BVN With NIN: Ǹkan márùn ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa NIN àti BVN

Oríṣun àwòrán, NIMC
Lẹ́yìn ìkéde ìjọba pé, ó ṣeeṣe kí ìjọba fi NIN rọ́pò BVN ní Nàìjíríà ni ọ̀pọ̀ tí n sọ oníruurú ǹkan tó yẹ kí ìjọba ṣe tàbí tí kò yẹ kí ìjọba ṣe.
Àlàyé díẹ̀ rèé lórí ǹka tí ó yẹ láti mọ̀ nípa NIN àti BVN:
Ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípà NIN
Láti inú oṣù kíní ọdún 2019 ló ti di dandan fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀, ilé iṣẹ́ àti àjọ láti ni nọmbà ìdánimọ kí wọ́n tó le gba ohunkóhun.
1. Ìdí tí ìjọba fí n ṣe èyí ni láti ríi dájú pé, gbogbo ǹkan tó niṣe pẹ̀lú ẹnikọ̀ọ̀kan ni Naìjíríà dí mímọ̀ fún ìjọba àti àrá ilú láti ni ojú kan soso tí ìjọba paa mọ́ sí. Bí àpẹrtí wọ́n bá dárúkọ pé ó hùwà ọdaran, inú akoto yìí ni wọ́n yóò lọ wò láti gbé gbogbo ǹkan tokù jáde nípà rẹ̀.
- Ọ̀rá lásán ló wà nínú ọ̀yàn mi tó jò, ẹ̀yin olólùfẹ́ mi, ẹ wá ǹkàn míì wò lára mi - Ronke Oshodi Oke
- 'Ẹ gbé ohùn àdúrà sókè fún mi o! nítorí 'glue' lẹ irun mi pa kò bá ṣí mọ́'
- Ọlọ́pàá dá ọkùnrin méjì tó ń ní ìbálòpọ̀ ọkùnrin sọ́kùnrin padà sí ìlú abínibí wọn
- À ṣé ara mi ni isó tí ń rùn, tí èmi náà ń ṣépè fún ẹni tí Jamiu Azeez ń sọ - Mama Ereko
2. Gbogbo ọmọ Nàìjíríà tó n gbé ní Nàìjíríà ló le gba nọ́mbà NIN, sùgbọ́n ọmọ ọdún mẹrìndílógún ló to le gba káàdì NIN, Bákan náà ni gbogbo ènìyàn tó tí n gbé Nàìjíríà fún ọdún méjì náà le gba Káàdì ìdánìmọ̀ NIN.
3. Tí ènìyàn bá ni NIN, yóò ni ànfàni láti lé sé àwọn ǹkan wọ̀nyí:
(a) Forúkọsílẹ̀ fún gbígba ìwé ìrìnà (International Passport)
(b) Ṣíṣí àpò ìkówópamọ́ ni bánkì fún àra ẹni
(d) Ìforúkọsílẹ̀ fún káàdì ìdìbò
(e) Rírà, fífún ni tàbí fíforúkọ ilẹ̀ silẹ lọ́dọ̀ ìjọba
(ẹ) Ìṣẹ ilé itúra, lílo ètò ìléra tàbi gbígbà ìtọ́jú
(g) Sísan owó orí
(gb) Rírà tàbí fífi orúkọ mọtọ̀, bàálù, tabi ọkọ̀ ojú omi sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjóba
(h) Títà, rírà tàbi pínpín àwọn ǹkan to níṣe pẹ̀lú owó bánkì
(i) Lílọ ọkọ òfurfú, yálà ilé iṣk tàbi ọlọ́dani.
(j) Fífi orúkọsilẹ̀ ni ilé ẹ̀kọ́ tàbi níle iwe gíga àti àwọn ẹgbẹ́ àkọ́ṣkmọṣẹ́.
(k) Iforúkọsílẹ̀ ilé iṣẹ́ ni ọ̀dọ̀ àwọn CAC
(l) Gbígba iṣẹ́
(m) Gbígbé ènìyàn lọ silé ẹjọ́ tàbí gbígbé iké iṣẹ́ lọ sílé ẹjọ́.
(n) Gbígbẹ ọjà wọlé láti ilẹ̀ òkèrè tàbi gbígbé ọjà lọ́ sítà
(o) Gbígba kọ́gila lọ́wọ́ ọlọ́dani àti ìjọba
(ọ) Gbígba ìwé àṣẹ̀ ìrìnà ọkọ̀.
4. Ẹnikẹ́ni tó bá kùnà láti ṣe àwọn ǹkan wọ̀nyiì'yóò mú ìjìyà oníruuru lọ́wọ́ tó fi mọ owó ìtàran mílíọ̀nù kan náírà nítorí pé ó ní àtìlẹ́yìn òfin Nàìjíríà.
5. Àwọ tí ọ̀rọ̀ náà kan ní ilé iṣẹ́ ìjọba, àjọ àtí ọlọ́dani, gbogbo ǹkan ini olúkúlùkù.
Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ BVN, wọ́n ti n lo NIN nilé ifowópamọ, èyí sì wà lára ìdí tí ìjọba ṣe n gbèrò láti máa lòó láti rọ́pò BVN.
Ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa BVN

Oríṣun àwòrán, CBN
Inú oṣù keji ọdún 2015 ni lílò BVN pọndandan fún gbogbo ẹni to bá ni ǹkan ṣe pllú ilé ìfówópamọ́., BVN náà ni àwọn nọ́mbà mọ́kànlá tó dàbi ǹkan ìdánimọ̀ fún gbogbo ilé ìfowópamọ́ t;i o bá lówó sí.
Ilé ìfdowópamọ́ àpàọ̀ Nàìjíríà CBN ló gbé ètò yìí kalẹ̀ láti ri dájú pé ààbò wà fún óladani àti ilé iṣẹ́, ẹnikẹ́ni ti kò bá sì ti ní nọ́mbà náà túmọ̀ si pé kò ni ni àṣẹ sí owó rẹ̀ tó bá wà nílé ìfowópamọ́ tàbi kí o máa kó owó rẹ̀ sínú ilé.
1. Inú oṣù kéji ọdún 2015 ni Nàìjíríà pọ́n ni dàndan fún gbogbo ẹni to bá n kọówó pamọ́ sílé ìfówópamọ́.
2. O kò le gba káàdì BVN sọ́wọ́ bi ti NIN, ó kan ti wà ni àkọsílẹ̀ ní Bánkì rẹ̀ pé nambà ìdánimọ̀ rẹ̀ ni ni gbogbo bánkì tí ó bá lówó sí.
3. Ǹkan tó niṣe pẹ̀lú owó ní BVN wà fún yàtọ si tí nọ́mbà ìdánimọ̀ NIN nítori náà kò sí bi o ṣe dàgbà tó, bi ó bá ni àpò owó ni Banki o kò le ni BVN
4. Kò sí bi ẹnikẹni ṣe le ri BVN gbà lóri ayélujára, ó pọndandan kí o lọ silé ifówópamọ́ láti ṣe gbogbo ǹkan ti ó yẹ .
%. BVN mú àdínkù bá ìwà àjẹbánu àti gbígbé owó ìlú lọsilẹ̀ òkèrè tàbí kíkó owó ìlú pamọ́ lábl orúkọ míràn.
Ìdí tí ìjọba yóò ṣe fí NIN rópò BVN ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, NIMC
Mínísítà fún ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti ètò ọrọ̀ ajé ìgbàlódé, Isa Pantami ti fi léde lánàá pé ó ṣeeṣe kí ìjọba fí Nọ́mbà ìdánimọ̀ tuntun (NIN) rọ́pò Nọ́mbà tó so àpò ìkówópamọ́ bánkì pọ̀ (BVN).
Ọdún 2014 ni ilé ìfówópamọ́ Nàìjíríà (CBN) paa láṣẹ́ pé kí àwọn ènìyàn máa gba nọ́mbà náà láti dáàbò bo owó wan ni báǹkì.
Ìdí tí ìjọba ṣe fẹ́ ṣe àyípadà yìí
Lásìkò tó n sọ̀rọ̀ ni Abuja ni mínísítà ló ti sàlàyé pé, ìdí pàtàkì tí èyí fi wáyé ni pé, NIN nìkan ó jẹ́ ojúlówó nọ́mbà àkọ́ka tó sì ní àtìlẹ́yìn nínú òfin Naìjíríà.
Ó ní nítorí ìdí èyí ní ó ṣe ṣe pàtàkì kí ìrú nọ́mbà bẹ́ẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀ lásìkò ìforúkọ̀ sílẹ̀ ní báńkì nítorí kò sí àtilẹ̀yìn òfin kankan fún BVN nínú òfin Naìjíríà.
Pantami ni ó tẹ́ ààré Buhari lọ́rùn bí ètò ifórúkọsílẹ̀ NIN ṣe ń lọ lọ́wọ́ ni Naìjírí, bótilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìpèníjà tó wà níbẹ̀ jú ti àìkò ìforúkọsílẹ̀ fún BVN lọ.
Ìlànà àti ṣíṣe bánkì ni BVN, bánkì nìkàn sì ló wà fún, sùgbọ́n NIN nìkàn ní nọ́mbà tó pọndandan gẹ́gẹ́bi nọ́mbà ìdánimọ̀ fùn ará ìlú ti ìjọba mọ, gbogbo àwọn àmì ìdánimọ̀ tókù kò wúlò fún ìjọba.
Kíni àwọn ọmọ Nàjíríà ń sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí?
Ọ̀rọ̀ ṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ìpìnù ìjọba yìí lójú òpo' twitter, bí àwọn péréte ṣe gbà pé ìgbésẹ̀ yìí wuyì púpọ̀ ní àwọn míràn ṣe ń sọ pé ìjọba fẹ́ràn láti máa ni ará ìlú lára.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Gẹ́gẹ́ bi Muyiwa Olagunju ṣe sọ, kò yẹ kí ìjọba máa lo ètò NIN tó ti kùnà láti ọjọ́ pípẹ́ maa da ọ̀rọ̀ BVN to ti ṣe aṣeyọri rú. O fi kun pé ṣebi CBN ni àti àwọn ilé ifówópamọ́ tó kù ni àwọn dátà ti wọn nílò, kílode ti ìjọba kò fikùnlùkù pẹ̀lú wọ́n.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Tun_Ibitoye ní tirẹ̀ ni kò sí ǹkan tó rọrùn ní orílẹ̀-èdè yìí, kíni ìjọba ń rò tẹ́lẹ̀ kó tó di àsìkò yìí, mó dẹbi ru, ìjọba mó sì dẹ̀bi ru ara mi pé mo yà sí Nàìjíría."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Abiodun Popoola ní tirẹ̀ ni Báwo ni ìjọba yóò se máa fi BVN rópò NIN, wọ́n gbégile CryptoCurrency wọn tun gbégilé àwọn bánkì orí ayélujájara, wọ́n.
Ó fí kun un pé ìjọba yìi'bákan náà ló n rọkun sápa àwọn ọdàran ajínígbé, tó sì n dáabò bo àwọn Fulani darandaran, "Se ọrọ iṣélu yé àwọn wọ̀nyí báyìí?



















