Wole Soyinka and Buhari administration: Ìjọba Ààrẹ Buhari ti kùnà, kò le è so ẹ̀yà kankan papọ̀ ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Ọjọgbọn Wọle Soyinka ti ni oun ko gbagbọ wi pe ifimọṣọkan ko le e ṣeeṣe labẹ isakoso aarẹ Muhammadu Buhari lorilẹ-ede Naijiria.
Soyinka ni aarẹ Buhari ati ijọba ti kuna ni ọpọlọpọ ọna, eleyi to ti mu ki iṣẹlẹ ẹlẹyamẹya gbinlẹ si ni Naijiria .
Nibi iwe kika lara iwe meji ti Onkọwe Wole Soyinka kọ, ti o pe akọle rẹ ni 'Trumpism in Academe' ati 'Chronicles of the Happiest People on Earth', ni o ti sọrọ naa.
- Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ ikú Kayode Badru ṣe ṣẹlẹ̀ ní Celestial Church of Christ ni Eko? ẹ wo ohun tí a mọ̀!
- Mo gbé ìgbésẹ̀ láti ṣẹ́ oyún ọmọ mi tuntun, ọkọ mi nàá sì faramọ́ nítorí pé...
- Sadiq Khan jáwé olúborí di 'Mayor' lẹ́ẹ̀kejì ní London
- Rọ́kẹ̀ẹ̀tì China ti balẹ̀, orí omi Indian Ocean ló já sí!- Iléeṣẹ́ ìròyìn China
- Wo orísun agbára tí Sunday Igboho gbójúlé tí ọwọ́ ẹnikẹ́ni kò fi le tẹ̀ ẹ́
Gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Imo lo bere ni ọwọ Wole Soyinka, iwe ti wọn le kọ to le e mu ki iṣọkan ati ifọwọsowọpọ pada si orilẹede Naijiria, paapaa laaarin awọn ẹya ni Naijiria.
Soyinka ni ko si iwe arokọ tabi akọsilẹ kankan to le e tun itan Naijiria kọ lati mu iṣọkan gbinlẹ si ni Naijiria.
O ni awọn ogunlende to wa ni awọn ibudo kaakiri ko le e jẹri si pe iṣọkan wa ni orilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Twitter
''Ki iṣọkan ati igbọraẹniye to le waye ni Naijiria, idajọ otitọ gbọdọ jọba paapaa fun awọn ti wọn n pa lọna aitọ kaakiri ni Naijiria.''
''Nitori naa mi o ni igbagbọ pe aarẹ Buhari le e ṣe ohunkohun nipa iṣọkan lorilẹede Naijiria''
- Trade by Barter, Rivers: Mọ̀ síi nípa ọjà ní Esuk Mba, níbití o ti lè fi iṣu gba edé, epo àti ǹkan míì
- A kò ní pe Ọlọ́run ní ẹjọ́ lórí ìkú ọmọ wa, Dare Adeboye - Ẹbí Adeboye
- Ǹkan dé o! Àwọn jàndùkú tún yìnbọn pa ọlọ́pàá méje lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n dáná sun ọkọ̀ wọn
- Ẹ tú Baba Ijesha sílẹ̀ pẹ̀lú Béèlì, ẹ má ṣi agbára òfin lò bí bẹ́ẹ̀ kọ́
- Àṣìṣe dókità ló pa Peju, ìbànújẹ́ dorí àgbà kodò- Funke Akindele
Ọjọgbọn Wole Soyinkas ni o ṣeeni laanu wi pe akoko ti aarẹ Buhari ni lati ṣe atunṣe ifọwọsọwọpọ ni Naijiria ti kọja nitori akoko naa ti kọja.
Amọ o fikun wi pe oun gbagbọ wi pe yoo dara kii Naijiria wa papọ gẹgẹbi ẹyọkan, amọ ijọba gbọdọ ṣe ojuṣe wọn lori eto aabo.














