National Prayer: Àjọ́ CAN pàṣẹ ètò àdúrà ọlọ́jọ́ mẹ́tà fún Naijiria , ẹ wo kókó àdúrá...

Oríṣun àwòrán, Others
Ajọ ọmọlẹyin Kristi lorilẹede Naijria, CAN ti pe fun adura ọlọjọ mẹta lati gbadura fun Naijiria.
Ajọ CAN ninu atẹjade ti wọn fi lede ni Ọjọ Ẹti, Ọjọ Kejidinlọgbọn si Ọgbọnjọ, Oṣu Karun un lati gbe ohun adura soke kaakiri ẹkun Naijiria ti awọn ọmọlẹyin Kristi.
CAN ni asiko ti to lati bẹbẹ fun aanu lorilẹ-ede Naijiria nitori itajẹsilẹ naa ti to ge.
- Ansoogun jagunjagun Iresa Adu Ogbomoso tó máa ń bínú gba ẹbọ- Oloye James Olawale
- Lẹ́yìn ìwọ́de Yomi Fabiyi, ọlọ́pàá sọ ìdí tí wọ́n kò fi gba béélì Baba Ijẹsha, àti ìgbà tó ṣe é ṣe kí wọ́n ó fi sílẹ̀
- Ohun tí mo fẹ́ ṣe fún ẹbí ẹ̀gbọ́n mí, Dare Adeboye rè é ... -Leke Adeboye
- Davido sí Yomi Fabiyi: Mùmú ni ẹ́
Bkan naa ni wọn kigbe si Ọlọrun lati dẹkun ipaniyan, ijinigbe pẹlu wahala ati idaanu to n koju awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria.
Akọwe Ajọ CAN, Daramola Bade Joseph ni ibanujẹ ọkan ni itajẹ silẹ ojoojumọ n jẹ fun awọn ọmọlẹyin Krisiti ni Naijiria, ati wi pe ẹṣẹ ti pọju ni orilẹ agbaye.
''Ẹjẹ ki a gbadura wi pe ki Ọlọrun dari gbogbo aiṣedede wa jinwa gẹgẹ bi ijọ ọlọrun ati orilẹede, paapaa awọn adari ni Naijiria''.
'' Ẹ gbadura wi pe imọ ọta ati awọn ẹni ibi lati ba aye awọn eniyan jẹ ati eto ọrọ aje kaakiri, ki o di ofo''

Ajọ CAN fikun pe ki ijọ dide ninu adura pe ki ogun maṣe bẹ silẹ ni Naijiria, ki awọn eniyan le raye sin Ọlọrun.
Laipẹ yii ni aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari naa kesi awọn ẹlẹsin Musulumi lati gbe ohun ẹbẹ si Allah lasiko ọdun itunu aawẹ, ki gbogbo ogun to n ja orilẹede Naijiria lọ si okun igbagbe.

Oríṣun àwòrán, Presidency
Ẹ̀yin ọmọ Naijiria, ẹ gbé ohùn àdúrà sókè nítorí ètò ààbò Naijiria - Buhari
Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi iṣẹ ikini ku ọdun itunu awẹ ranṣẹ si awọn ọmọ Naijiria ati Musulumi kaakiri agbaye.
Ninu atẹjade ikini ti agbẹnusọ rẹ, Garba Shehu fi sita, Buhari sọ fun awọn ọmọ Naijiria, lati gbadura tako ijinigbe ati iṣẹ awọn agbebọn ni Naijiria.
Buhari sọ pe " a gbọdọ gbadura tako awọn iṣẹlẹ ibanujẹ bi ijinigbe ati ikọlu lati ọwọ awọn agbebọn, to fi mọ bi awọn kan ṣe n wa gbogbo ọna lati já agbara gba, eyi ti wọn fi n dunkooko mọ orilẹede wa".
Aarẹ sọ pe oun rọ awọn olori ilu ati olori ẹsin, lati ba awọn "eniyan wa sọrọ pe ki wọn o ma a fi ifẹ ati oju aanu ba ara wọn lo".
- Òṣèré tíátà Yorùbá míràn tún kó sí gbaga ọlọ́pàá
- Ọmọdé méje àti olùkọ́ kan jẹ́ Ọlọrun nípè lẹ́yìn tí agbébọn ẹni ọdún 19 ṣíná ìbọn bolẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ wọn
- Ààwẹ̀ Ramadan ṣì tẹ̀síwájú dí Ọjọ́ọ̀rú, a kò tíì rí òṣùpá- Supreme Council (NSCIA)
- Ẹni tó bá ní láàkàyè, a mọ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, àwà ti kọ lẹ́tà, èsì t'Ọ́lọ́pàá sì fún wa rèé - Yomi Fabiyi
- Àwọn ọmọ Naijiria yóò rí akitiyan ìjọba láti yanjú ètò àbò tó mẹ́hẹ láìpẹ́ - Lai Mohammed
Alaye ti aarẹ ṣe ni pe inu didun ati iwuri ni bi awọn ẹlẹsin Kristiẹni kan ṣe n ṣe ọdun itunu awẹ pẹlu awọn Musulumi, tabi fun wọn ni ẹbun lasiko Ramadan. Eyi ti awọn Musulumi kan naa ma n ṣe lasiko ọdun awọn Kristiẹni.
O ni iru awọn iwa bẹẹ n ṣe atọna fun jijẹ ibatan ati idariji.
Ṣaaju ni Aarẹ Muhammadu Buhari ti funpe si gbogbo awọn mumini ati mumina lati ṣe ayẹyẹ ọdun Eid-el-Fitr ninu ile ara wọn lati yago fun itankalẹ arun Corona Virus.
Aarẹ sọ ọrọ yii ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Garba Shehu fi sita lọjọ Aiku ninu eyi to ti sọ wipe oun naa yoo ṣe adura ọdun Eid ninu ile ti ko si ni si a nkini kankan lẹyin rẹ.
- Àwọn agbébọn ya wọ mọ́ṣáláàṣí, wọ́n gbe èèyàn 40 lọ lásìkò àdúrà Tahajjud
- Ìjọ Kátólìkì, ẹ jèbùrẹ́, ọmọdé ló ṣe èmi àtàwọn ọmọ ìjọ mi- Father Mbaka
- Èèyàn 28 kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi tó dànù ní ìpínlẹ̀ Niger
- Mi ò bú Baba Adeboye, mo kàn gégùn-ún fún àwọn tí kò ṣàtìlẹyìn fún Oduduwa Republic ni- Sunday Igboho
- Ẹ wo bí Leke Adeboye, àwọn ọ̀dọ́ ìjọ RCCG ṣe gẹ irun wọn láti bú ọlá fún Dare Adeboye tó papòdà
- À ń ṣe ìwádìí lọ́wọ́ bí ''candle'' ṣe pa Kayode Badru ní ìpínlẹ̀ Eko - Ọlọ́pàá
."Gbogbo mọlẹbi aarẹ, awọn oluranlọwọ rẹ, minisita atawọn olori oṣiṣẹ alaabo aarẹ to wa ni ilu Abuja yoo ṣe adura ọdun ni ile aarẹ ni ilana ati ofin fun igbogun ti arun Covid-19".
Atẹjade naa tun sọ pe "lẹyin eyi, ko ni si ikini ti Salat. Ati pe adura yoo bẹrẹ ni ago mẹsan".
Gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe e lọdun to kọja lọ, bẹẹ gẹlẹ naa ni aarẹ rọ awọn adari lati ṣe ayẹyẹ yii ninu ile wọn nitori ajakalẹ arun.
Lọjọ Aiku, aarẹ Buhari ba wọn pe nibi ikadi eto kika Quaran eyi ti wọn ṣe ni ile rẹ ti Sheikh Abdulwahi Abubakar Sulaiman ti n dari lati ibẹrẹ awẹ Ramadan.
- 30 nínú 40 àwọn tí wọ́n jígbé nínú Mọ́ṣáláṣí lásìkò Tahajjud ní Katsina ti gba ìtúsílẹ̀
- Orílẹ̀-ède UK ti fi kún iye òfin tó de àwọn arìnrìàjò wọn tó fẹ́ wá sí Nàìjíríà nítorí…
- Ènìyàn 49 ló tún ṣẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdí ààrùn Coronavirus ní Naijiria
- Ìjọba dá òfin kónlé-ó-gbélé lórí àjàkálẹ̀ àrùn covid-19 padà
- Ṣé ẹ rántí àwọn ìkọlù tó ti wáyé ní ilé ìjọba rí? Àwọn rèé
- Bó ṣe nípasẹ̀ ọkada ni tàbí ọkọ̀ ojú omi tàbí láti inú ihò ilẹ̀, ẹ wá ọ̀nà láti fi Naijiria sílẹ̀- Pasitọ Paul Adefarasin
















