Ondo 2020 Tribunal: Ìgbìmọ̀ olùgbẹ̀jọ́ ìbò gómìnà yóò gbérasọ lọ́jọ́ Iṣẹgun

Yoruba aworan
Àkọlé àwòrán, APC,PDP, ZLP àtawọn ẹgbẹ́ miran ni Ondo

Igbimọ igbẹjọ idibo Gomina ipinlẹ Ondo ti n palẹmọ lati bẹrẹ ijoko.

Ninu idibo naa to waye ni ọjọ Kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ti Gomina Rotimi Akeredolu ti ẹgbẹ oṣelu APC lo gbegba oroke.

Adajọ Umar Abubakar ni yoo lewaju awọn adajọ meji mii ti yoo gbẹjọ ọhun bẹrẹ lati ọjọ Kẹjọ oṣu Kejila ọdun 2020.

Agboola Ajayi: Igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo tó fẹ́ yẹ àga mọ́ Akeredolu nìdí

Agbẹjọro oludijẹ ẹgbẹ PDP, Eyitayo Jegede tii ṣe Onyechi Ikpeazu lo fiwe pe Gomina Akeredolu ati ẹgbẹ APC fun aṣemaṣe to tako ofin ilẹ yi.

Lara kudiẹkudiẹ to mẹnu ba ni pe Gomina Akeredolu kọ ni ẹgbẹ rẹ dibo yan lati ṣoju wọn ninu idibo Gomina.

Ni ibamu pẹlu ohun tofin ilẹ yi sọ, o ni Gomina ipinlẹ ko le jẹ alaga ẹgbẹ ti yoo yan ẹlomii lati dije dupo.

O salaye pe Gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni lẹni to tako ofin yi nipa pe o di ipo alaga ẹgbẹ APC mu to si tun yan Akeredolu lati dije dupo Gomina.

Yatọ si alaye yi gẹgẹ bi kan lara idi ti ko yẹ ki wọn fi gba iyansipo Akeredolu wọle, Jegede tun ni iwa janduku waye lawọn ijọba ibilẹ kan ati aaye idibo lawọn ibomiran.

Àkọlé fídíò, Promise Akinlade: ọmọ ọdún mọ́kànlá tó ń fi ìlù dárà bíi àgbàlagbà sọ̀rọ̀ nípa tálẹ́ǹtì rẹ