Ghana elections result 2020: Èsì ìdìbò tó gbé aàrẹ tuntun wọlẹ́ ní Ghana rèé...

Wo ibi fún èsì ìdìbò yíyan aàrẹ tuntun ní orílẹ̀-èdè Ghana
Oludije mejila lo n dije dupo aarẹ Ghana tuntun nigba ti eto idibo na maa waye ni ẹkun mẹrindinlogun kaakiri orilẹ-ede Ghana.
O le ni miliọnu mẹtadinlogun eeyan to maa dibo ni Ghana.

- Awakọ̀ agbókùú, ọlọ́pàá, ológun, oníròyìn ló máa ń kọ́kọ́ dìbò ní Ghana, bó ṣe ń lọ rèé
- Ohun tó yẹ kẹ́ẹ mọ nípà olùdíje mèjì tó lágbára nínú ìdìbò Ghana rèé
- Ẹ dín iye ìgbà tẹ n gorí obìnrin kù torí ìdìbò tó n bọ̀, kẹ́ẹ lè lágbára láti ṣe ... - Ọ̀gá àgbà ọlọ́páà
- A kò ní padà sílé ìwé àyàfi t́i ìjọba bá san owó oṣù tó jẹ wá - ASUU
Bawo ni eto idibo naa se ri?
O le ni ibudo idibo ẹgbẹrun mejidinlogoji ti eto idibo naa ti waye ni ẹkun mẹrindinlogun kaakiri orilẹ-ed ghana.
Jean Mensa ni alaga ajọ eleto idibo naa to ṣe kookari eto idibo ọhun ni ọjọ aje , ọjọ keje, oṣu kejila ọdun 2020.
O ni oun maa kede esi idibo naa laarin wakati mẹrinlelogun si asiko idibo ti o ba ṣeeṣẹ.
Lasiko idibo na ni awọn ọlọpaa Ghana mu awọn oṣiṣẹ eleto ididbo meji pe wọn n ṣe magomago ni agbegbe Awutu Senya West ati ni Bawku Central.
Wọn tun fidiẹ mulẹ fun BBC pe awọn eeyan meji fara gbọta ibọn ni agbegbe Awutu Senya East.
Aarẹ Ghana, Nana Akufo-Addo ti ni oju lalakan fi n ṣọri fun gbogbo awọn to n mojuto kika esi idibo naa to n lọ lọwọ.
Duro si oju opo BBC.com/yoruba yii ki o le maa mọ bi wọn ṣe n mu esi naa wa.











