America blacklisted Nigeria: Amẹ́ríkà fi orukọ Nàìjíríà sínú ìwé 'mágùn' nítorí òmìnira ẹ̀sìn.

Nigeria ati America

Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìgbésẹ̀ tí Amẹ́ríkà fẹ́ gbé lórí Nàìjíríà nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn

Ijọba orilẹede Amẹrika ti fi orukọ Naijiria si inu iwe "mákàn" lori ọrọ ominira ati ṣe ẹsin tk ba wuni.

Atẹjade kan eyi ti minisita f'ọrọ ilẹ okeere l' Amẹrika, Mike Pompeo fi sita lọjọ keje oṣu kejila ọdun 2020.

Atẹjade naa tọka si awọn orilẹede bii Naijiria, to ba Amẹrika dọrẹ, gẹgẹ bi orilẹede to n kọ awọn eeyan lominu labẹ ofin ati ṣe ẹsin to ba wuni lagbaye ti won gbe kalẹ lọdun 1998.

Amọṣa, minisita f'ọrọilẹ okeere l'Amẹrika ko ṣalaye siwaju lori idi ti wọn fi fi orukọ Naijiria nibi ti ẹsin Kristiani ati Musulumi ti gbilẹ sara awọn orilẹede ti ọrọ naa kan.

Nitori awọn orilẹede ti o n tẹ oju ẹtọ ominira ati ṣe ẹsin to ba wuni mọlẹ nikan lofin orilẹede Amẹrika faye gba lati wa ninu iwe akọsilẹ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Kikelomo Ogunboye tan ìmalẹ̀ sí ìwà olè ọ̀gá ọlọ́pàá

Mike Pompeo ni, "loni, Amẹrika ti tọka si Burma, China, Eritrea, Iran, Nigeria, North Korea, Myanmar, Pakistan, Saudi Arabia, Tajikistan, ati Turkmenistan gẹgẹ bi awọn orilẹ-ede to n kọ agbaye lominu labẹ ofin ominira ẹsin lagbaye tọdun 1998 fun titẹ oju ofin ominira ẹsin mọlẹ.

Orilẹede Amẹrika ni ko si orilẹede kan lagbaye" " to gbọdọ lanfani ati maa gbogun ti awọn eeyan rẹ nitori ẹsin ti wọn gba."

Àkọlé fídíò, Promise Akinlade: ọmọ ọdún mọ́kànlá tó ń fi ìlù dárà bíi àgbàlagbà sọ̀rọ̀ nípa tálẹ́ǹtì rẹ

Ohun to yẹ ki o mọ niyi:

*Ṣaaju ninu atẹjade to fi sita ni ibẹrẹ ọdun yii, ileeṣẹ ọrọ okeere l'Amẹrika ti kọminu lori igbesẹ ti ijọba apapọ atijọba ipinlẹ ni Naijiria n gbe lori ọrọ ẹsin.

*O yọju rẹ sita pe iṣekupa ọgọrọ awọn ọmọ ijọ ẹlẹsin Musulumi Shiite to n doju ko ijọba ti ile ẹjọ si fofin de wọn.

*Kaakiri agbaye ni wọn ti bu ẹnu atẹ lu ijọba apapọ fun didoju kọ ijọ ẹsin Musulumi naa, titi kan iṣẹlẹ to waye lọdun 2015 nibi ti ologun ti pa ọpọlọpọ awọn ọmọ ijọ naa.

*Atẹjade naa tun sọrọ lori bi ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS ṣe mu awọn Musulumi kan ni ipinlẹ Kano nitoripe wọn n jẹun ni ita gbangba lasiko Ramadan nigba ti awon musulumi n gbawẹ ati abadofin ti wọn fọwọsi lati tako iwaasu itagbangba nibẹ.

O ṣeese ki orilẹ-ede Amẹrika o gbe igbesẹ to le tako Naijiria atawọn orilẹede wọnyii bi wọn ko ba ṣe atunṣe lasiko.