Modakeke-Ife crisis: Ọlọ́pàá ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Modakeke àti Ile Ife

Oríṣun àwòrán, Osun
Ni idaji ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlogun oṣu karun ọdun 2021 yii lawọn olugbe agbegbe Alaro ni Modakeke ṣadeedee gbọ iro ibọn kẹu kẹu.
Iro ibọn naa lo mu kawọn eeyan sí ni sọ nipa ogun Modakeke ati Ife mii eyi to mu ki ibẹrubojo gbalẹ.
Amọ, agbẹnusọ fun ẹgbẹ Modakeke Progressive Union, Ven. Debo Babalola ṣalaye pe awọn adigunjale to yabo adugbo kan ni Modakeke lo dabọn bolẹ.
Ninu ọrọ tiẹ, akọwe ẹgbẹ Ife Development Board, Lawrence Omidiora ni alaafia lawọn eeyan Ife wa.
O rọ awọn eeyan pe ki wọn ye da ibẹrubojo bolẹ pẹlu iroyin ofege.
Ṣugbọn iwadi fihan pe nkan o fara tẹlẹ laarin ilu mejeeji lẹnu ọjọ mẹta yii lẹyin tawọn yinbọn pa oniṣowo koko kan, Titilayo Gbadegesin ati ọmọkunrin rẹ, Reuben labule Alapata.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ niluu Modakeke ati Ife nipinlẹ Osun lẹyin ti ọrọ naa gba ori ayelujara kan pe ija tun ti bẹ silẹ laarin ilu mejeeji.
Fidio kan lawọn eeyan n pin kaakiri ori ayelujara lọjọ Aiku to n ṣafihan pe rogbodiyan tun ti bẹ silẹ.
Ṣugbọn agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, SP Opalola Yemisi Olawoyin, sọ pe irọ nla ni iroyin to lu ayelujara pa pe awọn kan wa da rogbodiyan silẹ lati ẹkun Famia.
"Iroyin ofege lasan ni, irọ nla pẹlu.
Awọn ọlọdẹ fijilante lo n dan agbara wo nigbati ti wọn n le awọn ole.
Awọn fijilante naa ṣe bẹẹ lati fi dawọn eeyan loju pe kò sí iyọnu fun wọn rara," SP Olawoyin lo sọ bẹẹ.
Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Ọsun, Olawale Olokode fi dá àwọn eeyan ilu mejeeji loju pe ileeṣẹ ọlọpaa ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ eto abo wọn.
Bakan naa lo tun rọ awọn eeyan ilu naa lati fi to ọlọpaa leti ti wọn ba ti furasi ẹnikẹni ti o n ṣe nnkan ifura.

















