Ekiti abduction: Ka nípa bí ìyá àti ọmọkùnrin rẹ afurasi ṣé fí ọmọ ọlọ́mọ pàmọ̀ fún ọdún mẹ́ta gbáko

Ẹ wa nkan fidi le ki ẹ si fi idi le nkan nitori iroyin eleyi gba ki eeyan mu ọkan ko to le ka nipa rẹ.
Jẹjẹ ni arabinrin ọmọ ọdun marundinlogun kan gbera kuro nile ni ọjọ kan ninu oṣu Kẹta ọdun 2019,
Erongba rẹ ni lati lọ si ile ẹkọ igbaradi fun idanwo Waec kan to wa ni ilu Ado Ekiti ni ipinlẹ Ekiti.
Bi aba foju wo o daada, ọrọ taa n sọ yi waye ni nkan bi ọdun mẹta sẹyin.

Ilẹ ẹkọ lẹsiini lo lọ kẹyin tawọn obirẹ ko fi ri mọ.
Wọn fẹjọ sun ni agọ ọlọpaa, wọn sare soke wọn sa silẹ ṣugbọn pabo ni igbiyanju wọn ja si.
Ọjọ gun ori ọjọ ti oṣu si gun ori oṣu, nigba ti ọdun mẹtaa n pe bọ, eeyan kan ta iya ọmọdebinrin yi lolobo pe o dabi ẹni pe oun ri ọmọ wọn.
Wọn sare kirakita lọ si ẹka ijọba to n ri si itọju awọn ọmọ to sọnu. Pẹlu atilẹyin ikọ ọtẹlẹmuyẹ ọlọpaa, wọn ri ọmọde yi ni idile arabinrin Ademiloye Felicia.
Bawo lo se de ibẹ
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti lo ṣalaye gbogbo ọrọ taa sọ ṣaaju yi amọ wọn tun yanana ọrọ lori bi ọmọde yi se di ero ile arabinrin Felicia.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekiti Abutu Sunday tu kẹkẹ ọrọ ninu atẹjade to fi sita lẹyin ti ọlọpaa ṣe afihan afurasi to ji ọmọ yi gbe pamọ niilu Ado-Ekiti.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ọmọ Felicia Adewumi Ademiloye lo lẹdi apo pọ pẹlu iya rẹ lati ji ọmọdebinrin yi gbe pamọ.

Iwaadi awọn ọlọpaa bo ṣe sọ fi han pe lọjọ ti ọmọdebinrin yi poora, Adewumi lo tan w inu ile to sifun ni oogun oloro to pa iye rẹ.
Ọmọbinrin yi sọ fun awọn ọlọpaa pe boun se lo oogun yi tan loun ko m ọna ile mọ lati igba naa titi di bi wn ṣe pada wa doola rẹ lẹyin ọdun mẹta.
Ibalopo ati fifi ọmọdebinrin yi ṣowo nọbi
Iwadii ọlọpaa ati ifọrọwanilnuwo mu ki Adewumi jẹwọ pe lootọ loun ba ọmọdebinrin yi lopọ laimọye igba .
Ko tan sibẹ, o ni bi owo ba fẹri diẹ lọwọ oun, nise loun maa n pe awọn ọkunrin wa lati ba ọmọdebinrin yi ni ibalopọ ti wọn a si maa san owo fun un.
Owo ti Adewumi a maa gba wa laarin ẹgbẹrun mẹwaa si ẹgbẹrun ogun Naira.
Lọwọlọwọ bayii, arabinrin yi loyun oṣu mẹjọ sinuti wn si ti fi oogun oloro ba ile aye rẹ jẹ de ibi to lami.
Ẹsun ti ọlọpaa fi kan awọn afurasi yi bayii
Abutu Sunday to jẹ alukoro ọlọpaa sọ pe awọn ti fi ẹsun igbimọran lati ji eeyan gbe, ifipabanilopọ ati lilo ọmọde nilo ẹru kan Adewumi ati iya rẹ.
Arabinrin taa n wi yi ti n gba itọju ni ileewosan ti Kmisana ọlọpaa ipinlẹ Ekiti si ti ni ki wọn fi iya ati ọmọ to hu iwa yi si atimọle.


















