RCCG Congress 2020: Pásítọ̀ ní owó Naira yóò sì tún gbé pẹ́ẹ́lí lẹ́ẹ̀kàn síi

Adeboye

Oríṣun àwòrán, @thehgcongress

Alabojuto gbogbogbo fun ijọ Redeemed Christian Church of God, RCCG, Pasitọ Enoch Adeboye ti sọ pe owo Naira yoo si tun pada niyi lawujọ awọn owo orilẹ-ede to gbe pẹẹli julọ lagbaye.

Adeboye lo sọ ọrọ naa laarọ ọjọ Abamẹta nibi ipade adura Holy Ghost Congress to maa n waye lọdọdun ni Olu ijọ naa to wa lọna marosẹ Eko si Ibadan.

Ẹni ọdun mejidinlaadọrin ọhun gbadura pe ki Ọlọrun da si eto iṣuna Naijiria, ko si tun yi ọkan awọn alaṣẹ to n mọọmọ ṣe awọn eto to n pa owo Naira lara pada.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adeboye sọ itan kan fun awọn eeyan to wa nibi ipade adura naa pe, ni ọpọ ọdun ṣeyin, oun nilo ẹgbẹrun marun un naira pere lẹyin ti oun pe ọpọ ero sibi ipade adura pẹlu ileri pe oun yoo gbọ bukata jijẹ ati mimu wọn.

Bo tilẹ jẹ pe ko ni owo naa lọwọ, o ni Ọlọrun pese owo ọhun lọna iyanu.

Pasitọ naa ni "owo Naira niye lori lọdun naa lọhun, yoo si tun niye lori lẹẹkan sii."

Adeboye

Oríṣun àwòrán, @thesignalng

"Gbogbo awọn to n mọọmọ rẹ owo naira silẹ, Ọlọrun yoo da si ọrọ wọn ki ilẹ ọla to mọ."

Ọpọ ọmọ Naijiria to ti n lọgun pe owo naira ko niyi mọ lati nkan bi ọdun diẹ sẹyin, paapaa lẹyin ti owo dollar kan parada di ẹẹdẹgbẹta naira.

Awọn to maa n ṣẹ owo ilẹ okere, Bureau De Change, sọ pe idi ti owo naira ṣe n lọ soke silẹ ko ṣẹyin awọn eeyan kan.

Ẹwẹ, banki apapọ Naijiria, CBN, ni owo dollar kan ko to irinwo naira, gẹgẹ bi iṣiro to wa loju opo wọn lori ayelujara.

Gómìnà Obaseki ní pásítọ̀ Adeboye sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé òun yóò wọlé ìbò gómìnà Edo lẹ́ẹ̀kejì

Godwin Obaseki

Oríṣun àwòrán, Facebook/Godwin Obaseki

Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki ti ṣalaye pe, oludari ijọ Redeemed Christian Church of God, Enoch Adeboye gbadura foun, o si tun sọ asọtẹlẹ pe oun yoo wọle ibo gomina ipinlẹ Edo fun saa keji.

Gomina Obaseki sọrọ yii lasiko to n jẹri nibi akanṣe eto ọlọdọọdun ijọ Redeem, RCCG Holy Ghost Congress ti ọdun 2020 yii lọjọ Ẹti.

Obaseki ni ''nigba ti ogun gbona giri giri, emi ati iyawo mi ṣabẹwo si Daddy G.O. ni ipagọ ijọ Redeem to wa lopopona ilu Eko si Ibadan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Lẹyin ti mo ṣalaye ipenija mi lagbo oṣelu tan, pasitọ Adeboye sọ pe ''ọmọ mi, ma foya, iwọ ni yoo bori, wa si wọle ibo gomina lẹẹkeji,'' Obaseki lo sọ bẹẹ.

Gomina ni oun pada lọ ri alufaa Adeboye nigba ti idibo gomina ọhun ku diẹ, o si tun sọ foun pe gbogbo rẹ maa dara lẹyin ''to gbadura fun mi tan.''

Oshiomole ati Obaseki

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ oṣelu APC lo gbe Obaseki wọle fun saa kinni gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Edo.

Ṣugbọn ẹgbẹ APC ko fun un lanfaani lati jẹ oludije ẹgbẹ ọhun ninu idibo ọdun 2020, lẹyin rogbodiyan to ṣẹlẹ pẹlu alaga gbogbo-gboo ẹgbẹ oṣelu naa tẹlẹ, Adam Oshiomole.

Pasitọ Osagie Eze-Iyamu ni APC fun lanfaani lati dije fun ipo gomina, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu naa dipo Obaseki.

Eyi lo mu ki Obaseki lọ sinu ẹgbẹ oṣelu PDP, nibi to wọle ibo gomina ipinlẹ lẹẹkeji.