Nigeria-Ghana trade war: Ààrẹ Ghana pàṣẹ kò sáàyè òwò fọ́mọ China tàbí Nàìjíríà mọ́ ní Ghana

Ààrẹ orílẹ̀èdè Ghana Akufo-Add

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ààrẹ Ghana pàṣẹ kò sáàyè òwò fọ́mọ China tàbí Nàìjíríà mọ́ ní Ghana

Aarẹ orilẹ-ede Ghana ti kede pe ko si aṣiwi tabi aṣitumọ ninu itumọ ti ẹgbẹ awọn ọlọja Ghana fun ofin kan eleyi to gbẹsẹ le ifarahan awọn ọlọja lawọn ọja abẹle gbogbo.

O ni titi di igba ti ayipada yoo fi de ba ofin naa, ẹṣẹ nla ni fun awọn ajeji lati maa ta ọja worobo lorilẹede Ghana.

Aarẹ Akufo Ado ni ẹnikẹni ti kii ba n ṣe ọmọ orilẹ-ede Ghana ko gbọdọ ta ohunkohun lọja Wana.

Lasiko ti o fi n ba awọn akọroyin sọrọ ni Aarẹ Akufo-Addo ṣalaye ọrọ yii.

Àkọlé fídíò, Bi ìyàwọ mi ṣe n jábọ́ sí kọ́tà ló jẹ́ kí n kọ́ka fura pé kò ríran mọ́- ọkọ Dorcas

Akufo Addo ni ohun ko fẹ mọ irufẹ ajeji tabi orilẹ-ede ti onitọhun lee ti wa, yala China tabi Naijiria, gbogbo wọn ni ofin orilẹ-ede Ghana ti paṣẹ pe ko gbọdọ ta ọja Ghana.

Bakan naa ni aarẹ Ghana tun fapa janu lori bi orilẹ-ede Naijiria ṣe ti ẹnu ibode rẹ nitori fayawọ irẹsi.

Àkọlé fídíò, Àrà méèrírí lórí òkè táwọn ará ìlú Idanre l'Ondo ń gbé láyé gbọ́ngan sẹ́yìn

O ni ko din ni ọọdunrun ọkọ akẹru latori orilẹ-ede Ghana to fara ko ọwọja ẹnubode ti Naijiria ti naa.

O ni awọn yoo wa ojutu si eto karakata abẹle lorilẹ-ede to bẹẹ ti titi ẹnu ibode ko fi ni nipa awọn eeyan rẹ lara mọ.

Ọrọ ede aiyede laarin awọn ontaja ọmọ orilẹ-ede Naijiria ati akẹgbẹ wọn ni Ghana ti bẹrẹ kaakiri gbogbo ọdun 2019.

Igba marun un ọtọọtọ si ni awọn ontaja ọmọ orilẹ-ede Ghana ti sọ agadangodo si ṣọọbu awọn ọmọ Naijiria to n taja lawọn ọjọ abẹle gbogbo nibẹ.

Ija owo yii si ti fa ọpọlọpọ ikayasoke laarin orilẹ-ede mejeeji.