Unknown gunmen: Ọlọ́pàá mẹ́tàlá pàdánù ẹ̀mi wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Najijria

Ikot Odion Abak Akwa Ibom State

Oríṣun àwòrán, Etini Akpaneyen

Ko din ni ọlọpaa mẹtala to padanu ẹmi wọn nitori ikọlu awọn agbebọn ti ẹnikẹni ko mọ ni opin ọsẹ to kọja yii.

Awọn ọlọpaa naa padanu ẹmi wọn nitori oniruru ikọlu ti awọn agbebọn naa ṣe ni ipinlẹ Rivers ati Akwa Ibom laarin ọjọ keje si ọjọ kẹsan an, oṣu Karun un, ọdun 2021 ti a wa yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom, Odiko Macdon, lo fidi ọrọ naa mulẹ ninu atẹjade to fi ṣọwọ si awọn akọroyin lẹyin ikọlu to waye lọjọ Aiku.

Odoro Ikpe Police Station, for Ini LGA of Akwa Ibom State.
Àkọlé àwòrán, Odoro Ikpe Police Station, for Ini LGA of Akwa Ibom State.

Ikọlu to waye lopin ọsẹ yii ni wọn ṣe si agọ ọlọpaa ti wọn ko lo mọ ni Essien Udim ati Ikot Odon ni ijọba ibilẹ Abk nipinlẹ naa.

Ileeṣẹ ọlọpa sọ fun BBC pe awọn agbebọn naa kọlu agọ ọlọpaa to wa ni Odoro Ikpe, nibi ti wọn ti pa ọlọpaa marun un, to fi mọ iyawo ọkan lara awọn ọlọpaa naa to lọ bẹ ọkọ rẹ wo lẹnu iṣẹ.

Ni ipinlẹ Rivers, awọn agbebọn pa ọlọpaa meje ni ikọlu mẹta ọtọtọ.

Iroyin ni awọn agbebọn ọhun gbe ibọn Ak-47 lọwọ lati ṣe awọn akọlu naa, ninu eyii ti awọn ọlọpaa kan ti farapa ti wọn si tun jo awọn ọkọ ti wọn fi n ṣiṣẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ni awọn ti bẹrẹ si n tọpinpin awọn agbebọn to lọwọ ninu awọn ikọlu ọhun.

Ikot Odion Abak Akwa Ibom State

Oríṣun àwòrán, Etini Akpaneyen

Ni Anambra, awọn agbebọn kọlu agọ ọlọpaa to wa ni Ozubulu, iyẹn ni ijọba ibilẹ Ekwusigo nipinlẹ ọuhn.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Ikenga Tochukwu sọ pe iṣẹlẹ ọhun waye ni nnkan bii aago meje aṣalẹ lọjọ kẹsan an, oṣu yii.

Tochukwu ni iwadii ti bẹrẹ lati fi oju awọn aṣebi to wa nidi awọn ikọlu naa lede.

Iye awọn ọlọpaa ti awọn agbebọn naa ti ṣekupa ti kun awọn ti ẹmi wọn ti sọnu ni Naijiria nitori awọn ikọlu lemọlemọ bayii.

Nnkan bii ọsẹ diẹ sẹyin ni awọn agbebọn naa bẹrẹ si n kọlu agọ awọn ọlọpaa ni iha ila-oorun Naijiria, ti ko si sẹni to mọ irufẹ eeyan ti awọn agbebọn naa jẹ tabi ohun gan ti wọn fẹ ni pato.