Kaduna bandits: Àwọn ajínigbé yìnbọn pa ara wọn, lẹ́yìn èdè-ài-yedè lórí owó pínpín

Oríṣun àwòrán, Other
Ẹfun abi eedi? Ẹgbẹ awọn janduku ajinigbe pawo meji kọju ija si ara wọn ni ijọba ibilẹ Giwa nipinlẹ Kaduna.
Koda eleeru sun igi, mẹsan an ninu awọn janduku ọhun lo dero Ọlọrun lẹyin ti da ibọn bo ara wọn tan.
Kọmiṣọnaa eto abo abẹle nipinlẹ Kaduna, Samuel Aruwan, lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn akọroyin.
- Gómìnà Osun, kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ sókè lórí wàhàlà tó bẹ́ sílẹ̀ láàrín Ife àti Modakeke lọ́jọ́ Ẹtì
- Ìkáyàsókè ní Ife, Modakẹ̀kẹ̀ lẹ́yìn tàwọn kan pa ọmọ Modakeke márùn ún
- Ọlọ́pàá mú afurasí tó pa oniṣowo ẹrọ igbowo POS kan, wọ́n ni àbọ̀dé ìgbẹ́jọ́ Sunday Igboho lọwọ́ tẹ̀ẹ́
- Àwọn jàǹdùkú sọ àjọ̀dún Amole di 'ọdún olè jíjà' nílùú Akure
- Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú Modakeke àti Ile Ife
- Búlọ́kù fẹ́ dá ìjà sílẹ̀ láàrín ìjọba àtàwọn olówò búlọ́kù ìpínlẹ̀ Ondo
Kọmiṣọnna ṣalaye pe ko si ẹni to mọ pato ohun to ṣe okunfa ija laarin awọn janduku ọhun.
''Ṣugbọn awọn kan sọ pe ede-aiyede lori bi wọn ti pin owo itusilẹ ti wọn ti ri gba lo fa ija laarin ẹgbẹ mejeeji.
Wọn awọn kan ninu wọn ni ẹgbẹ kan ti yan ẹgbẹ awọn jẹ wi pe owo ti o kan wọn kere,'' Aruwan lo sọ bẹẹ.
Kọmiṣọnaa eto abo abẹle ipinlẹ Kaduna ni awọn eeyan lo sọ nipa iṣẹlẹ naa fun ijọba.
Bakan naa lo sọ pe awọn oṣiṣẹ eleto abo naa jẹri pe lootọọ ni iṣẹlẹ ọhun waye.
''Iwadii lori eto abo fihan pe olori awọn janduku ajinigbe kan ti wọn n pe ni Godon Mota yabo abule Garke l'Ọjọru ọsẹ yii.
Nibẹ a gbọ pe awọn ọmọlẹyin rẹ ti kọlu ẹgbẹ janduku ajinigbe miran eleyii ki mẹsan ninu wọn dero ọrun.
Adele gomina ipinlẹ Kaduna, Ọmọwe Hadiza Balarabe, gan an ti fi idunnu rẹ han si iṣẹlẹ ọhun.
O si rọ awọn oṣiṣẹ eleto abo lati maa kaarẹ ninu akitiyan wọn lati fi ọwọ ofin mu awọn janduku ti wọn n da ilu laamu.
Iwadii ṣi n lọ lọwọ lori ọna ati wa ojutu si eto abo to mẹhẹ nipinlẹ Kaduna,'' Aruwan ṣalaye.












