Ifayemi Elebuibon: Mo jẹ páànù ìyà nítori mo fẹ́ mọ̀ọ́kọ, mọ̀ọ́kà

Oloye Elebuibon

Awọn agba bọ, wọn ni ọmọ ti yoo ba jẹ Aṣamu, ati kekere ni iru wọn ti maa n ṣẹnu ṣamu ṣamu.

Bayii lọrọ ri pẹlu ilumọọka oniṣegun ibilẹ to tun jẹ agba babalawo, Araba ilu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon.

Elebuibon sọ fawọn akọroyin pe, lati ọmọ ọdun mẹrin ni oun ti n fi ọfọ se iwosan fawọn ọrẹ oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Iṣẹ Ifa ni baba mi n ṣe, oun lo si n kọ mi nipa Ifa ati iṣẹṣe, ọjọ kan tiẹ wa ti mo ọkan lara awọn ohun ti baba mi ti mọ wo lara ọrẹ mi kan to farapa,''Elebuibon lo sọ bẹẹ.

Ifayemi Elebuibon

Oríṣun àwòrán, Ifayemi Elebuibon

O ni ọfọ ni oun mu bọnu nigba ti oju ibi ti ọrẹ oun fi ṣeṣe naa n ṣẹjẹ.

Elebuibon sọ pe iyalẹnu lo jẹ fawọn to wa nibẹ lọna naa pe oun fi ọfọ da ẹjẹ jade duro.

Araba ilu Osogbo ṣalaye siwaju pe, oun tun fi ọfọ ji saye ẹnikan to daku pada.

''Baba mi kọ mi ni oriṣiiriṣii nkan nipa Ifa nigba ti mo wa ni ọmọ kekere, koda o tun gba onifa mii, Agbongbon Awo ilu Osogbo, Oloye Faniyi Ajani lati maa kọ mi ni Ifa,'' Oloye Elebuibon ṣalaye.

Àkọlé fídíò, Itaniji: Oluwo sọ ìtàn bí Orunmila ṣe jìyà nílùú Iwo àti ayọ̀ tó gbẹ̀yìn rẹ̀ torí sùúrù

Elebuibon ni oun jẹ paanu iya, nitori ki oun le mọọ kọ, mọọ ka.

''Lati ilẹ ni baba mi ti sọ fun mi pe n ko ni lọ si ile iwe nitori iṣẹ Ifa akọsẹkaye mi sọ pe mo gbọdọ ṣe.

Ṣugbọn mo nifẹ si ki n mọ iwe kọ ati ki n mọ iwe ka. Mo maa n wo bawọn ọmọkunrin mẹta kan ṣe maa n ṣiṣẹ amurele wọn nile ọga mi onifa lagbegbe Oke Popo.

Amọ igbaju igbamu lo maa n bade lọdọ ọga mi, nitori ko fẹ ki n ni ohun kan ṣe pẹlu ileewe,'' Oloye Elebuibon lo ṣalaye bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Ado Ekiti Blind Couple: Tọkọ-taya Oke ní Ọ́ba òkè ló fi àwọn dá àrà tó wù ú

Elebuibon ni oun ko titori iya ti ọga oun fi jẹ oun ṣe, oun rii pe oun le kọwe, oun si le mọọ ka pẹlu.

Ṣebi Yoruba bọ, wọn ni ko si ẹni to mọ ibi ori n gbe e lọ. Elebuibon ni iṣẹ Ifa ti gbe oun de orilẹede Amerika ati kaakiri agbaaye.

O ni oun maa n ṣaaba lọ si Amẹrika lati kọ awọn eeyan lẹkọọ lori aṣa Yoruba ati ilẹ Afirika, bakan naa lo ni oun maa n ṣe etutu fawọn onibara oun nibẹ.

Koda Elebuibon ni oun ti kọ awọn akẹkọọ fasiti ipinlẹ San Francisco ri l'Amerika.

Àkọlé fídíò, Paystack Shola Akinlade: Ìgbésẹ̀ 5 yìí ni mo gbé tíléeṣẹ́ Stripe fi dókòwò $200m pẹ̀lú mi

Oloye Elebuibon ni ọkan oun balẹ pe awọn ọmọ oun ko kẹyin si Ifa sise.

O ni idunnu lo jẹ fun oun pe awọn ọmọ oun n polongo Ifa kiri origun mẹrin agbaye.

Araba ilu Osogbo ni iwe tawọn ọmọ oun ka ko ni ki wọn pa iṣẹ Ifa ṣiṣe ti.

''Irọ ni pe ọba tuntun maa n jẹ ọkan ọba to ku bii ara etutu ni ipebi,'' Oloye Elebuibon lo wi bẹẹ.

O ni ko si ẹsin yala ẹsin ibilẹ, musulumi tabi kristẹni to fọwọ si ki wọn maa fi eeyan ṣe irubọ.

Oloye Elebuibon sọ pe awọn to ba n ṣe iru nkan bayii n ṣe lati fi tabuku ẹsun abalaye ni.

Nigba ti awọn akọroyin beere iye ọdun ti eeyan fi le kọ iṣẹ Ifa, o ni o kere tan kikọ iṣẹ Ifa yoo gba ọdun mẹwaa ati abọ.

Elebuibon ni o le ju ọdun mẹwaa lọ nitori ẹkọ kikọ nipa Ifa ko le tan laelae.