Ondo Monarch and Regent: Ìlànà yìí ni wọ́n gbúdọ̀ tẹ̀lé kí wọ́n tó lè yan adelé obìnrin

Ọba Joseph

Ninu ilu kan ni ipinlẹ Ondo lapaa Guusu - Iwọ Oorun Naijiria to n jẹ Isikan ni Akure, Ọba Joseph Olu Ojo ṣẹṣẹ waja laipẹ ni.

Oun ni Ọba ikẹtadinlogoji.Ṣaaju rẹ, Ọba mẹrindinlogoji lo ti jẹ,

Lara aṣa ati iṣe ilu Isikan ni lati ṣe awọn ohun kọọkan kete ti Ọba kan ba ti waja titi di asiko isinku ati asiko yiyan adele obinrin sori itẹ.

Ifinijoye
Ọba Joseph

Ọjọ kẹta oṣu keje ọdun 1978 ni "Iralepo ti ilu Isikan", Ọba Joseph gori itẹ.

Lọdun 1977 ni wọn dibo yan an ti wọn si gbe e lọ si ojubọ fun gbogbo eto to tọ lati sọ ọ di Ọba ni nkan bii ọdun mẹtalelogoji sẹyin.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ to si farahan ninu awọn aworan to wa ninu iroyin yii eyi ti idile Ọba to ṣẹṣẹ waja fi ṣọwọ si wa, wọn kii sin Ọba ilu Isinkan loju ẹsẹ.

O ni iye ọjọ ti wọn gbudọ fi gbe oku Ọba joko sori itẹ rẹ ki wọn to lọ sin in.

Àkọlé fídíò, '500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'

Ki ni itan sọ nipa awọn Iralepo to ti jẹ niluu Isikan?

Ifinijoye

Ilu Isikan ninu itan gẹgẹ bi awọn olukọtan ṣe kọ ọ jẹ ilu nla tẹlẹ nigba aye rẹ ko to di pe ogun ko ilu naa to si sọ awọn ara ilu naa di alairilegbe.

Gẹgẹ bi awọn ilu ilẹ kaarọ o jiire kan ṣe tọpasẹ ibẹrẹpẹpẹ wọn lọ si Ile Ife, bẹẹ naa ni ilu Isikan ṣe jẹ ọmọ ọmọ si Oduduwa, Okanbi to bi Oluroko.

Ilana bi wọn ṣe maa n jẹ Iralepo tuntun

Ọjọ mẹsan gbako ni wọn yoo fi ṣe ayẹyẹ iyasọtọ. Iralepo yoo gun ori oke Okitiomoloore ni ilu naa ko to wọ inu afin rara. Inu igbo irumọlẹ Igboye ni wọn ti maa n ṣe ifinijoye Iralepo ti ilu Isikan.

Idi ti Ọba ilu Isikan ko fi si lara awọn ilumọọka Ọba nla nla to maa n gba itẹsiwaju lẹnu iṣẹ latọdọ ijọba bii ti awọn ilu nla mii ni Ọba Joseph Olu Ojo sọ nigba aye rẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pe ki oun to jọba lọdun 1978, ajọ kan wa ti wọn gbe kalẹ fun amojuto eyi to n jẹ Morgan Commission.

Amọ o ni ko si Iralepo ati Osolo nibẹ nigba naa tori wọn ko ni aṣoju nibẹ. Bayii ni awọn olori ilu kan ṣe di Oriade fun ilu wọn.

Asiko yii ti Iralepo to ṣẹṣẹ waja n s jẹ asiko ti ori aga oye ṣofo bo tilẹ jẹ pe adele wa nigba naa. O ni idile oye ko ba ti ṣe ara wọn ni ore nipa riran aṣoju lọ sibẹ.

Ẹwẹ lọdun yii ti Ọba Joseph waja, adele obinrin to jẹ lẹyin ti baba ti Ọba Joseph ku to ṣi wa lọjọ ogbo rẹ laye lo tọ awọn ọmọ atawọn oloye sọna lori ilana ti wọn gbudọ tẹle bi Ọba ba waja ti kan lara rẹ jẹ pe wọn gbudọ gbe oku rẹ joko sori itẹ.