Coronavirus update in Nigeria: Ènìyàn 49 ló tún ṣẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdí ààrùn Coronavirus ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, @DigiCommsNG
Eniyan mọkandinlaadọta lo tun ṣẹṣẹ lugbadi aarun Coronavirus ni Naijiria ni Ọjọ Aje, Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Karun, ọdun 2021.
Ipinlẹ mẹrin bii Abuja, Eko, Enugu ati Oyo ni awọn ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si ti wa.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ to n risi ajakalẹ aarun Coronavirus ni Naijiria, NCDC fi lede ni wọn ti sọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Eniyan mẹtadinlọgbọn lo lugbadi aarun naa ni ilu Abuja nigbati eniyan mọkanla ko aarun naa ni ilu Eko.
Bakan naa ni ilu Enugu, eniyan mẹjọ lo ko aarun naa nigba ti eniyan mẹta kagbako rẹ ni ipinlẹ Oyo.
Ni apapọ bayii ni Naijiria, eniyan to le ni ẹgbẹrun lọna marundinlaadọsan, 165,468 lo ti lugbadi aarun naa lorilẹede Naijiria.
- Òní ni àṣekágbá ètò ìsìnkú olóògbé Dare Adeboye ni Redemption Camp
- Mi ó ṣọ̀fọ̀, mo sọkún nítorípé... - Ìyàwó olóògbé Dare Adeboye sọ̀rọ̀ níbi ìsìn idágbére ọkọ rẹ̀
- Ẹ̀mí ọlọ́pàá mẹ́tàlá ló sọnù lópin ọ̀sẹ̀ lọ́wọ́ àwọn "unknown gunmen"
- Àwọn agbébọn ya wọ mọ́ṣáláàṣí, wọ́n gbe èèyàn 40 lọ lásìkò àdúrà Tahajjud
Iye eniyan to ti jajabọ lọwọ arun naa ti le ni ẹgbẹrun lọna mẹrindinlọgọjọ.
Amọ, iye eniyan ti aarun Coronavirus ti mu ẹmi wọn lọ ni Naijiria ti le ni ẹgbẹrun meji, 2,065.












