Ooni Adeyeye Ogunwusi: Fani-Kayode ní ìwà àbùkù Tinubu yìí ta bá gbogbo ọmọ Oodua

Oríṣun àwòrán, Others
Awuyewuye to n waye lori ikinni laarin Ọọni tilu Ile Ifẹ, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi ati asaaju ẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, si n tẹsiwaju lori ayelujara.
Nibayii, minisita tẹlẹ feto irinna, Femi Fani-Kayode naa ti da si isẹlẹ yii loju opo Twitter rẹ l'Ọjọru.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn rèé nípa bí Ogbomoso ṣe pa ọba, yọ nǹkan ọkùnrin rẹ jó kiri ìlú
- Háà ilẹ̀ wẹ! ọ̀dọ́ 47,000 fẹ́ di Amotekun, agbófinró yẹ̀ wọ́n wò yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́
- Aáwọ̀ oyè PDP gbé Fayose àti Seyi Makinde kọlu ara wọn, ìjà ń bọ̀
- Ènìyàn mẹ́ta pàdánù ẹ̀mí wọ́n lọ́wọ́ àrùn Coronavirus ní Nàìjíríà ní Ọjọ́ọ̀rú
- Bí nǹkan ọkùnrin bá há sójú ara obìnrin, kìí ṣe Mágùn, ẹ má páyà
- Bàbálọ́jà márùn ún la ó ò ní l'Oyo tí Makinde bá lè buwọ́lu ìyànsípò YK Abass
- Ìjọba, e yé dẹ́yẹ sí wa mọ́, àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ṣèwọ́de n'Ibadan
- Auxiliary gbé èèyàn mẹ́fà tó ń jáwèé ayédèrú fáwọn awakọ̀ lọ sí ilèẹjọ́ ní Ibadan
Nigba to n sọrọ lori bi Tinubu se joko, nigba ti Ọọni n ki lori iduro, Fani-Kayode ni ọrọ sunnukun ni ọrọ naa, o si yẹ ka fi oju sunnukun wo o.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Fani-Kayode ni "Isẹlẹ naa safihan iwa abuku ati ọyaju si ni nikan fawọn ọmọ bibi ilu Ile Ife, amọ iwa naa tabuku gbogbo ọmọ ilẹ Yoruba lọkunrin ati lobinrin."
Minisita tẹlẹ naa fikun pe, ojuti nla gbaa ni ihuwasi ọhun, eyii to yẹ ko pa ni lẹkun.

Oríṣun àwòrán, Others
Fani-Kayode wa n beere pe se asaaju oloselu lẹkun ariwa Naijiria lee kọ lati dide ki ọba alaye nibẹ?
Afenifere fara ya lórí bí Tinubu ṣe jókòó kí Ooni

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹgbẹ ọmọ Yoruba lorilẹede Naijiria, Afẹnifẹre ti bu ẹnu atẹ lu ihuwasi adari ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu pẹlu bi ko ṣe dide lati ki Ooni ti Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi, lasiko ti wọn n fi Ọba oniru ti Iru, Oba Omogbolahan Lawal jẹ ni Eko.
Odumakin sọrọ yii lẹyin ti aworan bi Tinubu ṣe joko, nigba ti Ooni dide lati ki i, gba oju ẹrọ ayelujara kan.
O ni bi o tilẹ jẹ pe awọn ọba ilẹ Yoruba ko ni agbara bi oloṣelu mọ, ohun to yẹ ni lati bọwọ fun awọn ori ade nipa titẹriba lati ki ọba.
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afẹnifẹre naa sapejuwe bi Aarẹ orilẹede Naijiria nigbakan ri, Oluṣegun Ọbasanjọ ṣe dọbalẹ lati ki Ọọni lọdun 2016 bii bibu ọwọ nla fun ori ade naa.
'' Ọmọ Yoruba ni wa, a si gbọdọ bu ọla fun ẹni ti ọla yẹ, paapaa awọn ọba alade nilẹ Yoruba, a kọ gbọdọ sọ wi pe nitori ọlaju, ki Tinubu wa joko, nigba ti Ọọni dide lati ki i.
Ohun to mu aarẹ nigba kan ri dọbalẹ gbalaja lati ki Ọọni ti Ifẹ, a gbọdọ bọwọ fun asa ati iṣe ilẹ Yoruba,"













