Ifa religion: Àwọn Oníṣẹ̀ṣe ń fẹ́ kí Buhari fún wọn láàyè láti yanjú ìṣoro Naijiria lásìkò yìí

Isese

Oríṣun àwòrán, Ifashola Adedeji Durokifa

Ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe nipinlẹ ogun ti ke si Aarẹ Muhammadu Buhari lati fun awọn laye lati yanju iṣoro to n koju ẹka eto abo Naijiria.

Oluwo Ifa ti ilu Egba, Oloye Ifagbeminiyi Baoku lo sọ ọrọ naa lasiko ayajọ ọjọ Iṣẹṣe ti ọdun 2021 to waye niluu Abeokuta.

Ayajọ ọjọ Iṣẹṣe naa jẹ ọjọ kan ti wọn maa n ya sọtọ nilẹ Yoruba fun awọn ẹlẹsin ibilẹ lati sin awọn oriṣa wọn.

Oluwo Ifa ti Egba naa sọ pe idi ti Naijiria ṣe n koju oniruru iṣoro ni ẹka eto abo ni pe awọn eeyan ti kọ awọn oriṣa adayeba silẹ, wọn ko si tẹle awọn alakalalẹ Ifa.

Baoku sọ pe ti Naijiria ba fẹ lati yanju awọn iṣoro to n koju rẹ, o ni lati lọ bi ifa leere.

O ni "Ijọba ti sun awa ẹlẹsin ibilẹ ti si ẹgbẹ kan, wọn ko si mọ pe awa gan ni ọna abayọ si awọn isọro to n koju Naijiria lọwọ yii.

Àkọlé fídíò, Babatunde Gbadamosi: Mo ta gbogbo dúkìá mi lásìkò kan kí ń tó padà di eèyàn lónìí

"Awọn ilana kan wa to rọ mọ ẹsin ibilẹ, ti a ba ṣe awọn nnkan to yẹ ki a ṣe gẹgẹ bi ilana ọhun ṣe gbe kalẹ ni, a ko ni maa koju awọn iṣoro to n dojukọ ilẹ wa lonii."

Oluwo Ifa ọhun wa ke si gomina dapo Abiodun ti ipinlẹ Ogun lati kede ayajọ ọjọ ọdun Iṣẹṣe naa, to jẹ ogunjọ, oṣu Kẹjọ ninu ọdun gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ ki awọn to n ṣe ọdun naa le ri aye lati ṣe etutu to yẹ.

Àkọlé fídíò, Badagry: Ojú ọ̀nà àrèmabọ̀ fáwọn ẹrú tó ń lọ sókè òkun

O fi kun pe kii ṣe ifakokoṣofo ni ti awọn eeyan ba n ṣe ọdun Ifa.

Ẹwẹ, alaga ẹgbẹ Iṣẹṣe Parapọ ni Egba, Ifaniaki Amosun sọ pe ọdun Iṣẹṣe naa ni ọna kan gboogi lati mu irẹpọ wa laarin gbogbo awọn oniṣẹṣe.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Mo faramọ́ àtúntò 'Restructuring' tí kò lọ́wọ́ ìṣèlú nínú- Oba Ahmed Adeku

Ifaniaki ṣalaye pe "Gbogbo ẹlẹsin lo maa n kopa ninu eto idibo ni Najiria, ṣugbọn lẹyin ti awọn oloṣelu ba ti wọle ibo tan ni wọn maa n ṣe idẹyẹsi awọn ẹlẹsin ibilẹ."

"Ọdọdun ni awọn gomina maa kede ayajọ ọjọ isinmi fun awọn ẹlẹsin Kristẹni atawọn Musulumi, ki lo de ti wọn fi maa n yọ awa ẹlẹsin abalaye sẹyin?"

"O ye ki wọn ya ọjọ silẹ fun awa ẹlẹsin ibilẹ naa lati maa ṣe awọn isin wa, a n fẹ ki gomina wa ati minista fun ọrọ aṣa bojuwo ọrọ naa."

Lara awọn to peju sibi ọdun Iṣẹṣe naa ni Baba Iṣẹṣe ti Egba, Ọjọgbọn Ayinde Salami; Ojubono ti Egba, Oloye Onifade Ogundelde atawọn lọbalọba.