Ghana Vs Nigeria: Ahmed Musa ṣèlérí pé Super Eagles yóò fẹ̀yìn Black Stars gbolẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì

Awọn agbabọọlu Naijria ati Ghana

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Agbabọọlu Super Eagles, Ahmed Musa ti sọ pe ikọ naa yoo sa ipa rẹ alati pegede fun idije ifẹ ẹyẹ agbaye Qatar 2020 nigba ti wọn ba koju ikọ gbabọọlu Ghana lopin ọsẹ yii.

Super Eagles yoo koju Black Stars ni ẹsẹ akọkọ ni papa iṣere Baba Yara to wa niluu Kumasi lọjọ Ẹti, nigba ti wọn yoo pada wa gba ẹsẹ keji ni papa iṣere Moshood Abiola to wa niluu Abuja.

Ikọ agbabọọlu mejeji ti bẹrẹ si n ṣe orogun ara wọn ni nnkan bii ibẹrẹ ọdun 1950, amọ ikọ Ghana lo ṣaba maa n jawe olubori ninu ikọ mejeji.

Ni gbogbo igba ti ikọ mejeji ti pade lori papa, Ghana ti bori nigba mọkanlelogun, wọn padanu ifẹsẹwọnsẹ mẹwaa, nigba ti ifẹsẹwọnsẹ mejidinlogun jẹ ọmi.

Àkọlé fídíò, Èyìí ni báwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀èdè Ghana ṣe ń wa kùsà góòlù lọ́nà kòtọ́ láti rówó

Ẹwẹ, Ahmed Musa ni ikọ aagbabọọlu tuntun Super Eagles yii ko gberegbe, wọn ko si ni fidi jalẹ ninu awọn ifẹsẹ a wọn wọn pẹlu Ghanato n bọ lọna.

Ninu fidio kan to fi lede loju opo Yoruba, Musa sọ pe "Lootọ ni wọn ti maa n da bantẹ iya fun wa tẹlẹ, amọ igba atijọ niyẹn, awa to wa ninu ikọ Super Eagles ti aye ode oni dantọ lati fidi wọn janlẹ."

"Mo mọ pe a maa sa ipa wa lati mu ori awọn ololufẹ wa wu."

"Lootọ ni a ṣeleri lati gba ife ẹyẹ Afcon to kọja ti a si ja awọn ọmọ Naijiria kulẹ, ohun kan ti a le ṣe bayii lati mu inu awọn araalu dun ni lati pegede fun ife ẹyẹ agbaye, a oo si ṣe bẹẹ lagbara Ọlọrun."

Àkọlé fídíò, Samuel Ajirebi ọmọ ọdún mẹ́rin àtijọ́ rèé, ó bojú wo fíìmù rẹ̀ ní kékére, máàkì tó fún ara rẹ̀ rèé

Musa fi kun pe lootọ Ghana kii ṣe ẹran rirọ, amọ awọn yoo gbiyanju nitori orogun to wa laarin Naijiria ati Ghana kii ṣe nipa ẹrẹ bọọlu afẹsẹgba nikan.

O ni "Orogun Naijiria ati Ghana kii ṣe nipa ere bọọlu nikan, a tun ṣe orogun de idi eto oṣelu, jollof rice, orin kikọ, oge ṣiṣe, ati bẹẹ bẹẹ lọ, amọ ni bayii ti ere bọọlu ti pa wa pọ, wọn maa mọ pe awa ni ọba."