Badirat Ajoke sọ pé òun fínnú-fíndọ̀ fi ààfìn Oyo sílẹ̀ ni, wọ́n kò lé òun

Oríṣun àwòrán, QueenOla2/Instagram
Olori Alaafin ilu Oyo , Badirat Ajoke, ti sọ ni gbangba pe oun ti kuro ni aafin Ọba Lamidi Adeyemi III.
O yan ọrọ naa lasiko to n fi atẹjisẹ dahun oriṣiri'si ibeere ti awọn ololufẹ rẹ n bi i lori ayelujara ibaraẹnidọrẹ Instagram rẹ ni ọjọ Aje.
Igba akọkọ si niyii ti Badirat sọ ni taara pe oun ti kuro ni aafin ilu Ọyọ. O ma n fi owe sọrọ ni lati igba ti iroyin naa ti jade ni bi oṣu diẹ sẹyin.
Nigba ti ẹnikan beere lọwọ rẹ pe ṣe nitori awuyewuye pe oun ati Wasiu Ayinde n fẹ ara wọn, lo ṣe kuro ni aafin, Badirat sọ pe oun ti kuro ni aafin ṣaaju iroyin naa.
- Kí ló mú Olorì Badrat Ajoke kúrò ní ààfin Oyo lọ́jọ́ Iléyá?
- Mo le búra pé kò sí ìbáṣepọ̀ láárin Olorì Badrat àti Wasiu Ayinde - Olori Folashade
- Kí ló wà láàrin Olorì Badra àti Bobrisky, tí ọ̀rọ̀ wọn fi wọ̀?
- Wò ó bí Alaafin àti aya àkọ́fẹ́ rẹ̀, Olorì Abibat ṣe pàdé ní èwe
- Mo ti gbà báyìí pé ohun gbogbo tó n dán kọ́ ni wúrà - Olori Badirat Adeyemi
Tẹ o ba gbagbe, oṣu diẹ sẹyin ni iroyin sọ pe olori naa, ati gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde K1 n fẹ ara wọn.

Oríṣun àwòrán, Instagram/queenola2
Ko si si ẹni to sọrọ taara lori iroyin naa ni gbangba ninu Badirat, K1 ati aafin ilu Ọyọ.
Ibeere mii to tun jọ ti akọkọ yi ni pe ṣe wọn le e kuro ni aafin ni, tabi fun'ra rẹ lo kuro.
Badirat Ajoke sọ pe fun'ra oun ni oun finufindọ kuro ni aafin.
Nigba ti wọn tun bi i pe ẹkọ wo lo mu kuro ni aafin, o ṣalaye pe ẹkọ ti oun kọ kuro ni aafin ni pe "ma ṣe finu tan ẹnikẹni. Awọn ọmọ rẹ ni ọrẹ rẹ timọ-timọ".
Ko tan sibẹ o, Badirat ni oun ko ranti iye olori to wa ni aafin tabi ipo ti oun wa.
Lootọ ni Olori Badirat Ajoke ṣi n wọ oruka si ọwọ, ṣugbọn o dahun ibeere ololufẹ rẹ kan to beere nipa rẹ pe kii ṣe oruka igbeyawo lo wa ni ọws oun.
"Ati pe emi ati Alaafin ko fẹ ara wa ni ilana ofin."
O ni oun ko tun jẹ ni ọkọ nile olorogun mọ, nitori iriri ti oun ni.
Kii ṣe Badirat Ajoke nikan ni olori to kuro ni aafin Oyo.
Ninu oṣu Kẹwaa ni Olori Anu naa fi aafin naa silẹ.
Koda, o fi ẹsun kan Alaafin pe o n lepa ẹmi oun, to si fẹ ẹ ji oun gbe nitori pe oun kuro ninu igbeyawo naa.















