Baba Ijesha ṣì wà l'ẹ́wọ̀n, ìgbèsẹ̀ tuntun tí Yomi Fabiyi gbé nípa rẹ̀ rèé

Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi/Ripples Nigeria

Oṣere Yomi Fabiyi to tun n ja fun ẹtọ akẹgbẹ rẹ Olanrewaju ti ọpọ mọ si Baba Ijesha ti ni oun ko ni yi ipinu oun pada tori oun mọ ofin.

Yomi ni bibọwọ fun ẹtọ ọmọniyan ṣe koko iru ipokipo tabi iṣẹlẹ ti ko baa jẹ.

"Gbogbo ẹni to ba ni laakaye gbudọ ni imọ pe ẹtọ ọmọniyan ṣe pataki". O ni bibọwọ fun ẹtọ bo ti wu ki ipo ti ẹni naa wa ṣe ri ṣe koko.

"Ko tii daju pe ẹri kan wa pe Baba Ijesha ṣe ọmọ naa baṣubaṣu sibẹ sibẹ, ọrọ Oludari ajọ to n ri si ifiyajẹ ọdaran jade, wọ́n tun kọ ọ sinu rẹ pe o ba ọmọ lajọṣepọ ki wọn kan ṣaa le ri nkan fi ti i mọle lai gba beeli ni".

Yomi Fabiyi n ja fun pe ko yẹ ki Baba Ijesha dede wa latimọle ọlọpaa titi di igba ti awọn ile ẹjọ to gun le iyanṣẹlodi yoo wọle iṣẹ pada.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Wo díẹ̀ nípa àbùdá Olodumare- Iyabo Ayinde

Ẹwẹ, Yomi Fabiyi ti fi lẹta sita eyi ti o kọ si ọ̀gá agba ọlọ́pàá l'Abuja lorukọ ẹgbẹ ijafẹtọ ọmọniyan rẹ "Break the silence foundation" lori ifẹhonuhan to fẹ ṣe lọla Ọjọru nilu Eko kọ ranṣẹ si ọga agba awọn ọlọpaa l'Abuja ti ẹka ileeṣẹ wọn ni Eko si ti buwọ lu u.

Leta Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi

O kọ lẹta yii bii ẹni n fẹjọ awọn ẹka agbofinro ilu Eko sun pe wọn ti akẹgbẹ rẹ Baba Ijesha mọle fun ọjọ gbọọrọ lai tii gba idajọ to si ni ko ba ofin mu.

Yomi ni oun ko tan ina wa ki eeyan fẹran oun, "ṣaa ti ri i daju pe o n ṣe ohun to tọ".

Àkọlé fídíò, Alara tí Ilara Epe: Òjò gbọ́dọ̀ rọ̀ lásìkò ọdún Ẹlẹ́gba ni ìlú Epe- Oba Olufolarin Ogunsan