FRSC No Parking: Wo ibi mẹ́rìnlá tí o kò gbọdọ̀ gbé ọkọ̀ rẹ sí lásìkò yìí...

FRSC

Oríṣun àwòrán, @FRSC

Bayii ti ọdun keresimesi ti n kan ilẹkun ti ọpọ si ti n rinrirn ajo kaakiri.

Ajọ eleto aabo ẹṣọ oju popo ti a mọ si Federal Road Safety Commission. ti ṣalaye ni kikun lori awọn nkan to yẹ ki eeyan maa ṣọra fun ki wọn ma baa ṣẹ si ofin oju popo.

Ajọ FRSC ti fi awọn n mojuto aabo awọn awakọ loju opopona Naijiria ni ki awọn eeyan ṣọra fun awọn nkan wọnyii nipa titẹle ofin yii:

- O ko gbọdọ gbe ọkọ rẹ silẹ nibikibi ti wọn ba fi ami: "No Parking" si.

Eyi tumọ si pe wọn ti gbe ami tabi akọle " Ma ṣe gbe ọkọ rẹ silẹ sibi yii".

Diẹ lara awọn ibi ti o ko gbọdọ gbe ọkọ rẹ si boya wọn gbe akọle " No Parking" sii tabi bẹẹkọ niwọnyi-

- Orita tabi iwọn mita mẹwaa to jẹ ẹṣẹ bata mejilelọgbọn.

- Aarin gbungbun kọọrọ tabi ọna to jẹ kọ́nà

- Ori oke tente nibi to ga soke ju ọna to ku lọ nitori pe o ṣeeṣe ki irufẹ ọkọ bẹẹ pada si ẹyin.

- Ori afara to tinrin ti o dabi ẹsẹ o gbèjì fún mọ́tò

Àkọlé fídíò, Ìgbátí ìgbámú àná látọwọ́ sọ́jà obìnrin ti bá arákùnrin náà dé iléèwòsàn

- Opopona irinna reluwe ti ọkọ oju irin maa n gba kọja

- Ibi ti wọn fa ila ami idanimọ " Zebra Crossing" si ni eyi to ṣafihan ila pẹlu awọ ofeefee pe awọn ẹlẹsẹ ero yoo maa gba kọja bọ si odi keji opopona.

- Ẹnu ọna ibudo iṣẹlẹ pajawiri bii ẹnu ọna abawọle ile iwosan, ileeṣẹ awọn ẹṣọ oju popo, ẹnu ọna abawọle agọ ọlọpaa, ileeṣẹ panapana ati bẹẹ bẹẹ lọ.

- Ẹnu ọna abawọle ọja, ile iwe ati ile ti ẹlomii n gbe.

- Ẹnu ọna iloro fun awọn to n fi ẹsẹ rin loju popo.

- Ẹgbẹ osi loju popo ni eyi to le di ọna fun awọn ti wọn n bọ lati odi keji opopona naa.

- Lori afara ati ni awọn opopona abẹ titi abẹlẹ.

- Lopopona Maroṣẹ yatọ si ibi ti wọn ti ay sọtọ lẹgbẹ ẹ titi.

- Ma ṣe gbe ọkọ rẹ si ẹgbẹ ọkọ miran ti wọn ti paaki silẹ ki o ma baa jẹ "Double Parking"

- Nitosi awọn to n tun ọna ṣe.

Àkọlé fídíò, Adebola Ademilua: Àìrísẹ́ ṣè lẹ́yìn ìwé kíkà ló sọ mi dí ìyá onírú, mo dúpẹ́ tèmi