Modakeke killings: Ilé iṣé ọlọ́pàá rọ àwọn akọ̀ròyìn láti lépa àlááfíà lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣekúpani nílùú Modakeke

Oríṣun àwòrán, other
Ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti rọ awọn akọroyin lati sọ otitọ lori iṣẹlẹ iṣekupani eeyan marun un to waye lọjọ Ẹti to lọ niluu Modakeke.
Alukoro ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola lo sọrọ yii fawọn akọroyin lalẹ ọjọ Abamẹta.
Opalola ni alaafia ni ipinlẹ Osun nilo lọwọ yii kii ṣe rogbodiyan.
- Àlàyé tí Ooni Ile Ife ṣe nìyìí lórí ìpànìyàn tó dá ìkáyàsókè sílẹ̀ láàrín Ife ati Modakeke lọ́jọ́ Ẹ́tì
- Ìkáyàsókè ní Ife, Modakẹ̀kẹ̀ lẹ́yìn tàwọn kan pa ọmọ Modakeke márùn ún
- Èèdì! Èdè-ài-yedè bẹ́ sílẹ̀ lórí owó pínpín, awọn ajínigbé yìnbọn pa ara wọn, èèyàn mẹ́sàn-án kú
- Àwọn Emèrè ṣe àjọ̀dún nílùú Osogbo, bó ṣe lọ nìyí
- Ìdí rèé tí PDP kò ṣe tíì wọlé ìbò gómìnà l'Eko láti 1999 di àkókò yìí- Bode George
- Búlọ́kù fẹ́ dá ìjà sílẹ̀ láàrín ìjọba àtàwọn olówò búlọ́kù ìpínlẹ̀ Ondo
- Láàrín ọdún méjì ₦3 bílíọ̀nù làwọn ajínigbé ti gbà nílẹ̀ Yorùbá, èèyàn 200 ni wọ́n sì ti pa- Gani Adams
''A gbọdọ huwa gẹgẹ bi ọmọluabi lẹnu iṣẹ wa lai ṣegbe lẹyin ẹnikan.
Bakan naa a ni lati fi ifẹ han si ilẹ wa papaa julọ ti a ba n jabọ iroyin to niiṣe pẹlu ẹlẹyamẹya tabi ọrọ oṣelu to le di wahala.
Ẹ jẹ ki a ranti pe ọmọ Oduduwa ni gbogbo wa, ẹ ma jẹ ka da epo si ina to n jo.
Mo fẹ fi da yin loju pe ko si ohun to jọ ija Ife ati Modakeke ninu ọrọ to wa nilẹ yii.
Nitori naa, ẹ jẹ ki a gba alaafia laaye lẹnu iṣẹ wa ki a maa da omi alaafia ru nipinlẹ Osun.
Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kọkọ ke sawọn eeyan agbegbe Ifẹ ati Mọdakẹkẹ lati maṣe fi aye gba awọn kọlọrọsi janduku laarin wọn lati da wahala silẹ nibẹ.
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla funrarẹ ti pe Ọọni ti ilu ile Ifẹ, Ọba Ẹnita Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja keji ati Ogunṣua ti ilu Mọdakẹkẹ, Ọba Moses Oyediran Ọladẹjọ ti awọn mejeeji si ti fi daa loju pe omi alaafia laarin ilu mejeeji yii yoo pada toro.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọsun pẹlu ti ṣalaye pe igbesẹ ipana aawọ ti nlọ lọwọ lati ọjọ Ẹti ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.
Kọmiṣọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun, Ọlawale Olokode ni awọn iroyin kan ti tu si ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ ti yoo ṣe okunfa mimu awọn oniṣẹ ibi naa ni kiakia.
- Ìdí tí wọ́n fi ń pè mi ní Maradona rèé- Ibrahim Babangida
- Èèmọ̀ rèé o! Àrá sán pa èèyàn 17 níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó, ọkọ ìyàwó farapa
- Àwòrán ayẹyẹ ìwúyè Olu ti Warri
- Ìdí rèé tí PDP kò ṣe tíì wọlé ìbò gómìnà l'Eko láti 1999 di àkókò yìí- Bode George
- Búlọ́kù fẹ́ dá ìjà sílẹ̀ láàrín ìjọba àtàwọn olówò búlọ́kù ìpínlẹ̀ Ondo















