Yollywood,: Olumide Olajide Òṣèré tíátà Yorùbá míràn tún kó sí gbaga ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn lílu jìbìtì

Osere tiata

Oríṣun àwòrán, @Others

Ọwọ awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ ti tẹ oṣere tiata Yoruba kan ti orukọ rẹ n jẹ Olumide Olajide fun ẹsun fifi ayederu alaati atẹjiṣẹ isanwo fi lu awọn ọlọja ni jibiti ni ilu Ibadan.

Oṣere tiata naa wa lara awọn ti wọn fi oju wọn han f'ayeri lolu ileeṣẹ ọlọpaa yo wa lagbegbe Ẹlẹyẹle ni ilu Ibadan.

Oun ati akẹkọọ HND ninu imọ ẹko karakata, Purchasing and Supply kan ti orukọ rẹ n jẹ Wemimo Adeyanju ni awọn ọlọpaa patẹ wọn sita faye ri bi ẹni patẹ atarodo.

Agbegbe Apẹtẹ ni ilu Ibadan ni ọwọ ti baa.

Gẹgẹ bi osere tiata naa ṣe sọ, o ni oun maa n bere akanti ifowopamọ awọn ọlọja naa ẹyin ti oun ba ra ọja lọwọ wọn tan lati lee fi ayederu alaati ranṣẹ siwọn gẹgẹ bi ẹri pe oun ti sanwo.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Wo díẹ̀ nípa àbùdá Olodumare- Iyabo Ayinde

Gẹgẹ bi Olajide ṣe sọ, alaati naa yoo farahan loju foonu awọn ọlọja naa gẹgẹ bi eyi to jẹ ojulowo lati banki wọn.

O ni, " igba mẹta pere ni mo se ki ọwọ ọlọpaa to tẹ mi."

Arabinrin kan to da a mọ nipa aworan ori oju opo WhatsApp rẹ lo kebosi sita ti ọlọpaa fi gbe e.

Àkọlé fídíò, Alara tí Ilara Epe: Òjò gbọ́dọ̀ rọ̀ lásìkò ọdún Ẹlẹ́gba ni ìlú Epe- Oba Olufolarin Ogunsan