DNA: Wo àkójọpọ̀ ọ̀nà méje tí ọmọ àlè fi le wọnú ilé láì jẹ́ pé ìyàwó ṣe aṣemáṣe

Baba ati omo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Wo bí ìyàwó ṣe le gbé ọmọ Ọbà fún Ọ̀ṣun láì yan àlè.

O to ọjọ mẹta kan ti ọrọ gbigbe ọmọ ọba fun ọsun ti n ja rain-rain lawujọ wa.

Eyi ko si sẹyin bi awọn ọkọ ninu idile se n gbe igbesẹ lati se ayẹwo awọn ọmọ wọn boya wọn jẹ ojulowo ọmọ ọkọ abi ọmọ ale.

Iwadii si ti fihan pe orilẹede Naijiria lo se ipo keji lẹyin orilẹede Jamaica, ti isẹlẹ gbigbe ọmọ Ọba fun Ọsun ti maa n waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Pupọ isẹlẹ gbigbe ọmọ ale wọnu ile si ni awọn eeyan saba maa n di ẹbi rẹ ru awọn iyawo ile pe wọn se asemase nita pẹlu ọkunrin mii.

Ero ọpọ eeyan ni pe ti iru ifẹ ikọkọ bẹẹ ba ja si oyun fun abilekọ, lo maa n ti iru ọmọ bẹẹ mọ ọkọ rẹ lọrun ninu ile.

Baba ati omo

Oríṣun àwòrán, DNA

Wọn ni bi ayẹwo DNA wa waye lori iru ọmọ bẹẹ, ni ọkọ yoo to mọ pe ọmọ ọlọmọ ni oun n pe ni ọmọ oun.

Amọ iwadi iwadii ijinlẹ kan ree, eyi to salaye bi ọmọ ale se le wọnu idile lai jẹ pe iyawo ile se asemase pẹlu ọkunrin miran nita.

Awọn igbesẹ to le mu ki ọmọ ale wọnu idile lai jẹ pe iyawo yan ale:

Ayẹwo fun mọlẹbi ti DNA wọn bara mu:

DNA tẹgbọn-taburo tabi ti baba ati ọmọ lee sunmọ ara wọn tabi ko jẹ nkankan naa.

Bi ọkan ninu wọn ba si ni ajọsepọ pẹlu iyawo ẹnikeji ninu ẹbi naa, boya ẹgbọn ba iyawo aburo sun, abi baba ba iyawo ọmọ rẹ sun, to si di oyun.

Ti obinrin bẹẹ ba gbe ọmọ naa fun ọkọ rẹ gangan, to ba di ọjọ iwaju, ti ayẹwo DNA si waye lori ọmọ yii, iwadii fihan pe ayẹwo DNA ọmọ naa ko ni fihan pe ọmọ ale ni.

Idi ni pe DNA baba to fun iya rẹ loyun ati baba to n pe ni baba rẹ jẹ nnkan kannaa tori ẹbi ni wọn.

Irufẹ baba bẹẹ ti wọn sọ fun pe ojulowo ọmọ ni ọmọ rẹ, ko ni mọ pe ọmọ oun kọ, ọmọ ọlọmọ to jẹ mọlẹbi oun ni.

Baba ati omo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Asise nidi ayẹwo DNA:

Gẹgẹ ba se mọ pe ko si ẹnikẹni tabi ohunkohun to pe ayafi ọlọrun ọba.

Bẹẹ na lo se ri pẹlu oniruuru imọ ẹrọ sayẹnsi ti oyinbo n se nitori asise lee waye lati ipasẹ ẹrọ naa, paapaa ti ko ba sisẹ bo se yẹ.

Bakan naa si ni ọmọ sori pẹlu ilana ati imọ ẹrọ ti wọn n gba se ayẹwo DNA.

Ti asise ba si waye, o see se ki wsn pe ọmọ ọkọ ni ọmọ ale tabi ọmọ ale ni ọmọ ọkọ eyi to lewu pupọ.

Bi wọn ba si pe ọmọ ọmọ ni ọmọ ale, ile ti daru, tiru ọmọ bẹẹ yoo si di ọmọ ale titi ayeraye lai jẹ pe iya rẹ yan ale tabi gbe ọmọ ọba fun ọsun.

Iru isẹlẹ yii ko si le mai waye nilẹ Afirika, ti itọju ati imọ ẹrọ ko ti kun to.

Pasipaarọ ọmọ nile iwosan:

Iwadii naa ti fihan pe o see se ki wọn paarọ ọmọ mọ iyawo ile lọwọ nile iwosan lai jẹ pe o mọ nipa rẹ.

Irufẹ isẹlẹ bayii si le waye ni orisi ọna meji eyi to nii se pẹlu iwa amọọmọ se latọdọ awọn osisẹ eleto ilera, olugbẹbi alaboyu tabi dokita.

Bakan naa ni isẹlẹ yii le waye nipa asise lai jẹ pe awọn olutọju alaisan tabi eleto ilera mọọmọ paarọ ọmọ.

Àkọlé fídíò, Ẹ má fún mi l'ówó bárà, mò ń bọ́ ẹnu púpọ̀, aya àtọmọ mẹ́ta - Oladapo Okalawon Shonde

Iwa mimọọmọ paarọ ọmọ mọ iya ikoko lọwọ:

Eyi maa n waye nifọwọ kọwọ pẹlu awọn osisẹ eleto ilera nile iwosan, to ti gba owo lati paarọ ọmọ laarin iyalọmọ kan si ekeji.

Nigba miran, wọn le paarọ ọmọbinrin si ọkunrin tabi ọkunrin si obinrin, ti iya ti wọn paarọ ọmọ rẹ ko si ni mọ pe ọmọ ọlọmọ ni wọn gbe fun oun.

Idi ni pe ti obinrin ba sẹsẹ bimọ, ẹmi ati itọju ara rẹ ni yoo kọkọ du, ọmọ tawọn agbẹbi ba si gbe fun pe o bi naa si ni yoo gbe wale.

Nigba miran, o le jẹ pe akoko ti iya ikoko naa kọ si baluwẹ lawọn olubi ẹda naa yoo ri aaye paarọ ọmọ sira wọn.

Àkọlé fídíò, Wòlíì ni ọmọ táà bá bí ni ago kan géérégé ni...Bàbá tó bí Ooni Adeyeye Ogunwusi sọ àṣírí àkọsẹ̀jayé rẹ̀

Iwa asise nidi pipaarọ ọmọ tuntun sira wọn:

Ti wọn ba sẹsẹ bi ọmọ tuntun nile iwosan ijọba, wọn yoo so orukọ baba ọmọ naa mọ ọmọ ọhun lọwọ lati tete daa mọ laarin ọpọ ọmọ tuntun ti wọn bi wọn si akoko kan naa.

Ni ọpọ ile iwosan ijọba yii, ọpọ ọmọ tuntun ti wọn ba bi sile iwosan naa lasiko kan naa, ni wọn yoo gbe wa sibudo ti wọn ti n wẹ wọn.

Bi wọn ko ba si sọra, orukọ ti wọn kọ si ọwọ iru ọmọ tuntun bẹẹ le jabọ laimọ, ti yoo si nira lati mọ iru ọmọ ẹni tii se.

Ti iru isẹlẹ naa ba si waye fun ọmọ tuntun meji tabi mẹta, eyi le mu ki awọn agbẹbi gbe awọn ọmọ yii fun iya to ba wu wọn, ti iyawo yoo si gbe ọmọ ọlọmọ wale fun ọkọ rẹ laimọ.

Àkọlé fídíò, Ado Ekiti Blind Couple: Tọkọ-taya Oke ní Ọ́ba òkè ló fi àwọn dá àrà tó wù ú

Ifipabanilopọ:

Ni ọpọ igba ti isẹlẹ ifipanilopọ ba waye, asa awujọ ni lati sọ fun obinrin ti wọn ba fipa ba lopọ pe ko panu mọ.

Bi obinrin naa ba si fi ọrọ yii se apamọra, ti ko si tun lọ sile iwosan fun ayẹwo ati itọju ara rẹ, ewu n bẹ loko longẹ.

Bi iru obinrin bẹẹ ba ni ibalopọ pẹlu ọkọ rẹ ni tooto igba ti isẹlẹ ifipanilopọ naa waye, o see se ko loyun, ko si jẹ pe ẹni to fipa ba lopọ lo ni oyun.

Iru iya bẹẹ le gbe ọmọ ale wọle lai fura pe oun ti gbe ọmọ ọba fun ọsun.

Pipaarọ atọ ọkunrin kan si ti ẹlomiran:

Ni awọn ile iwosan ti wọn ti n fi atọ pamọ, o see se ki pasipaarọ atọ ọkunrin kan si ti ẹlomiran waye.

Eyi si le waye bi lọkọlaya ba n wa ọmọ, ti wọn si ni ki ọkọ wa fi atọ silẹ, ki wọn le fi ilana IVF gbe sinu iyawo rẹ.

Amọ bi wọn ba ti paarọ atọ iru ọkọ iyawo bẹẹ, o le loyun pẹlu atọ ọkunrin miran laimọ.

Ayẹwo DNA lọjọ iwaju si le fihan pe ọmọ ale ni iyawo gbe wale.

Àkọlé fídíò, Ọwọ́ mi méjèjì ni Fulani gé jábọ́, wọn ò tilẹ̀ jẹ́ kí n rí ìbọn gbèjà ara mi - Fijilante