Nigeria vs Ghana: Eléyìí kọjá jọ̀lọ́ọ̀fù ẹni tó dùn ju, orí pápá ní Nàìjíríà àti Ghana yóò tí fìjà pẹẹ́ta

Akọnimọọgba Ghana Otto Addo ati Augustine Eguavoen ti Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Oluwashina Okeleji
    • Role, Football Writer, Nigeria

Bi eeyan ba darukọ Naijiria ati Ghana papọ ninu gbolohun kan, ohun meji lo maa n wa si ọkan awọn to ba gbọ ọ.

Akọkọ ni jọlọọfu ẹni to dun ju ti ẹlẹẹkeji si jẹ ẹni to mọ bọọlu gba julọ ninu awọn orileede mejeeji yi.

A tun le fi olorin to ba mọ orin kọ ju ninu olorin Naijiria ati Ghana kun afiwe yi ṣugbọn nitori pe ọrọ wa niṣe pẹlu ere idaraya, a o fi mọ nidi ere bọọlu.

Lọjọ kẹẹdọ́gbọn ati ọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu Kẹta, ija kan ni wọn yoo pari laarin ikọ agbabọọlu il wnyi, ẹni to ba si jaweoluboriu ni yoo tẹsiwaju lọ si idije ere bọọlu agbaye ni Qatar 2022.

Ipade laarin Naijiria ati Ghana ni Kumasi lọjọ Karundinlọgbọn oṣu yi yoo kamama.

Gbọngbọn yoo kan si, alarẹ yoo jagba ti pẹpẹyẹ yoo si pọnmọ lọjọ taa n wi yi.

Ipade akọkọ ree lari awọn orileeede mejeeji lati nkan bi ọdun mkanla sẹyin nigba ti wọn koju ni ọdun 2001.

Ọjọ mẹrin lẹyin ti wọn ba kọkọ figa gbaga ni Kumasi, wọn yoo tun fi ipade si Abuja fun ifẹsẹwọnsẹ ikẹyin ṣaaju irinajo ẹni to ba pegede si Qatar.

Naijiria n gbiyanju lati lọ si idije Workld Cup ẹlẹẹkẹrin wọn lera ti Ghana si fẹ tun tọ adun idije yi wo lẹyin ijakulẹ wọn lọdun 2018 ti ko jẹ ki wọn kopa ni Russia.

Àkọlé fídíò, Ọwọ́ mi méjèjì ni Fulani gé jábọ́, wọn ò tilẹ̀ jẹ́ kí n rí ìbọn gbèjà ara mi - Fijilante

Ẹgbọn ti ko ribi yan fanda ati aburo toun naa n ṣi n ra bi ọmọde

Naijiria ati Ghana kii se ajoji arawọn.

Ni ti ẹni to kọkọ gba ominira, Ghana ṣaaju Naijiria jakun lọwọ amunisin ṣugbọn ninu orileede to tobi julọ, Naijiria gbe Ghana mi laimọye igba.

Koda ninu ibi tawọn ọmọ Ghana ti n wa ọna ijẹ ati imu ni Naijiria wa lati ibẹrẹ ko to di ọrọ Ghana must Go to da ọpọ ọmọ ilẹ naa pada sile.

Ikọ Super Eagles ṣaaju ki wọn to fidirẹmi lọwọ Tunisia ni Afcon 2021

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Naijiria fidirẹmi pẹlu 1-0 lọwọ Tunisia ni idije Afcon 2021 Cameroon

Amọ ṣa bo ba kan ti ọrọ ere bọọlu, Ghana ti gba ife ẹyẹ Afcon lẹẹmẹrin ti Naijiria si ṣẹṣẹ ri gba niwọn igba mẹta pere.

Laarin ọdun1970-1980 Ghana a maa foju Naijiria gbole.

Bi a ko ba gbagbe,wọn gbewuro soju Naijiria ni ọdun 1992 nigba ti wn bori Naijiria ni abala to kangun si aṣekagba idije Nations Cup.

Omi tuntun ti ru bayi ti Naijiria si ti gba ife ẹyẹ Afcon ni ọdun 1994 ati 2013.Lati 1982 ti Ghana ti gba ife yi kẹyin, nkan ko rọgbọ fun wọn titi di asiko yi.

Àkọlé fídíò, 'Tóo bá lè bá mi jà, ìwọ wá!' Ademodi Maria tó lu ọmọdékùnrin mìí lálùbami rèé

Ọgbọn ayinike lọrọ yi gba

Lara ọgbọn ti Ghana da lati le ko ipaya ba Naijiria ni pe wọn ko tete kede orukọ awọn ti yoo ṣoju ilẹ naa lori papa.

''O si ko idamu bawọn'' nigbolohun to jade lẹnu ọmọ ẹgbẹ igbimọ alaṣẹ ere bọọlu Ghana Sammy Anim nigba to n ba BBC Sport sọrọ nibẹrẹ ọṣẹ yi.

''A ko le maa lo ọgbọn atẹyinwa ta ba fẹ bori Naijiria. Eyi taa lo yi, o da wa loju pe a o bori Naijiria lati tẹsiwaju lọ si Qatar 2022''

Àkọlé fídíò, 'Mi ò ní wo bọ́ọ̀lù mọ́ ti Nàìjíríà bá fìdírẹmi ni Russia 2018'

Balogun ikọ Ghana Andre Ayew ko ni kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ Kumasi nitori pe o gba kaadi pupa. Otto Addo ni akọnimọọgba Ghana bayi ti Chris Hughton agbabọọlu tẹlẹ fẹgbẹ Tottenham yoo jẹ oludari eto ikọ naa.

Awọn agbabọọlu Naijiria kanna wa ti wọn ko ni kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ yi.Alex Iwobi ti gba aṣ lọrọọkun nile, Wilfred Ndidi farapa ṣugbọn Ademola Lukman yoo ṣoju Naijiria lyin to paarọ orileede kuro nil Gẹẹsi lati le ṣoju Naijiria.

Awọn alatilẹyin ikọ Black Stars Ghana

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ghana nikan kọ ni nkan ko rọgbọ fun.

Awọn alatilẹyin Naijiria ti wọn ruga apa soke ti wa n se pẹlẹ bayi lẹyin tijakulẹ ikọ wn ni Afcon to kọja yi.

Eyi ko si ṣyin ijakulẹ ti ikọ Augustine Eguavoen koju lẹyin ti Tunisia fi goolu kan ṣoṣo ja ireti wọn labala komẹsẹoyọ.

''Mo gba pe emi ni mo lẹbi ijakulẹ ati gbogbo nkan to ṣẹlẹ ni Cameroon ṣugbọn nkan yoo yatọ pẹlu Ghana''

Ọrọ iwuri ree ti akọnimọọgba Super Eagles sọ lasiko ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC.

''Nkan to tobi lo wa nilẹ yi to si da lori niti yoo kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye. Mi o fẹ sọrọ pupọ. Ipade dori papa''

Ọdun 2013 ni Naijiria gba ife ẹyẹ Afcon kẹyin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọdun 2013 ni Naijiria gba ife ẹyẹ Afcon nigba ti wọn bori Burkina Faso