Palestine-Israel Conflict: Aṣojú America, Hady Amr àti àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé UN ti dé síbẹ̀ láti pẹ̀tùsáwọ̀ Isreal àti Palestine

Palestine

Oríṣun àwòrán, Anadolu Agency

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn alaṣẹ ilẹ Palestine ni eeyan mọkandinlogoje lo ti ku sinu laasigbo to tun suyọ larin oun ati orilẹede Israel.

Mọkandinlogoji wọn lo jẹ ọmọde ti mejilelogun si jẹ obinrin.

Orilẹ-ede Israel ni awsn agbebọn Palestine pẹlu ti ku sinu laasigbo naa

Aṣoju ijọba Amẹrika kan ti gunlẹ si Tel Aviv fun ijiroro ipẹtusaawọ laarin Isreal ati Palestine

Hady Amr yoo ṣepade pẹlawọn aṣoju orilẹede Israel, Palestine ati ajọ iṣọkan agbaye UN

Lori awọ tuntun to bẹ silẹ laarin Israel ati Palestine

Gaza

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìjá tó ń lọ́ láàrin ilẹ̀ Israel átí Palestian kò bá wa lára mú, ó ń kọwálọ́minú- Ìjọba Naijiria

Ijọba Israel ti kede ilu o fararọ ni ilu Lod nitori rogbodiyan to n waye laarin Israel atawọn ọmọ ogun ọlọtẹ, Hamas ni Palestine.

Ijọba orilẹ-ede Naijiria ti fi ero wọn han lori ija to n lọ lọwọ laaarin orilẹ-ede Isreal ati awọn alakatakiti ẹsin ilẹ Palestine Hamas.

Àkọlé fídíò, India, Coronavirus: Ìtọ́jú aláìsàn ló jẹ́ mi lógún nítorí ètò ìlera wa mẹ́hẹ- Nọ́ọ̀sì Kama

Ileeṣẹ to n risi ọrọ ilẹ okeere lorilẹ-ede Naijiria fi atẹjade sita loju opo Twitter pe ijọba ko ni inu didun si ipaniyan to n lọ lọwọ ni Gaza ati ilẹ Isreal.

Ijọba Naijiria rọ awọn orilẹ-ede Naijiria lati bọwọ fun ofin to de wọn gẹgẹ bio orilẹ-ede meji ọtọọtọ.

Bakan naa ni ijọba Naijiria rọ ijọba mejeeji lati jẹ ki awọn eniyan gbe ni alaafia ni ibi kibi ti wọn ba wa.

Ki lo n ṣẹlẹ lọwọlọwọ ni ija Isreal ati Hamas?

Orilẹede Isreal ti ṣigun lọ si ibode Gada lati koju awọn alakatakiti Hamas ti wọn n doju ija kọ Isreal lati bi ọjọ marun ṣẹyin.

Awọn ajijagbara Hamas naa ti ju ado oloro rọkẹẹti to le ni ẹgbẹrun meji si orilẹede Israel lọna ati doju ija kọ wọn.

Àkọlé fídíò, Ansoogun jagunjagun Iresa Adu Ogbomoso tó máa ń bínú gba ẹbọ- Oloye James Olawale

Amọ, orilẹ-ede Isreal ni awọn ko ni wọ ilu Gaza bi wọn ṣe sọ tẹlẹ, eleyii to ti fa ija igboro laarin awọn ẹya Jew ati Arab ti wọn n gbe ni Israel.

Awọn ara Palestine to le ni ọgọrun un lo ti ba iṣẹlẹ naa lọ, ti awọn ara Isreal mẹjọ si ti ku ninu iṣẹlẹ naa.

Awọn wo ni Hamas to n doju ija kọ Isreal lọwọ?

Ẹgbẹ alakatakiti Hamas lo ni ọmọ ẹyin to pọju ninu awọn alakatakiti ẹsin Islam lorilẹ-ede Palestine.

Orukọ apeja rẹ ni Ede Gẹẹsi, Islamic Resistance Movement, ti wọn bẹrẹ ni ọdun 1987 nigba oogun akọkọ pẹlu ilẹ Isreal to fẹ gba agbegbe West Bank mọ wọn lọwọ.

Hamas

Oríṣun àwòrán, AFP

Ohun kan soso ti wn n ja fun ni lati ri opin ilẹ Israel, amọ lati ọdun 2005 ti Israel ti ko awọn ọmọogun rẹ kuro ni Gaza, ni wọn ti bẹrẹ si ni dasi ọrọ oṣelu orilẹ-ede Palestine.

Lati igba yẹn titi di asiko yii, igba mẹta ọtọọtọ ni wọn ti jagun pẹlu orilẹ-ede Israel.

Amọ, ẹgbẹ agbesunmọmi ni orilẹede Amerika, Ilẹ Gẹẹsi ati Ajọ Isọkan ilẹ Yuroopu, EU ka ẹgbẹ agbẹsunmọmi Hamas si, ti wọn ko si fẹ ni nkan ṣe pẹlu wọn.

Israeli

Oríṣun àwòrán, AFP

Ogójì èèyàn ti pàdánù ẹ̀mí wọn nítorí ìjà tó ń wáyé láàrín Israel àti Palestine ní Lod

Palestine vs Israel updates

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O kere tan, ogoji eeyan lo ti dero ọrun nitori wahala naa, eyii ti awọn eeyan juwe gẹgẹ bii eyii to buru iru rẹ lati ọpọ ọdun sẹyin.

Àkọlé fídíò, Wọ́n rò pé mo ya wèrè ni Saudi lẹ́yìn ikú ọkọ mi

Alaṣẹ ilu Lod ti kede pe rogbogbodiyan to n waye niluu naa ti n farajọ ogun abẹle.

Awọn ọmọ ogun Israel sọ pe awọn ologun ọlọtẹ ni Palestine ti yin nnkan bii ẹgbẹrun meji rọkẹẹti si aringbungbun ati Guusu orile¬̣-ede naa.

Palestine vs Israel updates

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ṣugbọn awọn ti Palestine sọ pe awọn yin rọkẹẹti si agbegbe Tel Aviv lẹyin ti Israel ti kọkọ fi ado oloro wo ile alaja pupọ kan lagbegbe Gaza Strip.

Palestine vs Israel updates

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ki lo fa ija laarin Israel ati Palestine niluu Lod?

Awọn ọmọ ilẹ Isreal to jẹ Arab n ṣe ifẹhonuhan nitori eeyan wọn kan to ku nitori wahala kan to waye niluu Lod ṣaaju.

Ṣugbọn ifẹhonuhan naa gbọna mii yọ lẹyin ti awọn oluwọde ọhun bẹrẹ si n ju oko si awọn ọlọpaa to wa lagbegbe naa, ti awọn ọlọpaa ọhun si bẹrẹ si n ju ado oloro ti ko ju iṣu akara lọ si awọn naa pada.

Ilu Lod naa ko jina rara si Tel Aviv to jẹ gbajumọ ilu ni Israel.

Palestine vs Israel updates

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ọlọpaa ni wahala naa tẹsiwaju lorumọju titi di ọjọ keji, ti awọn eeyan si bẹrẹ si n dana sun awọn ọkọ ati ile itaja, eyii to mu ki adari ijọba, Benjamin Netayahu akede ilu o fararọ.

Palestine vs Israel updates

Oríṣun àwòrán, Reuters

Rogbogdiyan naa tun n waye lori bi awọn eeyan Palesine kan ṣe n binu pe awọn agbofinro Israel ko fun wọn laaye lati wọle si ibi mimọ julọ fun awọn Musulumi lasiko awẹ, iyẹn mọṣlaṣi al-Aqsa.

Palestine vs Israel updates

Oríṣun àwòrán, AFP

Agbegbe ti mọṣalaṣi naa wa tun ni ibi mimọ julọ fun awọn ẹlẹsin Judaism.

Palestine vs Israel updates

Oríṣun àwòrán, EPA

O ti to ọpọlọpọ ọdun ti ija ti n waye laarin awọn ọmọ Israel ati Palestine, paapaa lagbegbe Gaza Strip yii.