OAU VC Crisis: Wo ohun tí ààrẹ àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ sọ lòdì sí ìfẹ̀hónúhàn torí VC tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn

Oríṣun àwòrán, Facebook/Sola Salako Ajulo
Awọn olori, ati apapọ ọmọ ẹgbẹ ẹlẹsin ibilẹ, Traditional Worshippers Association (TRWASO), ti koro oju si bi awọn ẹlẹsin ibilẹ kan ṣe iwọde ni OAU.
Ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ TRWASO, Oloye Ifasola Onifade, ati Aarẹ ẹgbẹ, Dokita Oluseyi Atanda fi sita, wọn ni inu awọn ko dun si bi awọn ẹlẹsin ibilẹ kan ṣe yabo ọgba fasiti Obafemi Awolowo, OAU, to wa nilu Ile-Ife lọjọ Aje, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta.
Awọn onitọhun sọ pe awọn n binu si iyansipo ẹni ti kii ṣe ọmọ Ile-Ife, gẹgẹ bi ọga agba tuntun.
Ẹgbẹ TRWASO sọ pe lootọ ni awọn mọ pe o ẹnikẹni ni ẹtọ lati fi ẹhonu han si nkan ti ko ba tẹ ẹ lọrun.
Wọn ni ṣugbọn iyalẹnu ati nkan to ṣajoji ni bi awọn oluwọde naa ṣe wọ aṣọ awọn, ati awọn nkan miran to jọ eyi ti awọn fi n ṣe ẹṣọ ara.
O ni awọn oogun abẹnugọngọ ti iroyin sọ pe wọn mu dani, nikan ni kii ṣe tawọn.
Bakan naa lo sọ pe iwadii awọn fihan pe awọn oluwọde ọhun kii sẹ ọmọ ẹgbẹ TRWASO ni ẹka Ile-Ife, tabi ni awọn ilu to yi Ile-Ife ka.
"Ẹgbẹ wa ko si ninu igbimọ to yan ọga agba tuntun fun OAU, nitori naa ni ko ṣe si idi kankan fun wa lati tako iyansipo rẹ.
"Awọn ọmọ ẹgbẹ wa ko kopa rara ninu iwọde ẹlẹya naa."
Ẹgbẹ naa wa a kilọ pe ki awọn to ṣe iru iwọde naa pẹlu awọn nkan ti aye mọ mọ ẹsin ibilẹ, dẹkun iru iwa bẹẹ. Wọn ni bibẹẹkọ, igbesẹ to l'agbara ni awọn yoo gbe ti iru rẹ ba tun waye.
TRWASO ni awọn ko nii gba ki ẹnikẹni ta epo si aṣọ ala awọn tabi mu ki araye ma a fi oju oloogun ika wo awọn ọmọ ẹgbẹ.
Gómìnà Oyetola rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn aráàlù atí Oníṣẹ̀ṣe tó fẹ̀hónúhàn ní OAU torí VC tuntun tí kìí ṣe ọmọ ìlú
Gomina Gboyega Oyetola ti ipinlẹ Osun ti rawọ ẹbẹ si awọn araalu Ile-Ifẹto lọ fẹhonu han ninu ọgba Fasiti Obafemi Awolowo nitori adari tuntun ti wọn yan sori ile ẹkọ naa.
Ninu atẹjade kan ti adari ikọ iroyin rẹ, Ismail Omipidan fi sita nirọlẹ Ọjọ Iṣẹgun, Oyetola jẹ ko di mimọ pe ipo iyi ni Fasiti kaakiri agbaye wa to si yẹ ki ohun gbogbo wa ni ṣiṣe pẹlu iyi.
O fi kun un pe bo tilẹ jẹ pe ipinlẹ ko ni ipa kankan lori ẹni ti yoo jẹ adari Fasiti Obafemi Awolowo tori ile ẹkọ ijọba ni amọ oun ni ojuṣe gẹgẹ bii gomina lati ri aridaju abo Fasiti naa atawọn oṣiṣẹ ibẹ.
- Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun kéde ìsinmi lẹ́nú iṣẹ́ nítorí ọdún Ìṣẹ̀ṣe
- Àwa nìkan ni ọ̀nà àbáyọ sí ìṣoro tó ń dojúkọ Naijiria- Àwọn Oníṣẹ̀ṣe
- Àwọn Oníṣẹ̀ṣe l'Ọ́yọ̀ọ́ ń bèèrè àyájọ́ ìsìnmi láti sààmi ayẹyẹ ọjọ́ ìṣẹ̀ṣe
- Krìsìtẹ́nì àti Mùsùlùmí, ètò ọba jíjẹ àti ìsìnkú ọba kò kàn yín, ẹ jìnnà si - Oníṣẹ̀ṣe l'Ogun
- 'Ojú ara méjì ni mo ní, wọ́n sì bí i mọ́ mí ni'
Idi niyi to fi rọ awọn araalu to n ṣe iwọde ifẹhonuhan pe ki wọn dawọ rẹ duro ki wọn si gba alafia laye.
"Pẹlu ọkan wuwo ati itara ni mo fi ke si ẹyin ara ilu Ile-Ife paapaa julọ awọn to n fẹhonuhan lori ẹni ti wọn yan gẹgẹ bii adari Fasiti Obafemi Awolowo pe ki wọn ma jẹ ki ifẹhonuhan kankan waye mọ ki wọn si gba alafia laaye".

Oríṣun àwòrán, Facebook/Sola Salako Ajulo
Oyetola ṣalaye pe nipa iru iṣẹ ati ojuṣe wọn, awọn Fasiti jẹ ile ẹkọ giga ti ofin ati aato n dari labẹ akoso eto ẹkọ.
O ni "bi a ba ro wipe ikankan ninu awọn ofin to n dari iṣẹ awọn Fasiti yii n jẹ bii oludena, ilana wa lati ṣe atunṣe iru nkan bẹẹ ju ka maa fi ọwọ ara wa ru ofin lọ.
"Alafia ni wọn mọ wa mọ l'Ọṣun nitori naa, a ko gbudọ ṣe ohun kankan lati ba orukọ ire wa jẹ", Oyetola fi kun un.
Àwọn aláṣẹ OAU dá sí ìfẹ̀hónúhàn tó ń wáyé nítorí VC tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn
Awọn alaṣẹ fasiti Obafemi Awolowo ni Ile Ife, OAU, ti sọrọ lẹyin ti awọn ọmọ ilu naa ṣe ifẹhonuhan tako bi wọn ṣe yan Ọjọgbọn Adebayo Bamire gẹgẹ bii alaṣẹ kejila fun fasiti naa.
Eredi ifẹhonuhan ọhun ko sẹyin bi awọn eeyan naa ṣe n fẹ ki wọn yan ọmọ bibi Ile Ife gẹgẹ bii ọga agba OAU.
Ninu erongba wọn lati ri daju pe ọmọ bibi ilu Ile Ife ni ọga agba fasiti ọhun, awọn olufẹhonuhan naa yabo fasiti ọhun pẹlu oniruru oogun abẹnu gọngọ lọjọ Aje.
Yatọ si eyii,wọn tun gbe agadagodo si ẹnu ọna meji to wọ fasiti naa, ti wọn ko si jẹ ki awọn olukọ, akẹkọọ atawọn ero mii wọle tabi jade nibẹ.
Ifẹhonuhan ọhun bẹrẹ lọjọbọ to kọja ni kete ti awọn alaṣẹ fasiti naa kede Bamire gẹgẹ bi ọga agba tuntun.
Iroyin ni awọn olufẹhohan naa bẹgi dina abawọle fasiti ọhun, wọn tun kọlu awọn oṣiṣẹ kan, ti awọn oṣiṣẹ naa si di ero ile iwosan.
Nigba ti yoo fi di ọjọ Aje, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, wọn ti ji de ẹnu ọna abawọle fasiti ọhun ni nnkan bii aago mẹfa idaji, pẹlu oniruru oogun abẹnugọngọ lọwọ wọn ti wọn si n ṣe iwọde.
A ko ṣe ojoro lati yan VC tuntun - OAU
Ninu atẹjade kan ti alukoro fasiti naa, Abiodun Olarewaju, fi lede, o ni eeyan mẹrindinlogun ni wọn n du ipo ọga agba ile ẹkọ ọhun.
O ni wọn pe gbogbo awọn eeyan naa wọle lẹyọ kọọkan fun ifọrọwanilẹnuwo gẹgẹ bii orukọ wọn ṣe han ninu iwe, awọn alaṣẹ fasiti naa si n kọ akọsilẹ nipa wọn gẹgẹ bii idahun wọn.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ẹni ti nọmba rẹ ga ju ninu gbogbo wọn lo jawe olubori gẹgẹ ọga agba tuntun fun fasiti naa.

Oríṣun àwòrán, OAU ile ife
O ni "Awọn alaṣẹ fasiti yii tẹlẹ ọna to tọ lati yan ọga agba tuntun, wọn ko si ṣe ojoro rara."
"Nitori naa, a rọ awọn agbagba ilu Ile Ife lati ba awọn olufẹhonuhan sọrọ ni itubu-inubu ki ibarẹpọ alaafia to wa laarin awọn araalu ati fasiti yii ma ba daru."















