Aso Rock robbery: Àwọn ìgbà tí adigunjalé ti yabo àwọn ilé ìjọba rí

Aso Rock

Oríṣun àwòrán, Presidency

Ilé íjọba ipinlẹ Bayelsa

Eleyi ṣẹlẹ ni orilẹede Naijiria lọdun 2019 lẹyin ti awọn adigunle ja wọ inu ọfiisi igbakeji olori oṣiṣẹ gomina Bayelsa tẹlẹ, Seriake Dickson lati ji owo.

Ebizi Brown to jẹ igbakeji olori oṣiṣẹ nigba naa nipinlẹ Bayelsa ni awọn adigunjale ọhun ja wọ inu ọfiisi oun.

"Wọn si ji owo ti iye rẹ jẹ miliọnu mẹta abọ nigba naa", arabinrin Brown lo fidi ọrọ yii mulẹ fun ileeṣẹ amohunmaworan Channels lasiko naa.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Bayelsa nigba naa tun fi ẹnu kun un pe ootọ lo ṣẹlẹ.

Awọn ọlọpaa ṣafikun ọrọ pe awọn janduku ọhun ba ilẹkun to wọ ọfiisi arabinrin Brown jẹ lati le ri ọna wọle wọn si tun ba apoti ikowo pamọsi to wa ninu ọfiisi naa lati le ji owo.

Ikọlu Aafin Buckingham lọdun 1982

Eyi jẹ iṣẹlẹ ti awọn ara Britain ko le gbagbe laye laye lẹyin ti arakunrin kan ti wọn n pe ni Michael Fargan ri ọna wọ inu aafin naa.

Koda Fargan ribi wọ inu yara Ọlọla julọ, Ọbabinrin Elizabeth keji.

Gẹgẹ bi iroyin BBC ṣe sọ ọ, Fargan ẹni ọdun mejilelọgbọn naa lasiko ọhun fo fẹnsi wọle, o tọ inu oju iho paipu titi to fi de inu yara Ọbabinrin Elizabeth, ẹnikankan ko si ri i.

Aafin Ọbabinrin Elizabeth

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ofolongo ẹsẹ ni baba ọlọmọ marun adigunjale naa fi bọ mọ gbogbo awọn ẹṣọ ile ọba lọwọ to fi mọ gbogbo irinṣẹ alariwo to yẹ ko tu u fo titi to fi wọ yara Ọbabinrin.

Nigba to wọ inu iyẹwu rẹ, o ni ko fun ohun ni siga, Ọba ba pariwo ni ọkan ninu ẹṣọ ba bu u so titi ti awọn ọlọpaa fi gba a mu.

Ọfiisi Olootu ilẹ Gẹẹsi

Eleyi waye lọdun 2007 nigba ti igara ọlọsa, Obadiah Marius ati ọrẹbinrin rẹ kọlu inu ojule nọmba aadọrin ninu iloro Whitehall ni London.

Ile yii sunmọ ile ijọba Olootu ilẹ Gẹẹsi ati ibi ti aọn aṣofin ilẹ UK ti n ṣepade.

Awọn ololufẹ meji naa wa ọgbọn lati wọ inu ibi ipade awọn aṣofin lai gba ọna to yẹ ki wọn ti yẹ wọn wo rara.

Koda, wọn tun gba ouna ibode oni irin to yẹ ko maa da abo bo Olootu lọwọ awọn agbe ado oloro.

Nigba to ya, ọwọ awọn ọlọpaa tẹ Obadiah ati ọrẹbinrin rẹ ti wọn si fi ẹsun to lagbara kan wọn labẹ ofin ilẹ United Kingdom.

Bí àwọn adigunjalè ṣe gbìyànjú ti fọ́ ile olórí àwọn òṣìṣẹ́ lọ́fíìsì ààrẹ.

Illeṣẹ aarẹ

Oríṣun àwòrán, @statehouse

Awọn adigunjale kan ti gbiyanju lati wọ ile Ọjọgbọn Ibrahim Gambari, ẹni to jẹ olori awọn oṣiṣẹ lakata aarẹ Buhari.

Ileeṣẹ aarẹ fi idi rẹ mule ninu atẹjade kan loju opo Twitter.

Iroyin sọ pe awọn alọkolohunkigbe naa wọ ile olori awọn to n ba aarẹ Buhari ṣiṣẹ, ṣugbọn ileeṣẹ aarẹ ni ko si ohun to jọ ati pe awọn ole naa ko ri aye wọle.

Ileeṣẹ aare

Oríṣun àwòrán, Tweet

Garba Shehu to jẹ amugbalẹgbẹ fun aarẹ lori ọrọ iroyin ati ipolongo ṣalaye lori Twitter pe ko si giri nitoripe awọn ole naa ko raye wọ ile Ọjọgbọn Gambari.

"Olori awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ lọfiisi aarẹ, Ọjọgbọn Gambari ti fidi rẹ mulẹ pe awọn oponu eeyan kan yi gbiyanju lati fipa wọ ile oun ni nnkan bii agogo mẹta owurọ yii (ọjọ Aje) ṣugbọn wọn ko rii ṣe.

" Ọjọgbọn Gambari, ti ile rẹ wa ni opopona to kangun si ile aarẹ Aso Rock Villa, ti wa fi ọkan awọn eeyan balẹ pe ko sewu.",

Àkọlé fídíò, Alara tí Ilara Epe: Òjò gbọ́dọ̀ rọ̀ lásìkò ọdún Ẹlẹ́gba ni ìlú Epe- Oba Olufolarin Ogunsan