Ayodele Fayose and Seyi Makinde: Màá fidán han Seyi Makinde, tó bá yọjú sí Ekiti

Ayodele Fayose ati Seyi Makinde
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

O ti n rugbo bọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, to si dabi pe wọn ti n bẹnu fun ara wọn.

Idi ni pe gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose ti fa aala sibi ti gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde gbọdọ rin de, paapaa nipinlẹ Ekiti.

Fayose, lasiko to se abẹwo pẹlu awọn alaga ẹgbẹ PDP nipinlẹ Osun, Ekiti ati Eko lọ silu Abeokuta lọjọru, lo fewe ọmọ mọ Makinde leti bẹẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fayose ni ibi ti wọn ba fi Ẹlẹmọsọ gomina Makinde sọ, ni ko yaa sọ, oun ko si gbọdọ ri ẹsẹ rẹ nipinlẹ toun, tii se Ekiti.

O ni Makinde jẹ asaaju ẹgbẹ PDP lẹkun yii nitori ipo to wa bii gomina kansoso tẹgbẹ oselu PDP ni lẹkun iwọ oorun guusu ni.

Asia idamọ ẹgbẹ oselu PDP

Oríṣun àwòrán, @PDPng

O fikun pe gomina ipinlẹ Oyo naa ko gbọdọ wa tọwọ bọ ilana ipo asaaju to wa ninu ẹgbẹ oselu PDP lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria.

Bakan naa ni gomina ana nipinlẹ Ekiti naa ni Makinde gbọdọ gba awọn asaaju ẹgbẹ PDP lawujọ kọọkan laaye lati maa sejọba lọ nipinlẹ koowa wọn.

"Aawọ abẹnu wa lori ẹni ti yoo di ipo asaaju kọọkan mu lẹkun yii, ti Makinde si ni ki wọn yẹju awọn alasẹ ẹgbẹ lẹkun yii, kawọn igbimọ afunsọ si gba ipo wọn, eyi ti ẹgbẹ oselu naa tẹle."

Àkọlé fídíò, Mayowa Omoniyi: Kò sí orin Obey, Sunny Ade abí tàkasúfèé tí ń kò le ta gìtá sí

Fayose fikun pe "tori Makinde wa nipo gomina loniii ko fun ni asẹ lati maa lọ sipinlẹ miran, to ba sipinlẹ temi, maa koju rẹ, maa bọwọ fun tori arakunrin mi ni, mo nifẹ rẹ pupọ, mo si mọ si bo se di gomina."

Awọn afurasi darandaran pa agbẹ l'Ekiti

Darandaran fulani kan duro pẹlu agbo ẹran rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Gulegule awọn darndaran fulani ti da oniruuru ipaya silẹ kaakiri orilẹede Naijiria

Awọn daradaran kan ti wọn funrasi gẹgẹbi fulani ti pa rakunrin ọmọ ọdun mejilelọgbọn kan ti orukọ rẹ n jẹ Tunde Ọlayẹmi ni ilu Ipao Ekiti ni ipinlẹ Ekiti.

Ni ọsan ọjọ aiku ni wọn pa arakunrin naa lasiko to n pada bọ lati oko rẹ.

Ọmọ meji ni oloogbe Ọlayẹmi bi, oun pẹlu ẹnikan ni wọn lọ si oko ẹgẹ to gbin si igbo ọba to wa nilu naa.

Gẹgẹbi iroyin se sọ, bi wọn se n bọ silẹ lori okada lawon darandaran fulani naa sa dede yọ si wọn pẹlu ibọn.

Gomina Fayose ti ipinlẹ Ekiti duro pẹlu awọn ọdẹ ni ilu Ado Ekiti

Oríṣun àwòrán, @GovAyoFayose

Àkọlé àwòrán, Ni ibẹrẹ ọdun 2018 ni Gomina Fayose ti ipinlẹ Ekiti se ipade pẹlu awọn ọdẹ ni ilu Ado Ekiti

Bi wọn si ti se n salọ lawọn fulani naa mu Tunde, ti wọn si sa a yannayanna.

Ohun ti gomina ipinlẹ Ekiti sọ lori isẹlẹ naa

Ninu ọrọ rẹ, gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayose ni ọwọ yoo ba eniyan yoo wu to pa rakunrin Ọlayẹmi, yoo si fi oju wina ofin.

Gomina Fayose ke si ijọba apapọ lati ji giri si ọrọ abo ẹmi ati dukia paapaa julọ 'lọwọ awọn ọdaran to n pe arawọn ni darandaran ti wọn ti wa sọ ara wọn di adukulajamọni .

"Labẹ isejọba mi ni ipinlẹ yii, ko si ẹnikẹni ti yoo pa eniyan ti yoo si lọ bẹẹ lai foju ba ofin. Gbogbo awọn to pa Ọlayẹmi Tunde ni Ipao Ekiti lana, yala wọn jẹ darandaran tabi ohun yoo wu ti wọn lee jẹ, ọwọ ofin yoo tẹ wọn wọn o si jiya to tọ niwaju ofin. Mo ba idile rẹ kẹdun."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ohun ti ileesẹ ọlọpa sọ?

Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ lori ọrọ naa, alukoro ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Ekiti DSP Adeyẹmi Albert Ademọla ni ileesẹ ọlọpa ko tii lee fi idi rẹ mulẹ boya daranadaran fulani lo se isẹ ibi naa.

O ni awọn ọlọpa ti bẹrẹ iwadi lori isẹlẹ naa.

Awọn ọdẹ pẹlu ibọn n gba ọna oko lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ọdẹ ti bẹrẹ igbesẹ ati gbogun ti awọn darandaran Fulani nipinlẹ.

"Lootọ ni wọn pa eeyan kan ni ilu Ipao Ekiti sugbọn ileesẹ ọlọpa si n se iwadi lati mọ boya darandaran fulani lo sisẹ naa tabi awọn kọ. Nitori orisirisi isẹlẹ lo ti n sẹlẹ lẹnu ọjọ mẹta yii to n fẹ awofin daadaa."

Awọn ọdẹ ilu Ipao Ekiti ti fariga.

Nigba to n sọrọ, olori awọn ọdẹ ni ilu naa, ọgbẹni Adebayọ Ọdẹyẹmi salaye wipe awọn ọlọdẹ ti bẹrẹ igbesẹ ati gbogun ti awọn darandaran Fulani lagbegbe naa.

"Awa o kọlu darandaran kankan lagbegbe yii sugbọn wọn ti pa eeyan kan laarin ileto wa, a si maa rii daju pe wọn o da irufẹ asọ bẹẹ soro mọ.

Akinkanju ni wa, a kii se ojo. Nitorinaa, ohun to ba gba laa fun lati daabo bo ileto wa, awọn oko wa. Wọn ti pa ọkan ninu wa, iru rẹ ko si ni sẹlẹ mọ."

Saaju asiko yii ni ibẹẹrẹ ọdun 2018 ni gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayose ti gbe isẹ le awọn ọlọdẹ lọwọ lati daabo bo ileto koowa wọn lọwọ gulegule ikọlu awọn darandaran fulani ni ipinlẹ̀ naa.