ICC: Ẹ̀rí wà pé àwọn ológun Nàíjíríà ń hùwà ìka sí Boko Haram àti ọmọnìyàn

Awọn ọmọ ogun Naijiria

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn ileesẹ agbofinro ilẹ wa lo seese ko lọ jẹjọ ẹsun iwa ọdaran si ọmọniyan nileejọ agbaye to n gbọ ẹsun iwa ọdaran.

Ẹsun ti wọn fi kan awọn agbofinro naa ni pe wọn huwa ọdaran lasiko ti wọn lọ koju ikọ agbesunmọmi Boko Haram lẹkun ariwa orilẹede yii.

Agbefọba kan nileejọ agbaye naa, Fatou Bensouda lo sisọ loju ọrọ naa ninu atẹjade kan to fisita nipa iwadi ohun to n waye ni Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni awọn koko ẹri ti wa nilẹ lati foju awọn ileesẹ agbofinro lorilẹede Naijiria wina ofin nipa ihuwasi wọn si ikọ Boko Haram.

Olori ikọ Boko Haram, Abubakar Shekau

Oríṣun àwòrán, AFP

"Gẹgẹ bi awọn ikọ Boko Haram yoo se jẹjọ ẹsun hihu iwa ọdaran loju ogun, naa lawọn ileesẹ ologun Naijiria yoo jẹjọ awọn iwa aidaa ti wọn hu bii ipaniyan, ifipabanilopọ, ifiyajẹni ati iwa ika lọdọ ileẹjọ ICC.

Bakan naa ni ileẹjọ ICC n sewadi ileesẹ ologun ilẹ wa lori ẹsun gbigba awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ti to ọdun mẹẹdogun sisẹ ologun.

O ni wọn n gba awọn ọmọde naa laaye lati maa kopa ninu iwa ikorira, ifiyajẹ eeyan tori ọrọ isẹda wọn ati ti oselu to fi mọ awọn iwa kotọ mii si ọmọniyan.

Ikọ boko Haram to mura bi ologun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yatọ si eyi, bakan naa ni Bensouda fikun pe awọn ologun naa yoo tun jẹjọ lori pe wọn kopa ninu iwa "kikan nipa fun araalu lati poora, kiko awọn eeyan kuro lagbegbe wọn, ibinu si eeyan kan, kikọlu araalu ati mimu wọn si ahamọ laitọ."