni ọlọgbọ́n inú paápàá jùlọ lori ìlò Saxophone to si sàpejúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ẹgbọ̀n àgbà ati ohun amuyangan fun Cameroon ati ilẹ Africa.
N'Dour àti Kidjo, pẹlú àwọn gbajugbaja olorin míràn bii Salif Keita, Papa Wemba àti King Sunny Ade ni wan jọ ṣe iṣẹ́ pọ lori Dibangu ni ọdun 1992 to pe akọle rẹ̀ ni Wakafrika.
Lásìkò to n ba BBC sọ̀rọ̀ lọdun 2013 lori bi o ṣe fẹ ki àwọn ènìyàn maa ranti òun, Dibangu sọ pé ti ènìyàn ba ti ku, o ti tan niyẹn, kò si ni ìkáwọ mi mọ lati sọ pe mo fẹ́ nkan bayìí"
Ilú Doula ni a ti bii lọ́dun 1933, lásìkò ti ilu yii wa lábẹ àwọn Faranse, iṣẹ́ orin Dbango si tan ka fu bi ọgbsn ọdun.















