OAU VC: Mọ̀ nípa ìlànà tí wọ́n n gbà yan VC fasítì ní Naijiria

Ọgba fasiti OAU

Oríṣun àwòrán, The sun newspaper

Lati asiko diẹ sẹyin, ni awuyewuye ti n waye ni awọn fasiti kan nitori iyansipo olori fasiti, ti a mọ si Vice Chancellor.

Ọkan lara awọn iyansipo to fa wahala laipẹ yii ni ti Fasiti ilu Ibadan, UI, lọdun 2020.

Bakan naa ni ti Fasiti ipinlẹ Eko, LASU.

Fun bi ọdun kan ni eto iyansipo naa fi ni idiwọ ni UI, nitori awọn ẹsun ti awọn kan fi n kan ẹni to fẹ ẹ fi ipo naa silẹ, Ọjọgbọn Idowu Olayinka.

Wọn ni o n gbiyanju lati yan ẹni to wu si ipo.

Yatọ si eyi, awọn agbaagba kan to jẹ ọmọ Ibadan yari pe ẹni to jẹ ọmọ bibi ilu Ibadan ni wọn gbọdọ yan si ipo naa "nitori pe ọmọ ilu kankan ko de ipo naa ri".

Igba ti ileeṣẹ eto ẹkọ ninu ijọba apapọ to da sii, ni ọrọ to yanju. Eyi to yọri iyansipo Ọjọgbọn Kayode Adebowale, lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021.

Wahala to waye ni LASU

Bi ọrọ ṣe ri ni UI, naa lori ni Fasiti ipinlẹ Eko, LASU, lọdun 2021 bakan naa.

Àkọlé fídíò, Wòlíì ni ọmọ táà bá bí ni ago kan géérégé ni...Bàbá tó bí Ooni Adeyeye Ogunwusi sọ àṣírí àkọsẹ̀jayé rẹ̀

Koda, ẹẹmeji ni Gomina Babajide Sanwo-Olu kọ ẹni ti igbimọ oluṣakoso yan, nitori awọn awuyewuye to n waye.

Lẹyin o rẹyin, ni igbimọ tuntun yan Ọjọgbọn Ibiyemi Olatunji-Bello.

Lọwọlọwọ, Fasiti Obafemi Awolowo lo n koju wahala yii. Eyi ko ṣẹyin iyansipo Ọjọgbọn, ti awọ̀n kan si n fẹhonu han pe kii ṣe ọmọ ilu Ile-Ife.

Awọn oniṣẹẹṣe to ṣe iwọde ni OAU

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/SOLA SALAKO AJULO

Koda, ni ọjọ diẹ sẹyin ni awọn ọmọ ẹgbẹ Ọlọṣun ṣe iwọde ninu ọgba fasiti naa pe awọn kọ iyansipo Ọjọgbọn Adebayo Banire, ni kete ti wọn kede orukọ rẹ.

Ilana wo ni iyansipo olori fasiti, VC gbọdọ tẹle?

Eyi nii ṣe pẹlu iru fasiti to ba jẹ - boya ti ijọba apapọ, ipinlẹ tabi aladani.

Gẹgẹ bi iwadii sẹ sọ, to ba jẹ pe fasiti ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ ni, to si jẹ ti ijọba apapọ tabi ti ipinlẹ, gomina tabi aarẹ ni yoo yan olori ile ẹkọ naa fun igba akọkọ.

Ọdun marun-un ni awọn VC ma n lo nipo.

Awọn ilana naa:

  • Lẹyin iyansipo akọkọ yii, gbogbo igba ti ipo Vice Chancellor ba ṣofo ni awọn fasiti yii gbọdọ gbe ikede igbanisiṣẹ sita, ninu iwe iroyin meji, o kere tan.
  • Ikede naa si gbọdọ jade ni oṣu mẹfa ṣaaju ki saa ẹni to wa ni ipo naa to pari.
  • Ninu ikede ọhun ni wọn yoo kọ awọn amuyẹ ti ẹni ti yoo gba ipo Vice Chancellor naa gbọdọ ni.
  • Lara awọn amuyẹ naa ni iye ọdun to ti fi ṣiṣẹ lẹyin to gba oye imọ ijinlẹ ọjọgbọn, awọn iwe ẹri to ni, ati akọsilẹ nipa awọn ipo to ti wa ri.
  • Ti gbedeke fun awọn to ba fẹ kọwe gba iṣẹ naa ba wa sopin, ọfiisi ẹni to jẹ akọwe agba fasiti, Registrar ni yoo ṣe agbeyẹwo awọn iwe naa, ti yoo si ṣe ayọkuro awọn ti ko ba koju osunwọn.
  • Lẹyin naa ni awọn ọmọ igbimọ kan ti wọn n pe ni 'Search Team' yoo ṣe agbeyẹwo awọn orukọ, ati ifọrọwanilẹnuwo ati idanwo fun awọn olukopa.

Ninu iwe apilẹkọ kan ti ẹnikan to ti fi igba kan jẹ olori ile ẹkọ ofin ni Fasiti ilu Benin, Ọjọgbọn Ehi Oshio, kọ lọdun 2006, o ṣalaye pe ninu ofin idasilẹ awọn fasiti ni Naijiria, abala kọkanla rẹ lo sọrọ nipa iyansipo awọn olori fasiti.

O ṣalaye pe, Igbimọ alakoso (Governing Council) ni yoo buwọlu iyansipo naa, lẹyin ti awọn oludije ba ti la oriṣiriṣi idanwo ati ifọrọwanilẹnuwo kọja.

Igbimọ kan ti wọn n pe ni 'search team' ni yoo ṣeto igbanisiṣẹ naa.