Adeyeye Ile Ife: Kílódé tí Ọọni Ife, Oba Ogunwusi kò fi gbọdọ̀ rí ọmọ rẹ̀ tuntun títí di ẹ̀yìn oṣù mẹ́fà?

Oríṣun àwòrán, @Ooni
Ni kopẹkopẹ yii ni okiki kan kaakiri pe ilu Ile Ifẹ ti ni Arẹmọ tuntun.
Iyẹn nipe, Kabiyesi Ọọni Ile Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi ati aya rẹ, Olori Silẹkunọla Naomi Ogunwusi ti bi ọmọ tuntun.
Ọpọlọpọ lo ti n reti asiko ti Kabiyesi, Ọọni Ogunwusi yoo gbe Arẹmọ rẹ dani ninu fọto fun gbogbo mutumuwa, ki araye fun oju lounjẹ aworan arẹmọ Ọba.
- Ọ̀rá lásán ló wà nínú ọ̀yàn mi tó jò, ẹ̀yin olólùfẹ́ mi, ẹ wá ǹkàn míì wò lára mi - Ronke Oshodi Oke
- Ohun táa mọ̀ nípa àpò àsùwọ̀n owó Sunday Igboho tí ariwo ta pé ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé
- Ǹkan márùn ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa NIN àti BVN
- Àsìkò yìí la gbúdọ̀ pa jíjẹ́ ọ̀ta ara ẹni tì lẹ fi rí mi ní ìpàdé pẹ̀lú APC - Femi Fani Kayode
- Àwọn àgbà wo ló fọ́wọ́ ọlá gbá gbajúgbajà òṣèré Jamiu Afeez lójú tó ń wa ẹkún mu lóríi sinimá tó ṣe?
- 'Ẹ gbé ohùn àdúrà sókè fún mi o! nítorí 'glue' lẹ irun mi pa kò bá ṣí mọ́'
- Mi ò to iṣẹ́ Regina Daniels rárá kí n tó fẹ́ ẹ láàrin ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, mo sì tún le fẹ́ ìyàwó míì - Ned Nwoko
- Àyà mi já nígbà tí Ganduje rọ Sanusi lóyè Emir Kano tó fi Bayero síi, ṣùgbọ́n...- Ooni Ile Ife
- Ilé ìgbọ̀nsẹ̀ kan ṣoṣo ni aṣòfin mẹ́rin ń pín lò! Àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun pariwo sí Gómìnà wọn
- Ohun tó yẹ kẹ́ẹ mọ nípà olùdíje mèjì tó lágbára nínú ìdìbò Ghana rèé
Amọṣa, gẹgẹ bi ọpọ ṣe mọ pe eniyan ọtọ ni awọn Ọba alaye, gbogbo ohun ti tẹrutọmọ ba n ṣe ni gbẹfẹ ni kii rọrun fun awọn ọba lati ṣe; paapaa julọ, Ọọni ile Ifẹ ti iran Yoruba gba gẹgẹ bi Olori aye.
Eyi ko ṣẹyin pe ile Ifẹ ni ojumọ ti kọkọ mọ wa, ibẹ si ni orirun ilẹ Yoruba,
Nitori naa, bi aṣa ati iṣe Yoruba ko ba tilẹ ni itumọ ni ibikibi, o ni lati ni nile Ifẹ to wa ni ipinlẹ Osun ni iwọ oorun guusu Naijiria.
Ṣe eewọ kankan wa to de Ọba lori ọrọ ọmọ tuntun?
Ni ilẹ Yoruba ọpọlọpọ eewọ lo de Ọba alaye.
Fun apẹẹrẹ, Ọba kii ri oku, Ọba kii jẹun ni ita gbangba, ati bee bee lọ.
Ko si idi meji fun awọn eewọ wọnyii ju wi pe oriṣa, ẹni ori ṣa da lawọn Ọba alaye jẹ gege bi igbagbọ ilẹ Yoruba.
Nitori naa, ipo ọwọ ni wọn wa, wọn ko le e ṣa deede kan huwa ohun to wu wọn ni ṣiṣe, paapaa bi ifa ko ba fọwọ sii.

Oríṣun àwòrán, @Ooni
Ki wa lode ti Ooni Ogunwusi ko fi le ri ọmọ rẹ tuntun lasiko yii?
Eyi ni ibeere ti BBC Yoruba jade lọ ṣe iwadii rẹ.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Agẹṣin Adimula ti ilu Ila Ọrangun, Oloye Fagbenle Adedayọ to tun jẹ alukoro fun ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe ni ipinlẹ Ọsun sọrọ ilẹ kun.
O ṣalaye pe inu ifa ni ipilẹ Ọba jijẹ ati isesi awọn ọba alaye ti jade wa ninu.
Agẹsin Adimula ni Ifa eyi naa lo si ka ọpọlọpọ eewọ fun wọn gẹgẹ bi iṣẹṣe eyi ti wọn ko gbọdọ tapa si bi o ti wu ki aye di aye ọlaju to.
Oloye Adedayọ ti oun pẹlu jẹ ọkan lara awọn Afọbajẹ ilu Ila, to jẹ ọkan lara awọn ilu iṣẹmbaye nilẹ Yoruba fi idi rẹ mulẹ pe lara awọn eewọ ti Ọbalaye ni ilẹ Yoruba patapata ko gbọdọ ṣe ni riri ọmọ tuntun wa.
Ki wa ni igbesẹ ti Ọba fi le ri ọmọ tuntun nilẹ Yoruba?
Agẹṣin Adimula tilu Ila Ọrangun ni bi wọn ba bi ọmọ lori oye, akọkọ ni pe kii ṣe bi gbogbo eeyan yooku yoo ṣe ri ọmọ tuntun naa ni Kabiyesi tabi awọn Afọbajẹ yoo ṣe rii.
Sebi, idalu kuku ni iṣelu. ati pe eewọ yii naa ta ba awọn afọbajẹ pẹlu.

Oríṣun àwòrán, @Ooni
Agba oye ninu iṣẹṣe naa ni ohun akọkọ ni pe Ọba kii ri irun ọrun ori ọmọ tuntun nitori naa wọn gbọdọ kọkọ rii pe wọn fa irun ori ọmọ bẹẹ ki o to lee fi oju kan an.
Idi niyi ti Ọba ko fi gbọdọ si nibẹ nigba ti wọn ba fe gbẹbi ọmọ bẹẹ.
Bi ọpọlọpọ awọn lọkọ laya ode oni ṣe n ṣe, leyi ti ọkọ le e wọ inu iyara igbẹbi pẹlu iyawo rẹ lasiko ibimọ kii ṣe ti Ọba alaye nilẹ Yoruba.
Bawo ni igbẹbi Arẹmọ Ọọni Ile Ifẹ ṣe wa ṣẹlẹ?
Fun ọpọ ti ko mọ, aafin Ile Ifẹ kọ ni wọn bi Arẹmọ tuntun yii si.
Ilu Ọwọ ni ileewosan nla ti ijọba apapọ, FMC to wa nibẹ ni Olori Naomi Silekunola ti lọ bimọ rẹ si.
Ọpọ onwoye lo si n wo pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ni ibamu pẹlu ati pa eewọ yi mọ ni Yeyeluwa ilẹ Yoruba, iyẹn Olori Naomi ṣe fi aafin silẹ lọ ilu Ọwọ ṣaaju ibimọ rẹ.
Idi keji fun eewọ yii ni pe kii ṣe gbogbo igba ni wọn n gbe ọmọ ikoko lọ ki Ọba nitori kabiyesi ti le e wa ni ẹgun pẹlu awọn Onnilẹ.
Iyẹn ni pe, Kabiesi wa pẹlu awọn baba nla rẹ to si jẹ pe nnkan to ba foju ba le e ni apẹrẹ paapaa julọ to ba jẹ ikoko.

Oríṣun àwòrán, @Ooni
Kini Ọba to ba fẹ tete fi oju kan ọmọ rẹ le ṣe?
Bayii ni n o ṣe nakn mii, kuku yatọ si bayii ni a o ṣe nkan wa.
Oloye Adedayọ salaye pe bi o ba jẹ lawọn ilu kan ni; ti wọn ba fẹ ki kabiyesi tete fi oju kan ọmọ rẹ, wọn lee fa irun ọrun rẹ ni ọjọ keji.
Ṣugbọn sibẹ, irufẹ Ọba bẹẹ ko lee fọwọ kan ọmọ naa.
Yoo kan sure fun ikoko naa ni lati okeere ni.
O digba ti wọn ba ṣe idata rẹ ni ọjọ kẹta ti wọn bii ati ẹsẹntaye rẹ ni ọjọ keje to ba jẹ obinrin tabi ọjọ kẹsan an to ba jẹ ọkunrin.
Bawo ni awọn eewọ wọnyii ṣe kan Ọọni Ile ifẹ ati Arẹmọ rẹ?
Akọkọ naa, Ọba ilẹ Yoruba ni Ọọni Ile ifẹ,
Koda, kii ṣe Ọba lasan, olori ọba alaye nilẹ Yoruba ati lagbaye ni nitori naa ọdọ rẹ gan an ni orisun gbogbo awọn eewọ wọnyii ati bibọwọ fun wọn ti ṣẹ wa.
Agẹṣin Adimula ni nitori pe kii ṣe ori gbogbo ọmọ lo maa n tete gbo ti wọn yo fi lee tete fa.
Igba ti wọn ba si to o fa ori ikoko ni Ọọni yoo si tun lee rii.
Eleyii lee maa tete ya fun awọn idi kan tabi omiran.
Wo awọn idi pataki yii:
Akọkọ ni pe, nitori ibọwọ fun aṣa ati iṣe Yoruba ni, yoo ni iru abẹ ti wọn yoo lo, kii kan ṣe abẹ kan ṣa ni wọn yoo fi fa irun ori Arẹmọ tuntun.
Ekeji ni pe, nitori pe o jẹ ọmọ Ọba, o ni iru awọn eeyan to le e wa nibi ifari rẹ.
Pẹlu bi o ṣe ti jẹ pe kii ṣe afin, koda kii ṣe ilu Ile Ife ni wọn bi Arẹmo si yii, o ṣeeṣe ki gbogbo eyi ko gba akoko diẹ sii.
"Gbogbo awọn nnkan kan wa ti a o kọkọ gbewo to jẹ bi ami ororo ti wọn o ti yan, ti wọn o si ti mọ iru eeyan ti ọmọ yii maa jẹ.
Ẹ wo baba wa Ogunwusi yii, lati kekere ni wọn ti sọ fun awọn naa pe wọn yoo jọba.
A ko mọ iru iṣẹṣe ti wọn ti ṣe fun awọn naa nigba yẹn".
Oloye Agẹṣin Adimula u Ila Ọrangun tun fi kun un pe gẹgẹ bi o ṣe jẹ Ile ifẹ ni aṣa yoo gbilẹ bi o ti yẹ nibẹ gẹgẹ bi awokọṣe fun gbogbo ilẹkilẹ.
O ni ki wọn to lee fa irun ọmọ miran, "o le e pe oṣu mẹta, o le jẹ oṣu mẹfa, o le e pe osu meje.
Sugbọn o di bi dandan ki wọn ba ṣe e lọna ti o tọna nitori lọpọlọpọ igba Ifa gan an le e ni ki wọn ma tete fi abẹ kan ọmọ miran lori.
Iru ọmọ bẹẹ yoo lo ọjọ diẹ ko to lee ri baba rẹ".
Pẹlu gbogbo ọrọ alaye yii, ohun to daju nipe o digba ti Ifa ba to paṣẹ pe ki wọn ṣe bẹẹ fun ọmọ Ọọni tuntun ki o to lee ri bẹẹ.
- Mílíọ́nù mẹ́wàá Náírà ni ilé ẹjọ́ ni kí Kábíyèsí san gẹ́gẹ́ bí owó ìtaran ilẹ̀ tí ó gbà lọ́nà àìtọ́
- Ìjọba Naijiria faraya nínú lẹ́tà tó kọ sí CNN lórí ìwádìí rẹ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Toll Gate
- Omotara pàdánù isẹ́ olówó ńlá nítorí ó fi ọtí ẹlẹ́rìndòdò sódà lá ọmọ alágbe lójú
- Wo bí o ṣe lè ṣe eré ìdárayá tí yóò fún ọ ní adùn àti okun fún ìbálòpọ̀
- Ilé aṣòfin orílẹ̀-èdè UK n gbèrò fífí ìyà jẹ àwọn adarí Naijiria tọ lọ́wọ́ nínú rògbòdìyàn ENDSARS
























