Kayode Badru: Gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ ikú Kayode Badru kàn tó fí mọ́ ''Oluṣọ Ebony'' ló wà ní àtìmọ́lé

Kayode Badru

Oríṣun àwòrán, Google

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti ni iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori iṣẹlẹ iku to pa gbajumọ kan nipinlẹ Eko, Kayode Badru.

Kayode Badru lo n ṣe ọpẹ ni Ile Ijọsin kan ni Celestial Church of Christ pẹlu ''candle'' to si gbina to mu ẹmi rẹ lọ.

Iṣẹlẹ naa waye ni Ọjọ Aje, Ọjọ Kẹta, Osu Karun un, lasiko to n ṣe eto adura ninu ile ijọsin naa.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejobi fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye ni ipinlẹ Eko.

''Iru iṣẹlẹ to jọ bẹẹ wa ni agọ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, ti a si n ṣewadii lori rẹ''

Kayode Badru

Oríṣun àwòrán, Instagram

''Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n risi ọrọ ọdaran lo n ṣakoso iwadii naa, wọn ko si tii gbe iwadii wọn jade.''

''Ohun ti mo le sọ nipe iwadii n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa, ti esi iwadii ba jade a o fihan gbangba fun awọn araalu''.

Bakan naa ni agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, fikun wi pe awọn ti ọwọ awọn tẹ lori iṣẹlẹ naa wa ni atimọle ọlọpaa.

''Ohun ti mo le sọ ni wi pe gbogbo awọn ti ọwọ wa tẹ wa ni ọdọ wa''

Oloogbe Kayode Badru to jẹ ilumọọka ni ipinlẹ Eko, ni o ṣẹ̀ṣẹ de lati Dubai wa si Naijiria lati wa ṣe ayẹyẹ to ti wa pin nkan fun awọn eniyan,ki o to di pe ọlọjọ de.

Àkọlé fídíò, Alara tí Ilara Epe: Òjò gbọ́dọ̀ rọ̀ lásìkò ọdún Ẹlẹ́gba ni ìlú Epe- Oba Olufolarin Ogunsan