Anthony Joshua vs Pulev highlights: Ẹ̀bùn ọdún Kérésìmesì ni àseyọrí Joshua lẹ́yìn tó na Pulev lálùbolẹ̀ - Dapo Abiodun

aj

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ti ki abẹṣẹkubiojo,Anthony Joshua ku oriire lẹyin to bori ojugab rẹ lati orilẹ-ede Bulgaria, Kubrat Pulev ni gbagede SSE Arena ni ilu London lalẹ ọjọ Abamẹta.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Kunle Somorin fi lede, Abiodun ni Johsua gbe ogo ipinlẹ Ogun ga.

Gẹgẹ bi ohun ti gomina naa sọ, o ni ẹbun nla ni aṣeyọri naa jẹ, ati pe yoo tun jẹ ohun iwuri fun awọn elomiran lati tẹpa mọ ohunkohun ti wọn ba yan laayo.

Atẹjade naa ni "gbogbo wa ni ipinlẹ yii ni a gbadura fun aṣeyọri rẹ lai wo ti ẹsin."

"Mo le ka aṣeyọri nla to waye lalẹ ana ni London gẹgẹ bi ẹbun ọdun Keresimesi lati ọdọ Ọlọrun ati Anthony Joshua fun gbogbo wa ni ipinlẹ Ogun."

aj

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Abiodun ṣalaye pe Anthony Joshua, to tun jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ogun ti gbe ogo Naijiria ga, o si tun fi han awọn eeyan pe orilẹ-ede Naijiria ṣi maa bori gbogbo idojukjọ to n la kọja.

Gomina naa sọ pe adura awọn eeyan lo n gba lori abẹṣekubiojo naa ti ade IBF, WBA ati WBO ko tii fi bọ mọ lọwọ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Nigba to n sọrọ loju opo Twitter rẹ, Abiodun fi kun pe aṣeyọri naa ti fi han pe gbogbo owo ti ijọba ipinlẹ Ogun ati akitiyan rẹ lori ere idaraya ko lọ lasan.

Àkọlé fídíò, Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni wọ́n ti já àbálé Esra lábẹ́ àwáwí àyẹ̀wò wúndíá

Alẹ ọjọ Satide, ọjọ kejila, oṣu kejila ọdun 2020, ni ija naa waye ni gbagede SSE Arena, ni ilu London, nibi ti Joshua ti fi ẹṣe ja Pulev bọ bi apo irẹsi.

Yatọ si Abidoun, Aarẹ Muhammadu Buhari naa ti ki Joshua ku orrire aṣeyọri ọhun.