Kemi Afolabi on Lupus: Wo bí Kemi Afolabi ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó ti kàn síì pẹ̀lú owó ìtọ́jú àìsàn Lupus

Oríṣun àwòrán, Toyin Abraham
"Okun ati agbara mi ti pada mo si ṣetan lati ja fita-fita".
Eyi ni ọrọ to ya ni lori to tun jade lẹnu gbajugbaja oṣere lẹyin igba to jade lati sọ faraye nipa ohun to ti n gbe sabẹ aṣọ latọjọ yii pe aisan to n ṣe oun fẹ mu ẹmi ohun lọ laarin ọdun marun si isinsinyii.
Ninu ọdun marun yii gẹgẹ bi Dokita rẹ ṣe sọ fun un lo tun ni oun ti lo ọdun kan ninu rẹ bayii.
Iroyin yii jẹ eyi to ja ọpọlọpọ eeyan laya ni tori ko yatọ si ọrọ eeyan to ti gbọ deeti ọjọ iku rẹ.
Lati igba naa ni ọpọlọpọ eeyan ti n gbohun adura soke fun Kemi ti awọn mii si ni ko ma bẹru rara tori Dokita kọ lo ni idajọ lọwọ bikoṣe Ọlọrun olodumare.

Oríṣun àwòrán, Kemi Afolabi
Koda, oniruuru imọran lo ti n jade si Kemi Afolabi ati latọdọ ẹni to mọ ọ ri o atni ti ko mọ ọ ti wọn gbọ iroyin naa.
Bí ẹ ko ba gbagbe, lori eto gbajugbaja sọrọ sọrọ ori ayelujara kan, Chude Jideonwo ni ọrọ ipo ilera Kemi yii ti burẹkẹ ti gbogbo aye gbọ to n fi omije sọrọ nipa gbogbo ilakọja rẹ ati iye owo to n tu jade ni gbogbo igba fun itọju aisan yii.
Igba naa ni Kemi fọhun sita pe Dókítà ní ọdún márùn-ún ló kù fún mi láyé, mo sì ti lò lára rẹ̀ - Òṣèré Kemi Afolabi

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ẹwẹ, gbajugbaja oṣere naa ti n fi ẹmi imoore han si awọn ọmọ Naijiria fun ifẹ wọn, ati awọn akẹgbẹ rẹ fun iranwọ owo ti wọn n ṣe fun un.
Lati igba ti Kemi tun ti di eeyan ti wọn mọ sii nitori ohun to n la kọja, awọn ọmọ Naijiria rọjo ifẹ lee lori ti wọn si n fi ifẹ han sii lati jẹ ko gbe ero yii kuro lọkan rẹ ati lati mu ẹru rẹ fuyẹ lori owo to n na lati ra oogun lọsọọsẹ.
Koda, wọn ti ṣi oju opo ayelujara kan ti awọn ẹlyinju aanu to ba fẹ ṣeranwọ lee fi owo ranṣẹ sii fun.
"Mo dupẹ pupọ fun ifẹ ti fi han mi, o pọ gan, igboya mi ṣi wa, agbara lati ja fun aye mi si ti pada lagbara sii, mo dupẹ fun itọju, atilẹyin, aduroti, bibeere mi.
Ẹ ṣe mo dupẹ, Ọlọrun alagbara ko ni jẹ ki aisan jẹ ipin yin". Kemi sọ eyi ninu fidio naa.
Ṣaaju ni Kemi Afolabi fi sita loju opo rẹ pe Ẹ gbà mi o, àwọn oníjìbìtì ayélujára ti ń bèèrè ìrànwọ́ lórúkọ́ mi - Kemi Afolabi lọgun lati fi maa lọ awọn eeyan lọwọ gba nitori ailera rẹ to si ki awọn ṣọra fun wọn ki wọn si ba oun fi ẹjọ wọn sun.

Oríṣun àwòrán, Kemi Afolabi

Oríṣun àwòrán, Jaye Kuti
Ninu fidio kan ti o jade loju opo akẹgbẹ rẹ, toyin Abraham ni Kemi Afolabi ti n fi ọrọ idupẹ sita ti Toyin Abraham naa si n sọ fun awọn ololufẹ rẹ pe wọn a ranti pe oun ti dapọ biba eeyan tọrọ owo lori ayelujara duro tipẹ "amọ́ eleyi, mo ni láti ṣe e fun ọrẹ mi, arabinrin mi ati akẹgbẹ mi, Kemi Afolabi.
Bakan naa ni awọn oṣere mii naa ti bẹrẹ si ni fi fidio idupẹ rẹ ọhun sita bii Mercy Aigbe, Odunalade Adekola atawọn mii.

















