Uterus Didelphys: Elizabeth Amoaa sọ̀rọ̀ nípa ìrírí rẹ̀ pẹ̀lú ojú ara méjì àti ilé ọmọ méjì

Ọdun 2016 ni Elizabeth Amoaa lọ ṣe ayẹwo ara rẹ nile iwosan, nibẹ ni awọn dokita ti sọ fun pe isọro to n dojukọ ilera rẹ ko ṣẹyin pe o ni oju ara meji ati ile ọmọ meji.
Orukọ ohun to n ba obinrin naa finra, gẹgẹ bii awọn dokita rẹ ṣe sọ lẹyin ayẹwo MRI ni wọn n pe ni "uterus didelphys" tabi "double uterus."
Nigba to tu pẹrẹpẹrẹ ọrọ naa fun BBC, o ni oun ni oju ara meji, ọkan lapa ọtun ati ekeji lapa alaafia.

Oríṣun àwòrán, Elizabeth Amoaa
Bi Elizabeth ṣe mọ pe oun ni oju ara meji
Fun ọdun mejilelọgbọn ni Elizabeth fi n lọ sile iwosan lemọ-lemọ fun ayẹwo, lẹyin naa lo ṣe iṣẹ abẹ nigba marun un ọtọtọ amọ ko si eyikeyi ninu awọn dokita rẹ to mọ pe oju ara meji to ni lo n yọ ilera rẹ lẹnu titi di ọdun 2015.
Iroyin naa jẹ kayeefi fun amọ o gbakamu.
Lẹyin o rẹoyin, o pinnu lati jade sita lati sọrọ nipa bi ara rẹ ṣe ri ki awọn obinrin alawọ dudu to ba ni irufẹ ipenija bẹẹ le mọ pe kii ṣe ohun ti oju ko riri.
Ni bayii, obinrin naa to n fi ilẹ Gẹẹsi ṣe ibugbe ti n kọ awọn obinrin bii tirẹ nipa ẹya ara wọn.
Awọn dokita ni mi o le ṣabiyamọ
Lẹyin ti wọn ṣawari iṣoro rẹ, o ni awọn dokita sọ pe oun ko ni le bi ọmọ laye.
Amọ bo tilẹ jẹ pe wọn sọ bẹẹ fun, o fi inu ṣoyun, o si ti bi ọmọ tirẹ.
Oniruru ipenija lo dojukọ lasiko to loyun amọ o ru la.
O ni "Ile ọmọ mi apa ọtun n ṣiṣẹ daadaa ju ti apa alaafia lọ, nitori naa ti mo ba fi ile ọmọ osi gbe ọmọ naa, o ṣeeṣe ko má wa laye."
Nitori pe ile oọmeji lo ni, o ṣeeṣe ko fi ile ọmọ kan gbe oyun, ko si maa fi ile ọmọ keji ṣe nnkan oṣu.
Idi ree to fi jẹ pe lasiko to loyun, o si n ṣe nnkan oṣu.

Ki ni Uterine Didelphys?
Gẹgẹ bii awọn onimọ ṣe sọ, Uterine Didelphys ko wọnpọ amọ o tumọ si pe obinrin ni ile ọmọ meji ati oju ara meji.
Pupọ ninu awọn obinrin ti ara wọn ba ri bayii le bi ọmọ, ṣugbọn lọpọ igba wọn maa n padanu irufẹ ọmọ bẹ ni ikoko tabi ki oyun naa walẹ.
Awọn onimọ ko tii le sọ ohun to n sọfunfa irufẹ ara bẹẹ.
Ẹwẹ, wọn ni awọn to ba ni irufẹ ẹya ara bẹ le loyun, wọn si tun le bi ọmọ lai si idiwọ.
Kàyééfì! Àṣírí ìyá àti ọmọkùnrin rẹ̀ tó jí ọmọ ọlọ́mọ gbé fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó f'ọ́dún mẹ́ta tú l'Ekiti
















