Google searches Nigeria 2020: Hushpuppi, Naira Marley, Rema, ASUU wà lára ohun táwọn èèyàn ń wá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oju opo Google maa n saba ṣagbejade ọrọ ti awọn eeyan n wa julọ lori itakun wọn, ti onikaluku orilẹede n wa lọdọọdun.
Bakan naa ni oju opo yii maa ṣagbejade mẹwaa loke tente lara awọn orin, ere idaraya, awọn oṣere ati fiimu wọn gangan to fi mọ ifọrọwanilẹnuwo to fakọyọ.
Labẹ isọrii awọn mẹwa to pọju tawọn eeyan n bi google leere nipa wọn ju, awọn olorin ọmọ Naijiria bii Rema, Naira Marley, Omah Lay ati ajaweolubori eto ile Ẹlẹgbọn agba (Big Brother Naija Lock down Season 5), Laycon naa wa nibẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Obasanjo àti Gani Adams tẹ́ mi pẹ̀lú bí wọn ṣe tahùn síra wọn - Adebanjo
- Buhari le sọ ipò ààrẹ́ nù tí kò bá yọjú sáwọn aṣòfin - Amòfin
- Ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò takú láti gba èsì ìbò ààrẹ ní Ghana
- Ọ̀pọ̀ nkan tó n ṣẹlẹ̀ kò jẹ́ kí n gbàgbọ́ pé Naijiria wà ní abẹ́ ìdarí ẹnikẹ́ni - Wole Soyinka
- Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ṣoro ní Ijebu Ode, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sọnù
Ẹni akọkọ lorii ila awọn ti wọn n wa ju lori google ni aarẹ tuntun ti wọn dibo yan l'Amẹrika, Joe Biden, lẹyin naa ni Rema ati Naira Marley tẹle e.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbajugbaja oṣere fiimu Hausa, Rahama Sadau ni o wa nipo kẹrin. Ninu oṣu kọkanla ni Rahama gbayi lori google tori awọn fọto rẹ to fọnka sorii ayelujara.
Awọn fọto yii da wahala silẹ gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe ni o lodi si ilana "Prophet Mohammed" ti awọn mii si ni awọn o rohun to buru nibẹ.
Maryam Sanda, obinrin ti wọn fẹsun kan pe o pa ọkọ rẹ lọdun 2017, ti ile ẹjọ si dajọ iku nipa yiyẹgi fun un nibẹrẹ ọdun yii, naa wa lara awọn ohun ti wọn n wa loju opo agbaye yii.
- Àlàyé rèé lórí ìdí tí mo fi lọ sílé Tinubu - Rashidi Ladoja
- ‘Sim Card’ títà àti ìforúkọsílẹ̀ rẹ̀ dèèwọ̀ ní Nàíjíríà - NCC
- Ẹ̀yin tí ẹ máa ń bú àwon tó sanra ni ẹ ń jẹ́ kí wọ́n ronú pa ara wọn - Eniola Badmus
- Ṣé lóòtọ́ ni tírélà ti gba ààrín Ronke Odusanya àti bàbá ọmọ rẹ̀, Jago? Nkan tí a mọ̀ nìyíì
- Mo ti kúrò ní ààfin Oyo, kí ìròyìn tó ò jáde pé èmi àti Wasiu Ayinde n fẹ́ ara wa - Olori Badirat
Gẹgẹ bi google ṣe sọ ọ, Maryam Sanda ni ẹni ikẹẹsan lori ayelujara ni Naijiria lọdun yii, tawọn eeyan fẹ mọ nipa rẹ
Wo ẹkunrẹrẹ oniruuru isọri ohun tawọn eeyan n wa ati awọn to gba ipo kinni gẹgẹ bi google ṣe gbe e jade:
Awọn eeyan ti wọn n wa nipa wọn ju (Nigeria):
- Joe Biden
- Rema
- Naira Marley
- Rahama Sadau
- Hushpuppi
- Laycon
- Kamala Harris
- Omah Lay
- Maryam Sanda
- Kai Havertz
Nkan gboogi mẹwa tawọn eeyan n wa lọdun yii ni Naijiria lorii Google:
- Coronavirus
- US election
- Joe Biden
- Google Classroom
- ASUU
- Zoom Live
- Rema
- Naira Marley
- Rahama Sadua
- Hushpuppi
Iru ounjẹ, nkan mimu ati ipanu tawọn eeyan n beere ju nipa rẹ ni Naijiria lorii Google:
- Pornstar martini recipe
- Puff puff recipe
- Pancake recipe
- Red velvet cake recipe
- Meat pie recipe
- Chin chin recipe
- Bread recipe
- Chocolate cake recipe
- Oha soup recipe
- Egusi soup recipe
Awọn orin mẹwaa tawọn eeyan tẹ soju opo Google lọdun 2020:
- Davido - Fem
- Simi - Duduke
- XXXTentacion - Bad
- Betty - Butter
- Rema- Ginger me
- Rema - Woman
- Burna Boy - Wonderful
- Patoranking - Abule
- Naira Marley - Tesumole
- Davido ft Nicki Minaj - Holy Ground
Awọn ibeere bii "bawo ni wọn ṣe n ṣe burẹdi jẹ ọkan lara ibeere to wa loke ohun tawọn eeyan n bi Google ju lọdun 2020.
Awọn ibeere ọhun ni:
- Ta ni aarẹ tuntun ni Amẹrika?
- Igba wo ni ileewe n wọle?
- Bi wọn ṣe n ṣe oogun apakokoro "Sanitizer".
- Tani George Floyd?
- Bi wọn ṣe n ṣe aṣọ ibomu.
- Tani Joe Biden?
- Tani Laycon?
- Bi wọn ṣe n ṣe akara oyinbo.
- Tani Aisha Yesufu?
- Bi wọn ṣe n ṣe burẹdi.
- Who be Laycon?
- How to make cake
- Who be Aisha Yesufu?
- How to make bread












