Àwọn ìgba mẹ́rin t'áwọn èèkàn tí dùbúlẹ̀ àìsàn lásìkò tí wọ́n ń jẹ́jọ́ níwájú adájọ́

Maina lori wheelchair

Oríṣun àwòrán, other

Ọga agba ile isẹ to n risi owo awọn osisẹfẹyinti tẹlẹri, Abdurasheed Maina, ti darapọ mọ awọn eeyan to daku nile ẹjọ lẹyin ti wọn fi ẹsun ikowojẹ kan wọn.

Ọjọ kẹwaa, loṣu Kejila, ọdun 2020 ni Maina daku rangbọdan nile ẹjọ lẹyin ti ile ẹjọ pada bẹrẹ si n gbọ ẹsun ti wọn fi kan pe o lu biliọnu meji naira ni ponpo.

Pupọ ninu awọn ọmọ Naijiria lo ti n sọ pe oun ti Main ṣe kii ṣe tuntun nitori awọn eeyan kan ti wọn fi iru ẹsun bẹẹ kan ti daku bẹẹ ṣaaju akoko yii.

Wo diẹ lara awọn eeyan to ti daku bii Maina, tabi to dede dubulẹ aisan lẹyin ti wọn fẹsun ikowojẹ kan wọn.

Dino Melaye

Dino jẹ ọkan gboogi lara awọn oloṣelu to ni idan lọwọ ni Naijiria nitori ko ṣeni to le sọ iru aṣa ti o le ti ọwọ rẹ jade.

Melaye lori stretcher

Oríṣun àwòrán, @sumner_sambo

Ni oṣu Kẹrin, ọdun 2018 ni Melaye dede fo kuro ninu ọkọ to wa lori ere, eyii ti wọn fi n gbe lọ lati koju ẹsun kan ti wọn fi kan.

Igba to di ọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2019 ni Melaye fa ara rẹ ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ lẹyin ọjọ meje ti wọn ti wa lẹnu ọna ile rẹ.

Lẹyin iṣẹju diẹ to jọwọ ara rẹ fun awọn agbofinro tan lo dede ṣubu lulẹ, ti ko si le rin mọ.

Ṣugbọn lẹyin ti wọn gbẹ lọ si ọọfisi lo tun ṣubu lẹẹkeji, to si n mi gulegule bi ẹni ẹmi fẹ bọ lẹnu rẹ..

Olisa Metuh

Ni ọdun 2018 kan naa ni wọn gbe Olisah Metuh to jẹ alukoro tẹlẹ fun gbẹ oṣelu PDP.

Maina lori wheelchair

Oríṣun àwòrán, other

Ajọ EFCC gbe Olisah Metuh lọ sile ẹjọ giga kan nilu Abuja fun gbigba irinwo miliọnu naira lọwọ ọfiisi alamojuto abo lorilẹede Naijiria lọdun 2014.

Nigba ti yoo fi wa si igbẹjọ nileẹjọ, gbalaja bayii ni Metuh sun sori bẹẹdi alaarẹ, Stretcher wa si ile ẹjọ.

Kemebradikumo Pondei

NDDC Probe

Oríṣun àwòrán, NDDC

Àkọlé àwòrán, Ọjọgbọ́n Kemebradikumo Pondei

Oṣu Keje ọdun 2020 ni adele Ọga Agba ajọ to n mojuto idagbasoke agbegbe Niger Delta, Ọjọgbọn Kemebradikumo Pondei, daku rangbọndan lasiko ti iwadii ẹsun bi wọn ṣe na owo ajọ NDDC labẹ rẹ n waye.

Pondei daku lasiko to n ṣalaye iye owo ti ajọ NDDC na labẹ iṣakoso rẹ.

Ọjọgbọn Pondei nibi to ti daku sori aga to joko si i

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Niṣe ni gbogbo awọn to wa nibi ijoko naa n sare kijokijo lasiko ti Ọjọgbọn Pondei daku lori aga to joko si.

Eyi si mu ki gbogbo awọn to tẹle e wa sibẹ o ma a fẹ ẹ l'oju, fẹ ẹ nimu, rọ omi si i l'ori ko ma baa gba bẹ lọ.

Haliru Bello

Haliru, to jẹ alagba ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ ni ajọ EFCC fẹsun mẹrin to jọ mọ didari owo ijọba si apo ara rẹ kan lọdun 2015.

Nigba ti alaga naa yoo wa siwaju ilke ẹjọ, inu aga awọn abarapa ti ko le rin lo ti wa sile ẹjọ.

Maj. Gen. Hakeem Otiki

Inu aga arọ ti ko lẹsẹ naa ni ọgagun Hakeem Otiki ti wa sile ẹjọ awọn ologun lọdun 2020.

Army

Oríṣun àwòrán, @Chikelinks

Wọn fẹsun kan ọgagun naa pe o ko owo awọn ọmọ marun un to salọ sapo ara rẹ lọdun 2019.

Lẹyinorẹyin, ile ẹjọ naa ni ki wọn rẹ ipo rẹ silẹ lati Major General si Brigadier General, ki wọn si tun fi ọwọ osi juwe ile fun.

Owo ti wọn ni o lu ni ponpo ko ni din ni irinwo miliọnu naira.